Lef 26:11-13
Lef 26:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárín yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín. Èmi yóò wà pẹ̀lú yín: Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín: Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti: kí ẹ̀yin má ba à jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́. Mo sì já ìdè àjàgà yín: mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè.
Lef 26:11-13 Yoruba Bible (YCE)
N óo fi ààrin yín ṣe ibùgbé mi, ọkàn mi kò sì ní kórìíra yín. N óo máa rìn láàrin yín, n óo jẹ́ Ọlọrun yín, ẹ óo sì jẹ́ eniyan mi. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí ẹ má baà ṣe ẹrú wọn mọ́. Mo ti dá igi ìdè àjàgà yín kí ẹ lè máa rìn lóòró gangan.
Lef 26:11-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o si gbé ibugbé mi kalẹ lãrin nyin: ọkàn mi ki yio si korira nyin. Emi o si ma rìn lãrin nyin, emi o si ma ṣe Ọlọrun nyin, ẹnyin o si ma ṣe enia mi. Emi li OLUWA Ọlọrun nyin ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ki ẹnyin ki o máṣe wà li ẹrú wọn; emi si ti dá ìde àjaga nyin, mo si mu nyin rìn lõrogangan.