Jud 1:1-4
Jud 1:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
JUDA, iranṣẹ Jesu Kristi, ati arakunrin Jakọbu, si awọn ti a pè, olufẹ ninu Ọlọrun Baba, ti a si pamọ́ fun Jesu Kristi: Ki ãnu, ati alafia, ati ifẹ ki o mã bi si i fun nyin. Olufẹ, nigbati mo fi aisimi gbogbo kọwe si nyin niti igbala ti iṣe ti gbogbo enia, nko gbọdọ ṣaima kọwé si nyin, ki n si gbà nyin niyanju lati mã ja gidigidi fun igbagbọ́, ti a ti fi lé awọn enia mimọ́ lọwọ lẹ̃kanṣoṣo. Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa.
Jud 1:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Juda, iranṣẹ Jesu Kristi, tí mo jẹ́ arakunrin Jakọbu ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí Ọlọrun Baba fẹ́ràn, tí Jesu Kristi pè láti pamọ́. Kí àánú, alaafia ati ìfẹ́ kí ó máa pọ̀ sí i fun yín. Ẹ̀yin olùfẹ́, mo ti gbìyànjú títí láti kọ ìwé si yín nípa ìgbàlà tí a jọ ní, nígbà tí mo rí i pé ó di dandan pé kí n kọ ìwé si yín, kí n rọ̀ yín pé kí ẹ máa jà fún igbagbọ tí Ọlọrun fi fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lẹ́ẹ̀kan gbọ̀n-ọ́n. Nítorí àwọn kan ti yọ́ wọ inú ìjọ, àwọn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ nípa wọn lọ́jọ́ tó ti pẹ́ pé ìdájọ́ ń bọ̀ sórí wọn. Wọ́n jẹ́ aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, wọ́n yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa pada sí àìdára láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú wọn, wọ́n sẹ́ Ọ̀gá wa kanṣoṣo ati Oluwa wa Jesu Kristi.
Jud 1:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Juda, ìránṣẹ́ Jesu Kristi àti arákùnrin Jakọbu, Sí àwọn tí a pè, olùfẹ́ nínú Ọlọ́run Baba, tí a pamọ́ fún Jesu Kristi: Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ kí ó máa jẹ́ tiyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmí ní ìtara láti kọ̀wé sí i yín nípa ìgbàlà tí í ṣe ti gbogbo ènìyàn, n kò gbọdọ̀ má kọ̀wé sí yín, kí ń sì gbà yín ní ìyànjú láti máa jà fitafita fún ìgbàgbọ́, tí a ti fi lé àwọn ènìyàn mímọ́ lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọ́n ń yọ́ wọlé, àwọn ẹni tí a ti yàn láti ìgbà àtijọ́ sí ẹ̀bi yìí, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń sẹ́ Olúwa wa kan ṣoṣo náà, àní, Jesu Kristi Olúwa.