Lef 25:18-23
Lef 25:18-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ki ẹnyin ki o ma ṣe ìlana mi, ki ẹ si ma pa ofin mi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; ẹnyin o si ma gbé ilẹ na li ailewu. Ilẹ na yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, ẹ o si ma jẹ ajẹyo, ẹ o si ma gbé inu rẹ̀ li ailewu. Bi ẹnyin ba si wipe, Kili awa o ha ma jẹ li ọdún keje? sa wo o, awa kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li awa kò gbọdọ kó ire wa: Nigbana li emi o fi aṣẹ ibukún mi fun nyin li ọdún kẹfa, on o si so eso jade fun nyin fun ọdún mẹta. Ẹnyin o si gbìn li ọdún kẹjọ, ẹnyin o si ma jẹ ninu eso lailai titi di ọdún kẹsan, titi eso rẹ̀ yio fi dé ni ẹnyin o ma jẹ ohun isigbẹ. Ẹnyin kò gbọdọ tà ilẹ lailai; nitoripe ti emi ni ilẹ: nitoripe alejò ati atipo ni nyin lọdọ mi.
Lef 25:18-23 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí náà, ẹ níláti tẹ̀lé ìlànà mi, kí ẹ sì pa òfin mi mọ́, kí ẹ lè máa gbé inú ilẹ̀ náà láìséwu. Ilẹ̀ náà yóo so ọpọlọpọ èso, ẹ óo jẹ àjẹyó, ẹ óo sì máa gbé inú rẹ̀ láìséwu. “Bí ẹ bá ń wí pé, ‘Kí ni a óo jẹ ní ọdún keje bí a kò bá gbọdọ̀ gbin ohun ọ̀gbìn, tí a kò sì gbọdọ̀ kórè?’ Èmi OLUWA yóo pàṣẹ pé kí ibukun mi wà lórí yín ní ọdún kẹfa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ yóo so èso tí yóo to yín jẹ fún ọdún mẹta. Nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn ní ọdún kẹjọ, ẹ óo tún máa rí àwọn èso tí ó ti wà ní ìpamọ́ jẹ títí tí yóo fi di ọdún kẹsan-an, tí ilẹ̀ yóo tún mú èso rẹ̀ jáde wá, àwọn èso ti àtẹ̀yìnwá ni ẹ óo máa jẹ. “Ẹ kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ kan títí ayé, nítorí pé èmi OLUWA ni mo ni gbogbo ilẹ̀, ati pé àlejò ati àtìpó ni ẹ jẹ́ fún mi.
Lef 25:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“ ‘Ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì kíyèsi láti pa òfin mi mọ́, kí ẹ ba à le máa gbé láìléwu ní ilẹ̀ náà Nígbà yìí ni ilẹ̀ náà yóò so èso rẹ̀, ẹ ó sì jẹ àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìléwu. Ẹ le béèrè pé, “Kí ni àwa ó jẹ ní ọdún keje, bí a kò bá gbin èso tí a kò sì kórè?” Èmi ó pèsè ìbùkún sórí yín tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ yín yóò so èso tó tó fún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn rẹ̀. Bí ẹ bá gbin èso yín ní ọdún kẹjọ, àwọn èso ti tẹ́lẹ̀ ní ẹ ó máa jẹ, títí tí ìkórè ti ọdún kẹsànán yóò fi dé. “ ‘Ẹ má ṣe ta ilẹ̀ yín ní àtàpa torí pé ẹ̀yin kọ́ lẹ ni ín, ti Ọlọ́run ni, ẹ̀yin jẹ́ àjèjì àti ayálégbé