Lef 25:1-46
Lef 25:1-46 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose li òke Sinai pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ti mo fi fun nyin, nigbana ni ki ilẹ na ki o pa isimi kan mọ́ fun OLUWA. Ọdún mẹfa ni iwọ o fi gbìn oko rẹ, ọdún mẹfa ni iwọ o si fi rẹwọ ọgbà-ajara rẹ, ti iwọ o si kó eso rẹ̀ jọ; Ṣugbọn ọdún keje ki o si jasi ìgba isimi fun ilẹ na, isimi fun OLUWA: iwọ kò gbọdọ gbìn oko rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹwọ ọgbà-àjara rẹ. Eyiti o ba lalẹ̀ hù ninu ikore rẹ iwọ kò gbọdọ ká, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká eso àjara rẹ ti iwọ kò rẹ́ lọwọ: nitoripe ọdún isimi ni fun ilẹ na. Ọdún isimi ilẹ na yio si ma ṣe ohunjijẹ fun nyin; fun iwọ, ati fun iranṣẹ rẹ ọkunrin, ati fun iranṣẹ rẹ obinrin, ati fun alagbaṣe rẹ, ati fun alejò rẹ ti nṣe atipo lọdọ rẹ; Ati fun ohunọ̀sin rẹ, ati fun ẹran ti mbẹ ni ilẹ rẹ, ni ki ibisi rẹ̀ gbogbo ki o ṣe onjẹ fun. Ki iwọ ki o si kà ọdún isimi meje fun ara rẹ, ọdún meje ìgba meje; ati akokò ọdún isimi meje ni yio jẹ́ ọdún mọkandilãdọta fun ọ. Ki iwọ ki o si mu ki ipè ki o dún ni ijọ́ kẹwa oṣù keje, li ọjọ́ ètutu ni ki ẹnyin ki o mu ipè na dún ni gbogbo ilẹ nyin. Ki ẹnyin ki o si yà arãdọta ọdún simimọ́, ki ẹnyin ki o si kede idasilẹ ni ilẹ na fun gbogbo awọn ti ngbé inu rẹ̀: yio si ma jẹ́ jubeli fun nyin; ki ẹnyin ki o si pada olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si pada sinu idile rẹ̀. Ọdún jubeli ni ki arãdọta ọdún ki o jasi fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká ilalẹ-hù inu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká eso àjara rẹ̀ ti a kò rẹ-lọwọ. Nitoripe jubeli ni; mimọ́ ni ki o jasi fun nyin: ibisi rẹ̀ ni ki ẹnyin o ma jẹ lati inu oko wa. Li ọdún jubeli yi ni ki olukuluku nyin ki o pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀. Bi iwọ ba si tà ọjà fun ẹnikeji rẹ, tabi bi iwọ ba rà lọwọ ẹnikeji rẹ, ẹnyin kò gbọdọ rẹ ara nyin jẹ: Gẹgẹ bi iye ọdún lẹhin jubeli ni ki iwọ ki o rà lọwọ ẹnikeji rẹ, ati gẹgẹ bi iye ọdún ikore rẹ̀ ni ki o tà fun ọ. Gẹgẹ bi ọ̀pọ ọdún ni ki iwọ ki o bù owo rẹ̀ sí i, ati gẹgẹ bi ọdún rẹ̀ ti fàsẹhin, ni ki iwọ ki o si bù owo rẹ̀ kù; nitoripe gẹgẹ bi iye ọdún ikore ni ki o tà fun ọ. Nitorina ẹnyin kò gbọdọ rẹ ara nyin jẹ; bikoṣe pe ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Nitorina ki ẹnyin ki o ma ṣe ìlana mi, ki ẹ si ma pa ofin mi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; ẹnyin o si ma gbé ilẹ na li ailewu. Ilẹ na yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, ẹ o si ma jẹ ajẹyo, ẹ o si ma gbé inu rẹ̀ li ailewu. Bi ẹnyin ba si wipe, Kili awa o ha ma jẹ li ọdún keje? sa wo o, awa kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li awa kò gbọdọ kó ire wa: Nigbana li emi o fi aṣẹ ibukún mi fun nyin li ọdún kẹfa, on o si so eso jade fun nyin fun ọdún mẹta. Ẹnyin o si gbìn li ọdún kẹjọ, ẹnyin o si ma jẹ ninu eso lailai titi di ọdún kẹsan, titi eso rẹ̀ yio fi dé ni ẹnyin o ma jẹ ohun isigbẹ. Ẹnyin kò gbọdọ tà ilẹ lailai; nitoripe ti emi ni ilẹ: nitoripe alejò ati atipo ni nyin lọdọ mi. Ati ni gbogbo ilẹ-iní nyin ki ẹnyin ki o si ma ṣe ìrapada fun ilẹ. Bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti o ba si tà ninu ilẹ-iní rẹ̀, bi ẹnikan ninu awọn ibatan rẹ̀ ba si wá lati rà a, njẹ ki o rà eyiti arakunrin rẹ̀ ti tà pada. Bi ọkunrin na kò ba ní ẹnikan ti yio rà a pada, ti on tikara