Luk 1:13-38

Luk 1:13-38 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn angẹli na wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Sakariah: nitoriti adura rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yio si bí ọmọkunrin kan fun ọ, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Johanu. Iwọ o si li ayọ̀ ati inu didùn: enia pipọ yio si yọ̀ si ibí rẹ̀. Nitori on o pọ̀ niwaju Oluwa, kì yio si mu ọti-waini, bẹ̃ni kì yio si mu ọti-lile; yio si kún fun Ẹmi Mimọ́ ani lati inu iya rẹ̀ wá. On o si pa pipọ da ninu awọn ọmọ Israeli si Oluwa Ọlọrun wọn. Ẹmí ati agbara Elijah ni on o si fi ṣaju rẹ̀ lọ, lati pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ti awọn alaigbọran si ọgbọ́n awọn olõtọ; ki o le pèse enia ti a mura silẹ dè Oluwa. Sakariah si wi fun angẹli na pe, Àmi wo li emi o fi mọ̀ eyi? Emi sá di àgba, ati Elisabeti aya mi si di arugbo. Angẹli na si dahùn o wi fun u pe, Emi ni Gabrieli, ti ima duro niwaju Ọlọrun; emi li a rán wá lati sọ fun ọ, ati lati mu ìhin ayọ̀ wọnyi fun ọ wá. Si kiyesi i, iwọ o yadi, iwọ kì yio si le fọhun, titi ọjọ na ti nkan wọnyi yio fi ṣẹ, nitori iwọ ko gbà ọ̀rọ mi gbọ́ ti yio ṣẹ li akokò wọn. Awọn enia si duro dè Sakariah, ẹnu si yà wọn nitoriti o pẹ ninu tẹmpili. Nigbati o si jade, kò le fọhun si wọn: nwọn si woye pe o ri iran ninu tẹmpili: nitoriti o nṣe apẹrẹ si wọn, o si yà odi. O si ṣe, nigbati ọjọ iṣẹ isin rẹ̀ pe, o lọ si ile rẹ̀. Lẹhin ọjọ wọnyi ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyun, o si fi ara rẹ̀ pamọ́ li oṣù marun, o ni, Bayi li Oluwa ṣe fun mi li ọjọ ti o ṣijuwò mi, lati mu ẹ̀gan mi kuro lọdọ araiye. Li oṣù kẹfa a si rán angẹli Gabrieli lati ọdọ Ọlọrun lọ si ilu kan ni Galili, ti a npè ni Nasareti, Si wundia kan ti a fẹ fun ọkunrin kan, ti a npè ni Josefu, ti idile Dafidi; orukọ wundia na a si ma jẹ Maria. Angẹli na si tọ̀ ọ wá, o ni, Alãfia iwọ ẹniti a kọjusi ṣe li ore, Oluwa pẹlu rẹ: alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin. Ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò lelẹ nitori ọ̀rọ na, o si rò ninu ara rẹ̀ pe, irú kíki kili eyi. Angẹli na si wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Maria: nitori iwọ ti ri ojurere lọdọ Ọlọrun. Sá si kiyesi i, iwọ o lóyun ninu rẹ, iwọ o si bí ọmọkunrin kan, iwọ o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU. On o pọ̀, Ọmọ Ọgá-ogo julọ li a o si ma pè e: Oluwa Ọlọrun yio si fi itẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fun u: Yio si jọba ni ile Jakọbu titi aiye; ijọba rẹ̀ ki yio si ni ipẹkun. Nigbana ni Maria wi fun angẹli na pe, Eyi yio ha ti ṣe ri bẹ̃, nigbati emi kò ti mọ̀ ọkunrin? Angẹli na si dahùn o si wi fun u pe, Ẹmí Mimọ́ yio tọ̀ ọ wá, ati agbara Ọgá-ogo yio ṣiji bò ọ: nitorina ohun mimọ́ ti a o ti inu rẹ bi, Ọmọ Ọlọrun li a o ma pè e. Si kiyesi i, Elisabeti ibatan rẹ, on pẹlu si lóyun ọmọkunrin kan li ogbologbo rẹ̀: eyi si li oṣu kẹfa fun ẹniti a npè li agàn. Nitori kò si ohun ti Ọlọrun ko le ṣe. Maria si wipe, Wò ọmọ-ọdọ Oluwa; ki o ri fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Angẹli na si fi i silẹ lọ.

