Lef 20:22-27
Lef 20:22-27 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ kíyèsí gbogbo àwọn ìlànà mi ati àwọn òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́, kí ilẹ̀ tí mò ń ko yín lọ má baà tì yín jáde. Ẹ kò sì gbọdọ̀ kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo lé jáde fun yín, nítorí pé tìtorí gbogbo ohun tí wọn ń ṣe wọnyi ni mo fi kórìíra wọn. Ṣugbọn mo ti ṣèlérí fun yín pé, ẹ̀yin ni ẹ ó jogún ilẹ̀ wọn, n óo fi ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, tí ó sì ń ṣàn fún wàrà ati oyin fun yín, gẹ́gẹ́ bí ohun ìní. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo eniyan. Nítorí náà, ẹ níláti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn ẹran tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́; ati láàrin àwọn ẹyẹ tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹyẹ tabi ẹranko kankan tabi àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri lórí ilẹ̀, tí mo ti yà sọ́tọ̀ fun yín pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́. Ẹ níláti jẹ́ mímọ́ fún mi, nítorí pé, mímọ́ ni èmi OLUWA, mo sì ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn eniyan kí ẹ lè máa jẹ́ tèmi. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tabi oṣó, pípa ni kí ẹ pa á; ẹ sọ wọ́n ní òkúta pa ni, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì wà lórí ara wọn.”
Lef 20:22-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina li ẹnyin o ṣe ma pa gbogbo ìlana mi mọ́, ati gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: ki ilẹ na, ninu eyiti mo mú nyin wá tẹ̀dó si, ki o má ṣe bì nyin jade. Ẹnyin kò si gbọdọ rìn ninu ìlana orilẹ-ède, ti emi lé jade kuro niwaju nyin: nitoriti nwọn ṣe gbogbo wọnyi, nitorina ni mo ṣe korira wọn. Ṣugbọn emi ti wi fun nyin pe, Ẹnyin o ní ilẹ wọn, ati pe emi o fi i fun nyin lati ní i, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède. Nitorina ki ẹnyin ki o fi ìyatọ sãrin ẹranko mimọ́ ati alaimọ́, ati sãrin ẹiyẹ alaimọ́ ati mimọ́: ki ẹnyin ki o má si ṣe fi ẹranko, tabi ẹiyẹ, tabi ohunkohun alãye kan ti nrakò lori ilẹ, ti mo ti yàsọ̀tọ fun nyin bi alaimọ́, sọ ọkàn nyin di irira. Ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́ fun mi: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, mo si ti yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède, ki ẹnyin ki o le jẹ́ ti emi. Ọkunrin pẹlu tabi obinrin ti o ní ìmo afọṣẹ, tabi ti iṣe ajẹ́, pipa ni ki a pa a: okuta ni ki a fi sọ wọn pa: ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.
Lef 20:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“ ‘Kí ẹ pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Kí ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín láti máa gbé má ba à pọ̀ yín jáde. Ẹ má ṣe tẹ̀lé àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé jáde níwájú yín torí pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ń ṣe, tí mo kórìíra wọn. Ṣùgbọ́n mo ti sọ fún yín pé, “Ẹ̀yin ni yóò jogún ilẹ̀ wọn; Èmi yóò sì fi fún yín láti jogún ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.” Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn yòókù. “ ‘Ẹ gbọdọ̀ pààlà sáàrín ẹran tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Láàrín ẹyẹ tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkóhun tí ń rìn lórí ilẹ̀: èyí tí mo yà sọ́tọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́. Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé èmi OLúWA fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi. “ ‘Ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí oṣó láàrín yín ni kí ẹ pa. Ẹ sọ wọ́n ní òkúta, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.’ ”