rẹ̀ ti di olowo ti o ní to lati rà a pada; Nigbana ni ki o kà ọdún ìta rẹ̀, ki o si mú elé owo rẹ̀ pada fun ẹniti o tà a fun, ki on ki o le pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀. Ṣugbọn bi o ba ṣepe on kò le san a pada fun u, njẹ ki ohun ti o tà na ki o gbé ọwọ́ ẹniti o rà a titi di ọdún jubeli: yio si bọ́ ni jubeli, on o si pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀. Bi ọkunrin kan ba si tà ile gbigbé kan ni ilu olodi, njẹ ki o rà a pada ni ìwọn ọdún kan lẹhin ti o tà a; ni ìwọn ọdún kan ni ki o rà a pada. Bi a kò ba si rà a ni ìwọn ọdún kan gbako, njẹ ki ile na ki o di ti ẹniti o rà a titilai ni iran-iran rẹ̀: ki yio bọ́ ni jubeli. Ṣugbọn ile ileto wọnni ti kò ni odi yi wọn ká awọn li a kà si ibi oko ilu: ìrapada li awọn wọnni, nwọn o si bọ́ ni jubeli. Ṣugbọn niti ilu awọn ọmọ Lefi, ile ilu iní wọn, ni awọn ọmọ Lefi o ma ràpada nigbakugba. Bi ẹnikan ba si rà lọwọ awọn ọmọ Lefi, njẹ ile ti a tà na, ni ilu iní rẹ̀, ki o bọ́ ni jubeli: nitoripe ile ilu awọn ọmọ Lefi ni ilẹ-iní wọn lãrin awọn ọmọ Israeli. Ṣugbọn ilẹ ẹba ilu wọn ni nwọn kò gbọdọ tà; nitoripe ilẹ-iní wọn ni titi aiye. Ati bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti ọwọ́ rẹ̀ ba si rẹlẹ lọdọ rẹ; njẹ ki iwọ ki o ràn a lọwọ; ibaṣe alejò, tabi atipo; ki on ki o le wà pẹlu rẹ. Iwọ máṣe gbà elé lọwọ rẹ̀, tabi ẹdá; ṣugbọn bẹ̀ru Ọlọrun rẹ; ki arakunrin rẹ ki o le wà pẹlu rẹ. Iwọ kò gbọdọ fi owo rẹ fun u li ẹdá, tabi ki o wín i li onjẹ rẹ fun asanlé. Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, lati fi ilẹ Kenaani fun nyin, ati lati ma ṣe Ọlọrun nyin. Ati bi arakunrin rẹ ti mba ọ gbé ba di talakà, ti o si tà ara rẹ̀ fun ọ; iwọ kò gbọdọ sìn i ni ìsin-ẹrú: Bikoṣe bi alagbaṣe, ati bi atipo, ni ki o ma ba ọ gbé, ki o si ma sìn ọ titi di ọdún jubeli: Nigbana ni ki o lọ kuro lọdọ rẹ, ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ki o si pada lọ si idile rẹ̀, ati si ilẹ-iní awọn baba rẹ̀ ni ki o pada si. Nitoripe iranṣẹ mi ni nwọn iṣe, ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá: a kò gbọdọ tà wọn bi ẹni tà ẹrú. Iwọ kò gbọdọ fi irorò sìn i; ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ. Ati awọn ẹrú rẹ ọkunrin, ati awọn ẹrú rẹ obinrin, ti iwọ o ní; ki nwọn ki o jẹ́ ati inu awọn orilẹ-ède wá ti o yi nyin ká, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o ma rà awọn ẹrú-ọkunrin ati awọn ẹrú-obinrin. Pẹlupẹlu ninu awọn ọmọ alejò ti nṣe atipo pẹlu nyin, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o rà, ati ninu awọn idile wọn ti mbẹ pẹlu nyin, ti nwọn bi ni ilẹ nyin: nwọn o si jẹ iní nyin. Ẹnyin o si ma fi wọn jẹ ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin, lati ní wọn ni iní; ẹnyin o si ma sìn wọn lailai: ṣugbọn ninu awọn arakunrin nyin awọn ọmọ Israeli, ẹnikan kò gbọdọ fi irorò sìn ẹnikeji rẹ̀.
Lef 25:1-46 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ lórí òkè Sinai, ó ní, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, àkókò ìyàsọ́tọ̀ kan gbọdọ̀ wà fún ilẹ̀ náà tí yóo jẹ́ àkókò ìsinmi fún OLUWA. Ọdún mẹfa ni kí ẹ máa fi gbin èso sinu oko yín, ọdún mẹfa náà sì ni kí ẹ máa fi tọ́jú ọgbà àjàrà yín, tí ẹ óo sì máa fi kórè èso rẹ̀. Ṣugbọn ọdún keje yóo jẹ́ ọdún ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀ fún ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sinmi fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sinu oko yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ tọ́jú àjàrà yín. Ohunkohun tí ó bá dá hù fún ara rẹ̀ ninu oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ kórè èso tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà yín tí ẹ kò tọ́jú. Ọdún náà gbọdọ̀ jẹ́ ọdún ìsinmi fún ilẹ̀. Ìsinmi ilẹ̀ yìí ni yóo mú kí oúnjẹ wà fun yín: ati ẹ̀yin alára, tọkunrin tobinrin yín, ati àwọn ẹrú, ati àwọn alágbàṣe yín, ati àwọn àlejò tí wọ́n ń ba yín gbé, ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ tí wọ́n wà ní ilẹ̀ yín, gbogbo èso ilẹ̀ náà yóo sì wà fún jíjẹ. “Ẹ ka ìsinmi ọdún keje keje yìí lọ́nà meje, kí ọdún keje náà fi jẹ́ ọdún mọkandinlaadọta. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹwaa oṣù keje tíí ṣe ọjọ́ ètùtù, ẹ óo rán ọkunrin kan kí ó lọ fọn fèrè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín. Ẹ ya ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún náà sí mímọ́, kí ẹ sì kéde ìdáǹdè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín fún gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, yóo jẹ́ ọdún jubili fun yín. Ní ọdún náà, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀ ati sinu ìdílé rẹ̀. Ọdún jubili ni ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún yìí yóo jẹ́ fun yín. Ninu ọdún náà, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ kórè ohun tí ó bá dá hù fúnra rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ká àjàrà tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà tí ẹ kò tọ́jú. Nítorí pé, ọdún jubili ni yóo máa jẹ́ fun yín, yóo jẹ́ ọdún mímọ́ fun yín, ninu oko ni ẹ óo ti máa jẹ ohun tí ó bá so. “Ní ọdún jubili yìí, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá ta ilẹ̀ fún aládùúgbò yín, tabi tí ẹ bá ń ra ilẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìdára sí ara yín. Iye ọdún tí ó bá ti rékọjá lẹ́yìn ọdún jubili ni ẹ óo máa wò ra ilẹ̀ lọ́wọ́ aládùúgbò yín, iye ọdún tí ẹ bá fi lè gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ kan kí ọdún jubili tó dé ni òun náà yóo máa wò láti tà á fun yín. Tí ó bá jẹ́ pé ọdún pupọ ni ó kù, owó ilẹ̀ náà yóo pọ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé ọdún díẹ̀ ni, owó rẹ̀ yóo wálẹ̀; nítorí pé, iye ọdún tí ó bá lè fi gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ náà ni yóo wò láti ta ilẹ̀ náà. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìdára sí ara yín, ṣugbọn ẹ bẹ̀rù Ọlọrun yín; nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. “Nítorí náà, ẹ níláti tẹ̀lé ìlànà mi, kí ẹ sì pa òfin mi mọ́, kí ẹ lè máa gbé inú ilẹ̀ náà láìséwu. Ilẹ̀ náà yóo so ọpọlọpọ èso, ẹ óo jẹ àjẹyó, ẹ óo sì máa gbé inú rẹ̀ láìséwu. “Bí ẹ bá ń wí pé, ‘Kí ni a óo jẹ ní ọdún keje bí a kò bá gbọdọ̀ gbin ohun ọ̀gbìn, tí a kò sì gbọdọ̀ kórè?’ Èmi OLUWA yóo pàṣẹ pé kí ibukun mi wà lórí yín ní ọdún kẹfa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ yóo so èso tí yóo to yín jẹ fún ọdún mẹta. Nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn ní ọdún kẹjọ, ẹ óo tún máa rí àwọn èso tí ó ti wà ní ìpamọ́ jẹ títí tí yóo fi di ọdún kẹsan-an, tí ilẹ̀ yóo tún mú èso rẹ̀ jáde wá, àwọn èso ti àtẹ̀yìnwá ni ẹ óo máa jẹ. “Ẹ kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ kan títí ayé, nítorí pé èmi OLUWA ni mo ni gbogbo ilẹ̀, ati pé àlejò ati àtìpó ni ẹ jẹ́ fún mi. “Ninu gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní ìkáwọ́ yín, ẹ gbọdọ̀ fi ààyè sílẹ̀ fún ẹni tí ó bá fẹ́ ra ilẹ̀ pada. Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tí ó bá sì tà ninu ilẹ̀ rẹ̀, ọ̀kan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ yóo dìde láti ra ohun tí ìbátan rẹ̀ tà pada. Bí ẹni náà kò bá ní ẹbí tí ó lè ra ilẹ̀ náà pada, ṣugbọn ní ọjọ́ iwájú, tí nǹkan bá ń lọ déédé fún un, tí ó sì ní agbára láti ra ilẹ̀ náà pada, kí ó ṣírò iye ọdún tí ó ti tà á, kí ó sì san iye owó tí ó bá kù pada fún ẹni tí ó ta ilẹ̀ náà fún, lẹ́yìn náà kí ó pada sórí ilẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá ní agbára tó láti ra ilẹ̀ náà pada fúnra rẹ̀, ilẹ̀ náà yóo wà ní ọwọ́ ẹni tí ó rà á lọ́wọ́ rẹ̀ títí di ọdún jubili. Ní ọdún jubili, ẹni tí ó ra ilẹ̀ náà yóo dá a pada, ẹni tí ó ni ín yóo sì pada sórí ilẹ̀ rẹ̀. “Bí ẹnìkan bá ta ilé kan ninu ìlú olódi, ó lè rà á pada láàrin ọdún kan lẹ́yìn tí ó ti tà á. Bí ẹni náà kò bá ra ilé náà pada láàrin ọdún kan, ilé yóo di ti ẹni tí ó rà á títí lae ati ti arọmọdọmọ rẹ̀; kò ní jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ bí ọdún jubili tilẹ̀ dé. Ṣugbọn a óo ka àwọn ilé tí wọ́n wà ní àwọn ìlú tí kò ní odi pọ̀ mọ́ ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ wọn lé lórí. Ẹni tí ó ta ilẹ̀ lé rà wọ́n pada, ẹni tí ó rà á sì níláti jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ nígbà tí ọdún jubili bá dé. Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi lè ra gbogbo àwọn ilé tí wọ́n wà ní ààrin ìlú wọn pada nígbàkúùgbà. Ṣugbọn bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi kò bá lo ẹ̀tọ́ ìràpadà yìí, ẹni tí ó bá ra ilé náà lọ́wọ́ rẹ̀ ninu ìlú olódi, yóo jọ̀wọ́ ilé náà sílẹ̀ ní ọdún jubili, nítorí pé, àwọn ilé tí ó wà ní ìlú àwọn ọmọ Lefi jẹ́ ìní tiwọn láàrin àwọn eniyan Israẹli. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti gbogbogbòò, tí ó wà ní àyíká àwọn ìlú wọn, nítorí pé, ogún tiwọn nìyí títí ayérayé. “Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè bọ́ ara rẹ̀ mọ́, o níláti máa bọ́ ọ, kí ó sì máa gbé ọ̀dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àlejò ati àjèjì. O kò gbọdọ̀ gba èlé lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ, kí o sì jẹ́ kí arakunrin rẹ máa bá ọ gbé. O kò gbọdọ̀ yá a ní owó kí o gba èlé, o kò sì gbọdọ̀ fún un ní oúnjẹ kí o gba èrè. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ó mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi ilẹ̀ Kenaani fún ọ ati láti jẹ́ Ọlọrun rẹ. “Bí arakunrin rẹ, tí ń gbé tòsí rẹ bá di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún ọ, o kò gbọdọ̀ mú un sìn bí ẹrú. Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tabi bí àlejò; kí ó máa ṣiṣẹ́ fún ọ títí di ọdún jubili. Nígbà náà ni yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ati sórí ilẹ̀ ìní àwọn baba rẹ̀. Nítorí pé, iranṣẹ mi ni wọ́n, tí mo kó jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹnìkan kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú. O kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ. Láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí yín ká ni ẹ ti lè ra ẹrukunrin tabi ẹrubinrin. Ẹ sì lè rà láàrin àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín ati àwọn ìdílé wọn tí wọ́n wà pẹlu yín, tí wọ́n bí ní ilẹ̀ yín, wọ́n lè di tiyín. Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín nígbà tí ẹ bá kú, kí wọn lè jogún wọn títí lae. Wọ́n lè di ẹrú yín, ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli tí ẹ jẹ́ arakunrin ara yín, ẹ kò gbọdọ̀ mú ara yín sìn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú ara yín.
