Lef 11:1-47

Lef 11:1-47 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni, o wi fun wọn pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Wọnyi li ẹranko ti ẹnyin o ma jẹ ninu gbogbo ẹran ti mbẹ lori ilẹ aiye. Ohunkohun ti o ba yà bàta-ẹsẹ̀, ti o si là li ẹsẹ̀, ti o si njẹ apọjẹ, ninu ẹran, on ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹ máṣe jẹ ninu awọn ti njẹ apọjẹ, tabi awọn ti o si yà bàta-ẹsẹ̀: bi ibakasiẹ, nitoriti o njẹ apọjẹ ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ, alaimọ́ li o jasi fun nyin. Ati gara, nitoriti o njẹ apọjẹ, ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ li o jasi fun nyin. Ati ehoro, nitoriti o njẹ apọjẹ, ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ li o jasi fun nyin. Ati ẹlẹdẹ̀, bi o ti yà bàta-ẹsẹ̀, ti o si là ẹsẹ̀, ṣugbọn on kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ li o jasi fun nyin. Ninu ẹran wọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ, okú wọn li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn; alaimọ́ ni nwọn jasi fun nyin. Wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti mbẹ ninu omi: ohunkohun ti o ba ní lẹbẹ ati ipẹ́, ninu omi, ninu okun, ati ninu odò, awọn ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. Ati gbogbo eyiti kò ní lẹbẹ ati ipẹ́ li okun, ati li odò, ninu gbogbo ohun ti nrá ninu omi, ati ninu ohun alãye kan ti mbẹ ninu omi, irira ni nwọn o jasi fun nyin, Ani irira ni nwọn o ma jẹ́ fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, okú wọn ni ẹ o sì kàsi irira. Ohunkohun ti kò ba ní lẹbẹ ati ipẹ́, ninu omi, on ni ki ẹnyin kàsi irira fun. Wọnyi li ẹnyin o si ma kàsi irira ninu ẹiyẹ; awọn li a kò gbọdọ jẹ, irira ni nwọn iṣe: idì, ati aṣá-idì, ati idì-ẹja. Ati igún, ati aṣá li onirũru rẹ̀; Ati gbogbo ìwo li onirũru rẹ̀; Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀, Ati òyo ati ìgo, ati owiwi; Ati ogbugbu, ati ofù, ati àkala; Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán. Gbogbo ohun ti nrakò, ti nfò ti o si nfi mẹrẹrin rìn ni ki ẹnyin kàsi irira fun nyin. Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti nfò, ti nrakò, ti nfi gbogbo mẹrẹrin rìn, ti o ní tete lori ẹsẹ̀ wọn, lati ma fi ta lori ilẹ; Ani ninu wọnyi ni ki ẹnyin ma jẹ; eṣú ni irú rẹ̀, ati eṣú onihoho nipa irú rẹ̀, ati ọbọnbọn nipa irú rẹ̀, ati ẹlẹnga nipa irú rẹ̀. Ṣugbọn gbogbo ohun iyokù ti nfò ti nrakò, ti o ní ẹsẹ̀ mẹrin, on ni ki ẹnyin kàsi irira fun nyin. Nitori wọnyi li ẹnyin o si jẹ́ alaimọ́: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: Ẹnikẹni ti o ba si rù ohun kan ninu okú wọn ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ẹranko gbogbo ti o yà bàta-ẹsẹ̀, ti kò si là ẹsẹ̀, tabi ti kò si jẹ apọjẹ, ki o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: gbogbo ẹniti o ba farakàn wọn ki o jẹ́ alaimọ́. Ati ohunkohun ti o ba si nrìn lori ẽkanna rẹ̀, ninu gbogbo onirũru ẹranko, ti