Lef 6:8-13
Lef 6:8-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Paṣẹ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ sisun: Ẹbọ sisun ni, nitori sisun rẹ̀ lori pẹpẹ ni gbogbo oru titi di owurọ̀, iná pẹpẹ na yio si ma jò ninu rẹ̀. Ki alufa ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ rẹ̀ wọ̀, ati ṣòkoto ọ̀gbọ rẹ̀ nì ki o fi si ara rẹ̀, ki o si kó ẽru ti iná jọ, ti on ti ẹbọ sisun lori pẹpẹ, ki o si fi i si ìha pẹpẹ. Ki o si bọ́ ẹ̀wu rẹ̀ silẹ, ki o si mú ẹ̀wu miran wọ̀, ki o si gbé ẽru wọnni jade lọ sẹhin ibudó si ibi kan ti o mọ́. Ki iná ori pẹpẹ nì ki o si ma jó lori rẹ̀; ki a máṣe pa a; ki alufa ki o si ma kòná igi lori rẹ̀ li orowurọ̀, ki o si tò ẹbọ sisun sori rẹ̀; ki o si ma sun ọrá ẹbọ alafia lori rẹ̀. Ki iná ki o ma jó titi lori pẹpẹ na; kò gbọdọ kú lai.
Lef 6:8-13 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Mose pé, “Pa á láṣẹ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹbọ sísun: ẹbọ sísun níláti wà lórí ààrò lórí pẹpẹ ní gbogbo òru títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iná sì níláti máa jò lórí pẹpẹ náà ní gbogbo ìgbà. Kí alufaa wọ ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ funfun rẹ̀, ati ṣòkòtò aṣọ funfun, kí ó kó eérú ẹbọ tí ó ti fi iná sun kúrò lórí pẹpẹ, kí ó sì dà á sí ibìkan. Lẹ́yìn náà, kí ó bọ́ aṣọ iṣẹ́ alufaa rẹ̀ kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí ó wá ru eérú náà jáde kúrò ninu àgọ́ sí ibi mímọ́ kan. Kí iná orí pẹpẹ náà sì máa jó, kò gbọdọ̀ kú nígbà kan. Kí alufaa máa kó igi sí i ní àràárọ̀; kí ó máa to ẹbọ sísun lé e lórí, orí rẹ̀ ni yóo sì ti máa sun ọ̀rá ẹran tí ó bá fi rú ẹbọ alaafia. Iná orí pẹpẹ náà gbọdọ̀ máa jó nígbà gbogbo, kò gbọdọ̀ kú.
Lef 6:8-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose pé: “Pàṣẹ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé: ‘Èyí ni ìlànà fún ẹbọ sísun; ẹbọ sísun gbọdọ̀ wà lórí pẹpẹ láti alẹ́ di òwúrọ̀, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ kí àlùfáà sì wọ ẹ̀wù funfun rẹ̀ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì kó eérú tó wà níbi ẹbọ sísun tí iná ti jó lórí pẹpẹ, sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni yóò bọ́ aṣọ rẹ̀, yóò sì wọ òmíràn, yóò wá gbé eérú náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tí a kà sí mímọ́. Iná tó wà lórí pẹpẹ gbọdọ̀ máa jó, kò gbọdọ̀ kú, ní àràárọ̀ ni kí àlùfáà máa to igi si, kí ó sì to ẹbọ sísun sórí iná, kí ó sì máa sun ọ̀rá ẹran ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀. Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú.