Lef 20:1-21

Lef 20:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose pe, Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ni Israeli, ti o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki; pipa ni ki a pa a: ki awọn enia ilẹ na ki o sọ ọ li okuta pa. Emi o si kọju mi si ọkunrin na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀; nitoriti o fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, lati sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, ati lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ́. Bi awọn enia ilẹ na ba si mú oju wọn kuro lara ọkunrin na, nigbati o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, ti nwọn kò si pa a: Nigbana li emi o kọju si ọkunrin na, ati si idile rẹ̀, emi o si ke e kuro, ati gbogbo awọn ti o ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin, lati ma ṣe àgbere tọ̀ Moleki lẹhin, lãrin awọn enia wọn. Ati ọkàn ti o ba yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, ati ajẹ́, lati ṣe àgbere tọ̀ wọn lẹhin, ani emi o kọju mi si ọkàn na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀. Nitorina ẹnyin yà ara nyin simimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Ki ẹnyin ki o si ma pa ìlana mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́. Ẹnikẹni ti o ba fi baba tabi iya rẹ̀ ré, pipa li a o pa a: o fi baba on iya rẹ̀ ré; ẹ̀jẹ rẹ̀ wà lori rẹ̀. Ati ọkunrin na ti o bá aya ọkunrin miran ṣe panṣaga, ani on ti o bá aya ẹnikeji rẹ̀ ṣe panṣaga, panṣaga ọkunrin ati panṣaga obinrin li a o pa nitõtọ. Ati ọkunrin ti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho baba rẹ̀: pipa li a o pa awọn mejeji; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn. Ọkunrin kan ti o ba bá aya ọmọ rẹ̀ dàpọ, pipa ni ki a pa awọn mejeji: nwọn ṣe rudurudu; ẹ̀jẹ wọn wà lori wọn. Ati ọkunrin ti o ba bá ọkunrin dàpọ, bi ẹni ba obinrin dàpọ, awọn mejeji li o ṣe ohun irira: pipa li a o pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn. Ati ọkunrin ti o ba fẹ́ obinrin ati iya rẹ̀, ìwabuburu ni: iná li a o fi sun wọn, ati on ati awọn; ki ìwabuburu ki o má ṣe sí lãrin nyin. Ati ọkunrin ti o ba bá ẹranko dàpọ, pipa ni ki a pa a: ki ẹnyin ki o si pa ẹranko na. Bi obinrin kan ba si sunmọ ẹranko kan, lati dubulẹ tì i, ki iwọ ki o pa obinrin na, ati ẹranko na: pipa ni ki a pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn. Ati bi ọkunrin kan ba fẹ́ arabinrin rẹ̀, ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀, ti o si ri ìhoho rẹ̀, ti on si ri ìhoho rẹ̀; ohun buburu ni; a o si ke wọn kuro loju awọn enia wọn: o tú ìhoho arabinrin rẹ̀; on o rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. Ati bi ọkunrin kan ba bá obinrin dàpọ ti o ní ohun obinrin rẹ̀ lara, ti o ba si tú u ni ìhoho; o tú isun rẹ̀ ni ìhoho, obinrin na si fi isun ẹ̀jẹ rẹ̀ hàn: awọn mejeji li a o si ke kuro lãrin awọn enia wọn. Iwọ kò si gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ, tabi ti arabinrin baba rẹ: nitoripe o tú ìhoho ibatan rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn. Bi ọkunrin kan ba si bá aya arakunrin õbi rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho arakunrin õbi rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn; nwọn o kú li ailọmọ. Bi ọkunrin kan ba si fẹ́ aya arakunrin rẹ̀, ohun-aimọ́ ni: o tú ìhoho arakunrin rẹ̀; nwọn o jẹ́ alailọmọ.