nfi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rìn, alaimọ́ ni nwọn fun nyin: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ẹniti o ba si rù okú wọn ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: alaimọ́ ni nwọn fun nyin. Wọnyi ni yio si jasi alaimọ́ fun nyin ninu ohun ti nrakò lori ilẹ; ase, ati eku, ati awun nipa irú rẹ̀. Ati ọmọ̃le, ati ahanhan, ati alãmu, ati agiliti, ati agẹmọ. Wọnyi li alaimọ́ fun nyin ninu gbogbo ohun ti nrakò: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ati lara ohunkohun ti okú wọn ba ṣubulù, ki o jasi alaimọ́; ibaṣe ohun èlo-igi, tabi aṣọ, tabi awọ, tabi àpo, ohunèlo ti o wù ki o ṣe, ninu eyiti a nṣe iṣẹ kan, a kò gbọdọ má fi bọ̀ inu omi, on o si jasi alaimọ́ titi di aṣalẹ; bẹ̃li a o si sọ ọ di mimọ́. Ati gbogbo ohunèlo amọ̀, ninu eyiti ọkan ninu okú nwọn ba bọ́ si, ohunkohun ti o wù ki o wà ninu rẹ̀ yio di alaimọ́, ki ẹnyin ki o si fọ́ ọ. Ninu onjẹ gbogbo ti a o ba jẹ, ti irú omi nì ba dà si, yio di alaimọ́: ati ohun mimu gbogbo ti a o ba mu ninu irú ohunèlo na yio di alaimọ́. Ati ohunkohun lara eyiti ninu okú wọn ba ṣubulù, yio di alaimọ́; iba ṣe àro, tabí idana, wiwó ni ki a wó wọn lulẹ: alaimọ́ ni nwọn, nwọn o si jẹ́ alaimọ́ fun nyin. Ṣugbọn orisun tabi kanga kan, ninu eyiti omi pupọ̀ gbé wà, yio jẹ́ mimọ́: ṣugbọn eyiti o ba kàn okú wọn yio jẹ́ alaimọ́. Bi ninu okú wọn ba bọ́ sara irugbìn kan ti iṣe gbigbìn, yio jẹ́ mimọ́. Ṣugbọn bi a ba dà omi sara irugbìn na, ti ninu okú wọn ba si bọ́ sinu rẹ̀, yio si jẹ́ alaimọ́ fun nyin. Ati bi ẹran kan, ninu eyiti ẹnyin ba ma jẹ, ba kú; ẹniti o ba farakàn okú rẹ̀ yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ẹniti o ba si jẹ ninu okú rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ẹniti o ba si rù okú rẹ̀ ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ yio jasi irira; a ki yio jẹ ẹ. Ohunkohun ti nfi inu wọ́, ati ohunkohun ti nfi mẹrẹrin rìn, ati ohunkohun ti o ba ní ẹsẹ̀ pupọ̀, ani ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, awọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; nitoripe irira ni nwọn. Ẹnyin kò gbọdọ fi ohun kan ti nrakò, sọ ara nyin di irira, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi wọn sọ ara nyin di alaimọ́ ti ẹnyin o fi ti ipa wọn di elẽri. Nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin: nitorina ni ki ẹnyin ki o yà ara nyin si mimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́; nitoripe mimọ́ li Emi: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi ohunkohun ti nrakò sọ ara nyin di elẽri. Nitoripe Emi li OLUWA ti o mú nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: nitorina ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́, nitoripe mimọ́ li Emi. Eyiyi li ofin ẹranko, ati ti ẹiyẹ, ati ti ẹda gbogbo alãye ti nrá ninu omi, ati ti ẹda gbogbo ti nrakò lori ilẹ: Lati fi iyatọ sãrin aimọ́ ati mimọ́, ati sãrin ohun alãye ti a ba ma jẹ, ati ohun alãye ti a ki ba jẹ.

Lef 11:1-47 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA rán Mose ati Aaroni pé kí wọ́n sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Àwọn ẹran tí wọ́n lè jẹ lára àwọn ẹran tí wọ́n wà láyé nìwọ̀nyí: Àwọn ẹran tí wọ́n bá ya pátákò ẹsẹ̀, àwọn tí ẹsẹ̀ wọ́n là ati àwọn tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ. Ninu àwọn tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ tabi tí pátákò ẹsẹ̀ wọ́n yà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àwọn wọnyi: ràkúnmí, nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín. Ati gara nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín. Ati ehoro, nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín. Ati ẹlẹ́dẹ̀ nítorí pé pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ yà, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì yà, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn, aláìmọ́ ni wọ́n. “Ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ àwọn wọnyi: gbogbo ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, kì báà jẹ́ èyí tí ó ń gbé inú òkun tabi inú odò, ẹ lè jẹ wọ́n. Ṣugbọn ohunkohun tí ó ń gbé inú òkun, tabi inú odò, ninu gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọn ń káàkiri inú omi, èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ohun ìríra ni fun yín. Ohun ìríra ni wọn yóo jẹ́ fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn, ohun ìríra ni òkú wọn gbọdọ̀ jẹ́ fun yín pẹlu. Ohunkohun tí ó ń gbé inú omi, tí kò bá ti ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ohun ìríra ni fun yín. “Àwọn wọnyi ni ẹ óo kà sí ohun ìríra, tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ẹyẹ: idì, igún, ati oríṣìí àṣá kan tí ó dàbí idì, gbogbo oniruuru àṣá, gbogbo oniruuru ẹyẹ ìwò, ògòǹgò, ati ẹyẹ kan bí ẹ̀lulùú tí ń gbé aṣálẹ̀, ẹyẹ òwìwí, ẹyẹ òòyo, ati ẹyẹ kan bí igún, ògbúgbú, òfú, ati àkàlà, ẹyẹ àkọ̀, ati oniruuru yanjayanja, ẹyẹ atọ́ka, ati àdán. “Gbogbo kòkòrò tí ó ní ìyẹ́, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn, ìríra ni wọ́n jẹ́ fun yín. Sibẹsibẹ ninu àwọn kòkòrò tí wọn ní ìyẹ́, tí wọn ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn, ẹ lè jẹ àwọn tí wọn bá ní tete tí wọ́n fi ń ta káàkiri lórí ilẹ̀. Ẹ lè jẹ àwọn wọnyi ninu wọn: Oríṣìíríṣìí eṣú ati oríṣìíríṣìí ìrẹ̀ ati oríṣìíríṣìí tata. Ṣugbọn gbogbo àwọn kòkòrò yòókù tí wọ́n ní ìyẹ́ tí wọ́n sì ní ẹsẹ̀ mẹrin, ìríra ni wọ́n jẹ́ fun yín. “Àwọn ni wọ́n lè sọ yín di aláìmọ́; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn bá là, ṣugbọn tí ẹsẹ̀ wọn kò là, tí wọn kì í sì í jẹ àpọ̀jẹ, aláìmọ́ ni wọ́n; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n di aláìmọ́. Ninu àwọn ẹranko tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn tí wọ́n sì ní èékánná jẹ́ aláìmọ́ fun yín; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; ohun àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fun yín. “Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín ninu gbogbo àwọn ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀ ni: asín, ati èkúté, ati àwọn oríṣìíríṣìí aláǹgbá ńlá, ọmọọ́lé, ọ̀ni, aláǹgbá, agílíńtí ati alágẹmọ. Wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín ninu gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ohunkohun tí òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, ìbáà jẹ́ ohun èlò igi, tabi aṣọ tabi awọ, tabi àpò, irú ohun èlò yòówù tí ó lè jẹ́, ó níláti di fífọ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn náà, yóo di mímọ́. Bí èyíkéyìí ninu wọn bá jábọ́ sórí ohun èlò amọ̀, gbogbo ohun tí ó bá wà ninu ohun èlò amọ̀ náà di aláìmọ́, fífọ́ ni kí o fọ́ ohun èlò náà. Ohunkohun tí ó bá jẹ́ jíjẹ tí ó bá wà ninu ìkòkò amọ̀ yìí, tabi tí omi inú rẹ̀ bá ta sí lára, di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá jẹ́ mímu, tí ó wà ninu rẹ̀ náà di aláìmọ́. Ohunkohun tí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, kì