Lef 25:1-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose ní orí òkè Sinai pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín: ilẹ̀ náà gbọdọ̀ sinmi fún OLúWA. Ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi gbin oko rẹ, ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ, tí ìwọ ó sì fi kó èso wọn jọ. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí ilẹ̀ náà ní ìsinmi: ìsinmi fún OLúWA. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ. Ẹ má ṣe kórè ohun tí ó tìkára rẹ̀ hù: ẹ má ṣe kórè èso àjàrà ọgbà tí ẹ ò tọ́jú. Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ ní ìsinmi fún ọdún kan Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ọdún ìsinmi ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún yín àní fún ẹ̀yin tìkára yín, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín, àwọn alágbàṣe àti àwọn tí ń gbé pẹ̀lú yín fún ìgbà díẹ̀. Fún àwọn ohun ọ̀sìn yín, àti àwọn ẹranko búburú ní ilẹ̀ yín. Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ẹ lè jẹ. “ ‘Ọdún ìsinmi méje èyí tí í ṣe ọdún mọ́kàn-dínláàdọ́ta ni kí ẹ kà. Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè ní gbogbo ibikíbi ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́. Ní ọjọ́ ètùtù yìí, ẹ fọn fèrè yíká gbogbo ilẹ̀ yín. Ẹ ya àádọ́ta ọdún náà sọ́tọ̀ kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà. Yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Kí olúkúlùkù padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀. Àádọ́ta ọdún ni yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Ẹ má ṣe gbin ohunkóhun, ẹ kò sì gbọdọ̀ kórè ohun tí ó hù fúnrarẹ̀ tàbí kí ẹ kórè ọgbà àjàrà tí ẹ kò dá. Torí pé ọdún ìdásílẹ̀ ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún yín. Ẹ jẹ ohun tí ẹ mú jáde nínú oko náà. “ ‘Ní ọdún ìdásílẹ̀ yìí, kí olúkúlùkù gbà ohun ìní rẹ̀ padà. “ ‘Bí ẹ bá ta ilẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín tàbí bí ẹ bá ra èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ. Kí ẹ ra ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yín ní gẹ́gẹ́ bí iye owó tí ó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ pé, kí òun náà sì ta ilẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí iye ọdún rẹ̀ tókù láti kórè. Bí iye ọdún rẹ̀ bá gùn, kí iye owó rẹ̀ pọ̀, bí iye ọdún rẹ̀ bá kúrú, kí iye owó rẹ̀ kéré, torí pé ohun tí ó tà gan an ní iye èso rẹ̀. Ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ, ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run: Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín. “ ‘Ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì kíyèsi láti pa òfin mi mọ́, kí ẹ ba à le máa gbé láìléwu ní ilẹ̀ náà Nígbà yìí ni ilẹ̀ náà yóò so èso rẹ̀, ẹ ó sì jẹ àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìléwu. Ẹ le béèrè pé, “Kí ni àwa ó jẹ ní ọdún keje, bí a kò bá gbin èso tí a kò sì kórè?” Èmi ó pèsè ìbùkún sórí yín tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ yín yóò so èso tó tó fún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn rẹ̀. Bí ẹ bá gbin èso yín ní ọdún kẹjọ, àwọn èso ti tẹ́lẹ̀ ní ẹ ó máa jẹ, títí tí ìkórè ti ọdún kẹsànán yóò fi dé. “ ‘Ẹ má ṣe ta ilẹ̀ yín ní àtàpa torí pé ẹ̀yin kọ́ lẹ ni ín, ti Ọlọ́run ni, ẹ̀yin jẹ́ àjèjì àti ayálégbé, Ní gbogbo orílẹ̀-èdè ìní