Lef 20:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ará Israẹli pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín Israẹli, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún Moleki, kí wọ́n pa á, kí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa. Èmi tìkára mi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ń ó sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ fún òrìṣà Moleki ó ti ba ibi mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú. Bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá mójú kúrò lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún òrìṣà Moleki tí wọn kò sì pa irú ẹni bẹ́ẹ̀. Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ké wọn kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn: òun àti gbogbo àwọn tí ó jọ ṣe àgbèrè tọ òrìṣà Moleki lẹ́yìn. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbèrè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀; Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. “ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín. Ẹ máa kíyèsi àṣẹ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́: Èmi ni OLúWA tí ó sọ yín di mímọ́. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé baba àti ìyá rẹ̀. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀: ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù baba rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n ti í bá obìnrin lòpọ̀: àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra: pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyátọmọ papọ̀: ìwà búburú ni èyí: iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má ba à gbilẹ̀ láàrín yín. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, ẹ gbọdọ̀ pa ọkùnrin náà àti ẹranko náà. “ ‘Bí obìnrin kan bá súnmọ́ ẹranko tí ó sì bá a lòpọ̀ obìnrin náà àti ẹranko náà ni kí ẹ pa: ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì wà lórí ara wọn. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ arábìnrin rẹ̀ yálà ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀, ohun ìtìjú ni èyí: Ẹ ó gé wọn kúrò lójú àwọn ènìyàn wọn: ó ti tàbùkù arábìnrin rẹ̀. Ẹ̀bi rẹ̀ yóò wá sórí rẹ̀. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá súnmọ́ obìnrin, ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀. Ó ti tú orísun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òun náà sì gbà á láààyè. Àwọn méjèèjì ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn. “ ‘Má ṣe bá arábìnrin baba tàbí ti ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí o ti tú ìhòhò ìbátan rẹ: Ẹ̀yin méjèèjì ni yóò ru ẹ̀bi yín. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá aya arákùnrin baba rẹ̀ lòpọ̀ ó ti tàbùkù arákùnrin baba rẹ̀. A ó jẹ wọ́n ní ìyà; wọn yóò sì kú láìlọ́mọ. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá gba aya arákùnrin rẹ̀, ohun àìmọ́ ni èyí, ó ti tàbùkù arákùnrin rẹ̀, wọn ó wà láìlọ́mọ.

Lef 20:1-21 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn ati àwọn àlejò, tí wọn ń ṣe àtìpó ní ààrin wọn tí ó bá fi èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, pípa ni kí wọ́n pa á; kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa. Èmi gan-an yóo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé ó ti fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, ó sì ti sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ó ti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Bí àwọn eniyan tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà bá mójú fo ẹni tí ó bá fi ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, tí wọn kò pa á, nígbà náà ni èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, n óo sì yọ wọ́n kúrò lára àwọn eniyan wọn, ati òun, ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n jọ ń bọ oriṣa Moleki. “Bí ẹnìkan bá ń lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, tabi àwọn oṣó, tí ó sì ń tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, n óo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Nítorí náà, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ máa ṣàkíyèsí àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn. Èmi ni OLUWA tí ó sọ yín di mímọ́. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa á. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí ara rẹ̀ nítorí pé ó ṣépè lé baba tabi ìyá rẹ̀. “Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa olúwarẹ̀ ati obinrin tí ó bá lòpọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, ó dójúti baba rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn. Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya ọmọ rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji; wọ́n ti hùwà ìbàjẹ́ láàrin ẹbí, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn. Bí ọkunrin kan bá bá ọkunrin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lòpọ̀ bí a ti ń bá obinrin lòpọ̀, àwọn mejeeji ti ṣe ohun ìríra; pípa ni kí wọ́n pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn. Bí ẹnìkan bá fẹ́ iyawo, tí ó sì tún fẹ́ ìyá iyawo náà pẹlu, ìwà burúkú ni; sísun ni kí wọ́n sun wọ́n níná, ati ọkunrin ati àwọn obinrin mejeeji, kí ìwà burúkú má baà wà láàrin yín. Bí ọkunrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, pípa ni kí ẹ pa òun ati ẹranko náà. Bí obinrin bá tọ ẹranko lọ, tí ó sì tẹ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún un láti bá a lòpọ̀, pípa ni kí ẹ pa òun ati ẹranko náà, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn. “Bí ọkunrin kan bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ baba rẹ̀ tabi ọmọ ìyá rẹ̀, tí wọ́n sì rí ìhòòhò ara wọn, ohun ìtìjú ni; lílé ni kí wọ́n lé wọn jáde kúrò ní àdúgbò, kí wọ́n sì yọ wọ́n kúrò láàrin àwọn eniyan wọn, nítorí pé ó ti bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀. Orí rẹ̀ ni yóo sì fi ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bí ọkunrin kan bá bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí obinrin yìí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, lílé ni kí wọ́n lé àwọn mejeeji kúrò ní àdúgbò, kí wọ́n sì yọ wọ́n kúrò láàrin àwọn eniyan wọn. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá arabinrin ìyá rẹ, tabi arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ìwà ìbàjẹ́ ni láàrin ẹbí. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Bí ẹnìkan bá bá aya arakunrin baba rẹ̀ lòpọ̀, ohun ìtìjú ni ó ṣe sí arakunrin baba rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn yóo kú láì bímọ. Bí ọkunrin kan bá bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lòpọ̀, tabi aya àbúrò rẹ̀, ohun àìmọ́ ni, ohun ìtìjú ni ó sì ṣe sí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ̀, àwọn mejeeji yóo kú láì bímọ.