báà jẹ́ ààrò tabi àdògán, o gbọdọ̀ fọ́ ọ túútúú; wọ́n jẹ́ aláìmọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ jẹ́ aláìmọ́ fun yín. Tí ó bá jẹ́ odò, tabi kànga tí ó ní omi ni, wọn kì í ṣe aláìmọ́, ṣugbọn gbogbo nǹkan yòókù tí ó fara kan òkú wọn di aláìmọ́. Bí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé orí èso tí eniyan fẹ́ gbìn, èso náà kò di aláìmọ́. Ṣugbọn bí eniyan bá da omi lé èso náà lórí, tí apákan ninu òkú wọn sì já lé èso náà, ó di aláìmọ́ fun yín. “Bí ọ̀kankan ninu àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ bá kú, ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú rẹ̀ di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ òkú ẹran náà níláti fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó bá ru òkú ẹran náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. “Ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìríra, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá ń fi àyà wọ́, tabi ohunkohun tí ó bá ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn tabi ohunkohun tí ó ní ọpọlọpọ ẹsẹ̀, tabi ohunkohun tí ó ń fà lórí ilẹ̀, nítorí ohun ìríra ni wọ́n. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di ìríra; ẹ kò gbọdọ̀ kó ẹ̀gbin bá ara yín, kí ẹ má baà di aláìmọ́. Nítorí pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí mímọ́ ni èmi Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di aláìmọ́. Nítorí èmi ni OLUWA tí ó ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, láti jẹ́ Ọlọrun yín; nítorí náà, ẹ níláti jẹ́ mímọ́, nítorí pé, mímọ́ ni èmi Ọlọrun.” Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ àwọn ẹranko ati ẹyẹ ati àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọn wà ninu omi ati àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n ń fi àyà fà lórí ilẹ̀, láti fi ìyàtọ̀ sí ààrin ohun tí ó mọ́, ati ohun tí kò mọ́, ati sí ààrin ẹ̀dá alààyè tí eniyan lè jẹ, ati ẹ̀dá alààyè tí eniyan kò gbọdọ̀ jẹ.

Lef 11:1-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Ẹ sọ fún àwọn ara Israẹli pé, ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń gbé lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyí ni ẹ le jẹ. Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ. “ ‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátákò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbákasẹ ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátákò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gara (ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta) ń jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátákò ẹsẹ̀; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́dẹ̀ ya pátákò ẹsẹ̀ ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín. Ẹ má ṣe jẹ ẹran wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn. Àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín. “ ‘Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá tí ń gbé inú omi Òkun, àti nínú odò: èyíkéyìí tí ó bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ́. Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń gbé inú Òkun àti nínú odò tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́, yálà nínú gbogbo àwọn tí ń rákò tàbí láàrín gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù tí ń gbé inú omi àwọn ni kí ẹ kórìíra. Nígbà tí ẹ ti kórìíra wọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn: ẹ gbọdọ̀ kórìíra òkú wọn. Ohunkóhun tí ń gbé inú omi tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́ gbọdọ̀ jásí ìríra fún yín. “ ‘Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ni ẹ gbọdọ̀ kórìíra tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n torí pé ohun ìríra ni wọ́n: idì, oríṣìíríṣìí igún, Àwòdì àti onírúurú àṣá, Onírúurú ẹyẹ ìwò, Òwìwí, onírúurú ògòǹgò, onírúurú ẹ̀lúùlú, onírúurú àwòdì, Òwìwí kéékèèkéé, onírúurú òwìwí, Òwìwí funfun àti