Luk 1:13-38 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sakaraya, nítorí pé adura rẹ ti gbà. Elisabẹti iyawo rẹ yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo pe orúkọ rẹ̀ ní Johanu. Ayọ̀ yóo kún ọkàn rẹ. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá ọ yọ̀ nígbà tí ẹ bá bí ọmọ náà. Ọmọ náà yóo jẹ́ ẹni ńlá níwájú Oluwa. Kò gbọdọ̀ mu ọtíkọ́tí, ìbáà jẹ́ líle tabi èyí tí kò le. Yóo kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti ìgbà tí ó bá tí wà ninu ìyá rẹ̀; ọpọlọpọ àwọn ọmọ Israẹli ni yóo sì yipada sí Oluwa Ọlọrun wọn. Òun ni yóo ṣáájú Oluwa pẹlu ẹ̀mí Elija ati agbára rẹ̀. Yóo mú kí àwọn baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu àwọn ọmọ wọn. Yóo yí àwọn alágídí ọkàn pada sí ọ̀nà rere. Yóo sọ àwọn eniyan di yíyẹ lọ́dọ̀ Oluwa.” Sakaraya bi angẹli náà pé, “Báwo ni n óo ti ṣe mọ̀? Nítorí pé mo ti di arúgbó; iyawo mi alára náà sì ti di àgbàlagbà.” Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Geburẹli ni orúkọ mi, èmi ni mo máa ń dúró níwájú Ọlọrun. Ọlọrun ló rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, ati láti sọ nǹkan ayọ̀ yìí fún ọ. Nítorí pé ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, o óo ya odi, o kò ní lè sọ̀rọ̀ títí ọjọ́ tí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí yóo ṣẹ nígbà tí ó bá yá.” Àwọn eniyan ti ń retí Sakaraya. Ẹnu yà wọ́n pé ó pẹ́ ninu iyàrá Tẹmpili. Nígbà tí ó jáde, kò lè bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n sì mọ̀ pé ó ti rí ìran ninu iyàrá Tẹmpili ni. Ó yadi, ọwọ́ ni ó fi ń ṣe àpèjúwe fún wọn. Nígbà tí ó parí àkókò tí yóo fi ṣiṣẹ́ alufaa ninu Tẹmpili, ó pada lọ sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Elisabẹti lóyún. Ó bá fi ara pamọ́ fún oṣù marun-un. Ó ní, “Oluwa ni ó ṣe èyí fún mi. Ó ti fi ojú àánú wò mí, ó sì ti mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀gàn fún mi lójú eniyan kúrò.” Ní oṣù kẹfa, Ọlọrun rán angẹli Geburẹli lọ sí ìlú kan ní Galili tí wọn ń pè ní Nasarẹti. Ọlọrun rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wundia kan tí ó jẹ́ iyawo àfẹ́sọ́nà ọkunrin kan tí ń jẹ́ Josẹfu, ti ìdílé Dafidi. Wundia náà ń jẹ́ Maria. Angẹli náà wọlé tọ Maria lọ, ó kí i, ó ní “Alaafia ni fún ọ! Ìwọ ẹni tí Ọlọrun kọjú sí ṣe ní oore, Oluwa wà pẹlu rẹ.” Nígbà tí Maria gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ó ń rò lọ́kàn rẹ̀ pé, irú kíkí wo nìyí? Angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí o ti bá ojurere Ọlọrun pàdé. O óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan, Jesu ni o óo pe orúkọ rẹ̀. Eniyan ńlá ni yóo jẹ́. Ọmọ Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè é. Oluwa Ọlọrun yóo fún un ní ìtẹ́ Dafidi, baba rẹ̀. Yóo jọba lórí ìdílé Jakọbu títí lae, ìjọba rẹ̀ kò ní lópin.” Maria bá bi angẹli náà pé, “Báwo ni yóo ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí n kò tíì mọ ọkunrin?” Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóo tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá Ògo yóo ṣíji bò ọ́. Nítorí náà Ọmọ Mímọ́ Ọlọrun ni a óo máa pe ọmọ tí ìwọ óo bí. Ati pé Elisabẹti, ìbátan rẹ náà ti lóyún ọmọkunrin kan ní ìgbà ogbó rẹ̀. Ẹni tí wọ́n ti ń pè ní àgàn rí sì ti di aboyún oṣù mẹfa. Nítorí kò sí ohun tí ó ṣòro fún Ọlọrun.” Maria bá dáhùn pé, “Iranṣẹ Oluwa ni mí. Kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà bá fi í sílẹ̀ lọ.

Luk 1:13-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sekariah: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Johanu. Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ: ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ. Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá. Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run wọn. Ẹ̀mí àti agbára Elijah ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòtítọ́; kí ó le pèsè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.” Sekariah sì wí fún angẹli náà pé, “Ààmì wo ni èmi ó fi mọ èyí? Èmi sá ti di àgbà, àti Elisabeti aya mi sì di arúgbó.” Angẹli náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gabrieli, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìròyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá. Sì kíyèsi i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.” Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sekariah, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹmpili. Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsi wí pé ó ti rí ìran nínú tẹmpili, ó sì ń ṣe àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ ní oṣù márùn-ún, Ó sì wí pé “Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó ṣíjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrín àwọn ènìyàn.” Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán angẹli Gabrieli sí ìlú kan ní Galili, tí à ń pè ní Nasareti, sí wúńdíá kan tí a ṣèlérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Josẹfu, ti ìdílé Dafidi; orúkọ wúńdíá náà a sì máa jẹ́ Maria. Angẹli náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlàáfíà fun ọ, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ń bẹ pẹ̀lú rẹ.” Ṣùgbọ́n ọkàn Maria kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kín ni èyí. Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria: nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ìwọ yóò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní JESU. Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é: Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún: Yóò sì jẹ ọba lórí ilé Jakọbu títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.” Nígbà náà ni Maria béèrè lọ́wọ́ angẹli náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tí ì mọ ọkùnrin.” Angẹli náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò ṣíji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é. Sì kíyèsi i, Elisabeti ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọkùnrin kan ní ògbólógbòó rẹ̀. Èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn. Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.” Maria sì dáhùn wí pé, “Wò ó ọmọ ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.