yín, ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìràpadà ilẹ̀ náà. “ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín bá tálákà, dé bi pé ó ta ara àwọn ẹrù rẹ̀, kí ará ilé rẹ̀ tí ó súnmọ́ ọ ra ohun tí ó tà padà. Ẹni tí kò ní ẹni tó lè rà á padà fún un, tí òun fúnrarẹ̀ sì ti lọ́rọ̀, tí ó sì ní ànító láti rà á. Kí ó mọ iye owó tí ó jẹ fún iye ọdún tí ó tà á, kí ó dá iye tí ó kù padà fún ẹni tí ó tà á fún: lẹ́yìn náà, ó lè padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí kò bá rí ọ̀nà àti san án padà fún un. Ohun tí ó tà wà ní ìkáwọ́ ẹni tí ó rà á títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ó dá a padà fún ẹni tí ó ni i ní ọdún ìdásílẹ̀, ẹni tí ó ni í tẹ́lẹ̀ lè tún padà gbà ohun ìní rẹ̀. “ ‘Bí arákùnrin kan bá ta ilé gbígbé kan ní ìlú olódi, kí ó rà á padà ní ìwọ̀n ọdún kan sí àkókò tí ó tà á, ní ìwọ̀n ọdún kan ni kí ó rà á padà. Ṣùgbọ́n bí kò bá rà á padà láàrín ọdún náà ilé náà tí ó wà láàrín ìlú ni kí ó yọ̀ǹda pátápátá fún ẹni tí ó rà á, àti àwọn ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n má da padà ní ọdún ìdásílẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ilé tí ó wà ní abúlé láìní odi ni kí a kà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ oko, a lè rà wọ́n padà, kí wọ́n sì da padà ní ọdún ìdásílẹ̀. “ ‘Àwọn ọmọ Lefi ní ẹ̀tọ́, nígbàkúgbà láti ra ilẹ̀ wọn, tí ó jẹ́ ohun ìní wọn ní àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Lefi. Torí náà ohun ìní àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n rà padà, fún àpẹẹrẹ, èyí ni pé ilẹ̀ tí a bá tà ní ìlúkílùú tí ó jẹ́ tiwọn, ó sì gbọdọ̀ di dídápadà ní ọdún ìdásílẹ̀, torí pé àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìlú àwọn Lefi ni ìní wọn láàrín àwọn ará Israẹli Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí wọ́n ti ń da ẹran tí ó jẹ́ ti ìlú wọn, wọn kò gbọdọ̀ tà wọ́n, ilẹ̀ ìní wọn láéláé ni. “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀: ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó ba à le è máa gbé láàrín yín. Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀: ẹ bẹ̀rù OLúWA kí arákùnrin yín le è máa gbé láàrín yín. Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti láti fún yín ní ilẹ̀ Kenaani àti láti jẹ́ Ọlọ́run yín. “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà dé bi pé ó ta ara rẹ̀ fún ọ bí ẹrú. Má ṣe lò ó bí ẹrú. Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tàbí àlejò láàrín yín: kí ó máa ṣiṣẹ́ sìn ọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀. Nígbà náà ni kí ó yọ̀ǹda òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n padà sí ìdílé wọn àti sí ilẹ̀ ìní baba wọn. Torí pé ìránṣẹ́ mi ni àwọn ará Israẹli jẹ́. Ẹni tí mo mú jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, torí èyí ẹ kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú. Ẹ má ṣe rorò mọ́ wọn: ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín. “ ‘Àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín lè jẹ́ láti orílẹ̀-èdè tí ó yí yín ká: Ẹ lè ra àwọn ẹrú wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn. Bákan náà, ẹ sì le è ra àwọn àlejò tí ń gbé láàrín yín, àti àwọn ìdílé wọn tí a bí sáàrín yín. Wọn yóò sì di ohun ìní yín. Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ bí ogún fún àwọn ọmọ yín; Wọ́n sì lè sọ wọ́n di ẹrú títí láé. Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rorò mọ́ ọmọ Israẹli kankan.