òwìwí ilẹ̀ pápá, àti àkàlà, àkọ̀, onírúurú òòdẹ̀, atọ́ka àti àdán. “ ‘Gbogbo kòkòrò tí ń fò tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn ni wọ́n jẹ́ ìríra fún yín irú àwọn kòkòrò oniyẹ̀ẹ́ tí wọn sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tí ẹ le jẹ nìyí: Àwọn kòkòrò tí wọ́n ní ìṣẹ́po ẹsẹ̀ láti máa fi fò lórí ilẹ̀. Nínú àwọn wọ̀nyí ni ẹ lè jẹ onírúurú eṣú, onírúurú ìrẹ̀ àti onírúurú tata. Ṣùgbọ́n gbogbo ohun ìyókù tí ń fò, tí ń rákò, tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin, òun ni kí ẹ̀yin kí ó kà sí ìríra fún yín. “ ‘Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. “ ‘Àwọn ẹranko tí pátákò wọn kò là tan tàbí tí wọn kò jẹ àpọ̀jẹ jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú èyíkéyìí nínú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Nínú gbogbo ẹranko tí ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tí ń fi èékánná wọn rìn jẹ́ aláìmọ́ fún yín: Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Wọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín. “ ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń rìn lórí ilẹ̀ ìwọ̀nyí ni ó jẹ́ àìmọ́ fún yín: Asé, eku àti oríṣìíríṣìí aláǹgbá, Ọmọnílé, alágẹmọ, aláǹgbá, ìgbín àti ọ̀gà. Nínú gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ìwọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Bí ọ̀kan nínú wọn bá kú tí wọ́n sì bọ́ sórí nǹkan kan, bí ó ti wù kí irú ohun náà wúlò tó, yóò di aláìmọ́ yálà aṣọ ni a fi ṣe é ni tàbí igi, irun aṣọ tàbí àpò, ẹ sọ ọ́ sínú omi yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn náà ni yóò tó di mímọ́. Bí èyíkéyìí nínú wọn bá bọ́ sínú ìkòkò amọ̀, gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ti di àìmọ́. Ẹ gbọdọ̀ fọ ìkòkò náà. Bí omi inú ìkòkò náà bá dà sórí èyíkéyìí nínú oúnjẹ tí ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ náà di aláìmọ́. Gbogbo ohun mímu tí a lè mú jáde láti inú rẹ̀ di àìmọ́. Gbogbo ohun tí èyíkéyìí nínú òkú wọn bá já lé lórí di àìmọ́. Yálà ààrò ni tàbí ìkòkò ìdáná wọn gbọdọ̀ di fífọ́. Wọ́n jẹ́ àìmọ́. Ẹ sì gbọdọ̀ kà wọ́n sí àìmọ́. Bí òkú wọn bá bọ́ sínú omi tàbí kànga tó ní omi nínú, omi náà kò di aláìmọ́ ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá yọ òkú wọn jáde tí ó fi ọwọ́ kàn án yóò di aláìmọ́. Bí òkú ẹranko wọ̀nyí bá bọ́ sórí ohun ọ̀gbìn tí ẹ fẹ́ gbìn wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ti da omi sí ohun ọ̀gbìn náà tí òkú wọn sì bọ́ sí orí rẹ̀ àìmọ́ ni èyí fún un yín. “ ‘Bí ẹran kan bá kú nínú àwọn tí ẹ lè jẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú rẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èyíkéyìí nínú òkú ẹranko náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú ẹranko yóò fọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wà ní àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. “ ‘Ìríra ni gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ń rìn ká orí ilẹ̀ yálà ó ń fàyàfà tàbí ó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, tàbí ó ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ̀ rìn ìríra ni èyí: Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi ohun kan tí ń rákò, sọ ara yín di ìríra, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi wọ́n sọ ara yín di aláìmọ́, tí ẹ̀yin yóò fi ti ipa wọn di eléèérí. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ torí pé mo jẹ́ mímọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ ohunkóhun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀. Èmi ni OLúWA tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi. “ ‘Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹranko, ẹyẹ, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi àti àwọn ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀. Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrín àìmọ́ àti mímọ́ láàrín ẹ̀dá alààyè, tí ẹ le jẹ àti èyí tí ẹ kò le jẹ.’ ”