Lef 19:1-18

Lef 19:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi OLUWA Ọlọrun nyin jẹ́ mimọ́. Ki olukuluku nyin ki o bẹ̀ru iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Ẹ máṣe yipada si ere, bẹ̃ni ki ẹnyin má si ṣe ṣe oriṣa didà fun ara nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Bi ẹnyin ba si ru ẹbọ alafia si OLUWA, ki ẹnyin ki o ru u ki ẹ le di ẹni itẹwọgbà. Li ọjọ́ ti ẹnyin ru ẹbọ na ni ki a jẹ ẹ, ati ni ijọ́ keji: bi ohun kan ba si kù ninu rẹ̀ titi di ijọ́ kẹta, ninu iná ni ki a sun u. Bi a ba si jẹ ninu rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, irira ni; ki yio dà: Nitorina ẹniti o ba jẹ ẹ ni yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀, nitoriti o bà ohun mimọ́ OLUWA jẹ́: ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. Ati nigbati ẹnyin ba nṣe ikore ilẹ nyin, iwọ kò gbọdọ ṣa igun oko rẹ li aṣatán, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ pa èṣẹ́ ikore rẹ. Iwọ kò si gbọdọ pèṣẹ́ ọgbà-àjara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká gbogbo àjara ọgbà-àjara rẹ; ki iwọ ki o fi wọn silẹ fun awọn talaka ati alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Ẹnyin kò gbọdọ jale, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe alaiṣõtọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣeké fun ara nyin. Ẹnyin kò si gbọdọ fi orukọ mi bura eké, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA. Iwọ kò gbọdọ rẹ́ ẹnikeji rẹ jẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ haramu: owo ọ̀ya alagbaṣe kò gbọdọ sùn ọdọ rẹ titi di owurọ̀. Iwọ kò gbọdọ bú aditi, tabi ki o fi ohun idugbolu siwaju afọju, ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ: iwọ kò gbọdọ gbè talaka, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe ojusaju alagbara: li ododo ni ki iwọ ki o mã ṣe idajọ ẹnikeji rẹ. Iwọ kò gbọdọ lọ soke lọ sodo bi olofófo lãrin awọn enia rẹ: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ró tì ẹ̀jẹ ẹnikeji rẹ: Emi li OLUWA. Iwọ kò gbọdọ korira arakunrin rẹ li ọkàn rẹ: ki iwọ ki o bá ẹnikeji rẹ wi, ki iwọ ki o máṣe jẹbi nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. Iwọ kò gbọdọ gbẹsan, bẹ̃ni ki o máṣe ṣe ikùnsinu si awọn ọmọ enia rẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o fẹ́ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ: Emi li OLUWA.

Lef 19:1-18 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún ìjọ eniyan Israẹli pé “Ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí pé, mímọ́ ni èmi OLUWA Ọlọrun yín. Olukuluku yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá ati baba rẹ̀, kí ó sì pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ yipada kí ẹ lọ bọ oriṣa tabi kí ẹ yá ère kankan fún ara yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóo fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú ẹbọ náà gan-an tabi ní ọjọ́ keji rẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ohun tí ẹ fi rúbọ tán. Bí ohunkohun bá kù di ọjọ́ kẹta, sísun ni ẹ gbọdọ̀ dáná sun ún. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ́ ní ọjọ́ kẹta, ohun ìríra ni, kò sì ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà mọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ẹ́ yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí pé, ó ti ba ohun mímọ́ OLUWA jẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀. “Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ, o kò gbọdọ̀ kórè títí kan ààlà. Lẹ́yìn tí o bá ti kórè tán, o kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn ohun tí o bá gbàgbé. O kò gbọdọ̀ kórè gbogbo àjàrà rẹ tán patapata, o kò sì gbọdọ̀ ṣa àwọn èso tí ó bá rẹ̀ sílẹ̀ ninu ọgbà àjàrà rẹ, o níláti fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ. “Ẹ kò gbọdọ̀ jalè, ẹ kò gbọdọ̀ fi ìwà ẹ̀tàn bá ara yín lò; ẹ kò sì gbọdọ̀ parọ́ fún ara yín. Ẹ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké, kí ẹ má baà ba orúkọ Ọlọrun yín jẹ́. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ pọ́n aládùúgbò yín lójú tabi kí ẹ jà á lólè; owó iṣẹ́ tí alágbàṣe bá ba yín ṣe kò gbọdọ̀ di ọjọ́ keji lọ́wọ́ yín. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé adití ṣépè tabi kí ẹ gbé ohun ìdìgbòlù kalẹ̀ níwájú afọ́jú, ṣugbọn ẹ níláti bẹ̀rù Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ dájọ́ èké, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka tabi ọlọ́rọ̀, ṣugbọn ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ àwọn aládùúgbò yín pẹlu òdodo. Ẹ kò gbọdọ̀ máa ṣe òfófó káàkiri láàrin àwọn eniyan yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ kọ̀ láti jẹ́rìí aládùúgbò yín, bí ẹ̀rí yín bá lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ di arakunrin yín sinu, ṣugbọn ẹ gbọdọ̀ máa sọ àsọyé pẹlu aládùúgbò yín, kí ẹ má baà gbẹ̀ṣẹ̀ nítorí tirẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san, tabi kí ẹ di ọmọ eniyan yín sinu, ṣugbọn ẹ níláti fẹ́ràn ọmọnikeji yín gẹ́gẹ́ bí ara yín. Èmi ni OLUWA.

Lef 19:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé, “Bá gbogbo àpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí Èmi OLúWA Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́. “ ‘Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá àti baba rẹ̀, kí ẹ sì ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín. “ ‘Ẹ má ṣe yípadà tọ ère òrìṣà lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ rọ ère òrìṣà idẹ fún ara yín. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín. “ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí OLúWA, kí ẹ̀yin kí ó ṣe é ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò yín. Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì; èyí tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun. Bí ẹ bá jẹ nínú èyí tí ó ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, àìmọ́ ni èyí jẹ́, kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ OLúWA jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. “ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣa ẹ̀ṣẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀). Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́. “ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké: kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni OLúWA. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládùúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù OLúWA Ọlọ́run rẹ: Èmi ni OLúWA. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúsàájú sí ẹjọ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn: ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu: Èmi ni OLúWA. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ, Èmi ni OLúWA.