Joṣ 8:1-29

Joṣ 8:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o má ṣe fò ọ: mú gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ ki iwọ ki o si dide, ki o si gòke lọ si Ai: kiyesi i, emi ti fi ọba Ai, ati awọn enia rẹ̀, ati ilunla rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀ lé ọ lọwọ: Iwọ o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀: kìki ikogun rẹ̀, ati ohun-ọ̀sin rẹ̀, li ẹnyin o mú ni ikogun fun ara nyin: rán enia lọ iba lẹhin ilu na. Joṣua si dide, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun, lati gòke lọ si Ai: Joṣua si yàn ẹgba mẹdogun, alagbara akọni, o si rán wọn lo li oru. O si paṣẹ fun wọn pe, Wò o, ẹnyin o ba tì ilu na, ani lẹhin ilu na: ẹ má ṣe jìna pupọ̀ si ilu na, ṣugbọn ki gbogbo nyin ki o murasilẹ. Ati emi, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu mi, yio sunmọ ilu na: yio si ṣe, nigbati nwọn ba jade si wa, gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju, awa o si sá niwaju wọn; Nitoriti nwọn o jade si wa, titi awa o fi fà wọn jade kuro ni ilu; nitoriti nwọn o wipe, Nwọn sá niwaju wa, gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju; nitorina li awa o sá niwaju wọn: Nigbana li ẹnyin o dide ni buba, ẹnyin o si gbà ilu na: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin yio fi i lé nyin lọwọ. Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gbà ilu na tán, ki ẹnyin ki o si tinabọ ilu na; gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA ni ki ẹnyin ki o ṣe: wò o, mo ti fi aṣẹ fun nyin na. Nitorina ni Joṣua ṣe rán wọn lọ: nwọn lọ iba, nwọn si joko li agbedemeji Beti-eli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn Ai: ṣugbọn Joṣua dó li oru na lãrin awọn enia. Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si kà awọn enia, o si gòke lọ si Ai, on, ati awọn àgba Israeli niwaju awọn enia. Ati gbogbo awọn enia, ani awọn ọmọ-ogun ti mbẹ pẹlu rẹ̀, nwọn gòke lọ, nwọn si sunmọtosi, nwọn si wá siwaju ilu na, nwọn si dó ni ìha ariwa Ai; afonifoji si mbẹ li agbedemeji wọn ati Ai. O si mú to bi ẹgbẹdọgbọ̀n enia, o si fi wọn si ibuba li agbedemeji Betieli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn ilu na. Nwọn si yàn awọn enia si ipò, ani gbogbo ogun ti mbẹ ni ìha ariwa ilu na, ati awọn enia ti o ba ni ìha ìwọ-õrùn ilu na; Joṣua si lọ li oru na sãrin afonifoji na. O si ṣe, nigbati ọba Ai ri i, nwọn yára nwọn si dide ni kùtukutu, awọn ọkunrin ilu na si jade si Israeli lati jagun, ati on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, niwaju pẹtẹlẹ̀, ibi ti a ti yàn tẹlẹ; ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn ti o ba dè e mbẹ lẹhin ilu. Joṣua ati gbogbo awọn Israeli si ṣe bi ẹniti a lé niwaju wọn, nwọn si sá gbà ọ̀na aginjú. A si pe gbogbo enia ti mbẹ ni Ai jọ lati lepa wọn: nwọn si lepa Joṣua, a si fà wọn jade kuro ni ilu. Kò si kù ọkunrin kan ni Ai tabi Beti-eli, ti kò jade tọ̀ Israeli: nwọn si fi ilú nla silẹ ni ṣíṣí nwọn si lepa Israeli. OLUWA si wi fun Joṣua pe, Nà ọ̀kọ ti mbẹ li ọwọ́ rẹ nì si Ai; nitoriti emi o fi i lé ọ lọwọ. Joṣua si nà ọ̀kọ na ti o ni li ọwọ́ rẹ̀ si ilu na. Awọn ti o ba si dide kánkan kuro ni ipò wọn, bi o si ti nàwọ́ rẹ̀, nwọn sare, nwọn si wọ̀ ilu na lọ, nwọn si gbà a; nwọn si yára tinabọ ilu na. Nigbati awọn ọkunrin Ai boju wo ẹhin wọn, kiyesi i, nwọn ri ẹ̃fi ilu na ngòke lọ si ọrun, nwọn kò si lí agbara lati gbà ihin tabi ọhún sálọ: awọn enia ti o sá lọ si aginjù si yipada si awọn ti nlepa. Nigbati Joṣua ati gbogbo Israeli ri bi awọn ti o ba ti gbà ilu, ti ẹ̃fi ilu na si gòke, nwọn si yipada, nwọn si pa awọn ọkunrin Ai. Awọn ti ara keji si yọ si wọn lati ilu na wá; bẹ̃ni nwọn wà li agbedemeji Israeli, awọn miran li apa ihin, awọn miran li apa ọhún: nwọn si pa wọn, bẹ̃ni nwọn kò si jẹ ki ọkan ki o kù tabi ki o sálọ ninu wọn. Nwọn si mú ọba Ai lãye, nwọn si mú u wá sọdọ Joṣua. O si ṣe, nigbati Israeli pari pipa gbogbo awọn ara ilu Ai ni igbẹ́, ati ni aginjù ni ibi ti nwọn lé wọn si, ti gbogbo wọn si ti oju idà ṣubu, titi a fi run wọn, ni gbogbo awọn ọmọ Israeli pada si Ai, nwọn si fi oju idà kọlù u. O si ṣe, gbogbo awọn ti o ṣubu ni ijọ́ na, ati ọkunrin ati obinrin, jẹ́ ẹgba mẹfa, ani gbogbo ọkunrin Ai. Nitoriti Joṣua kò fà ọwọ́ rẹ̀ ti o fi nà ọ̀kọ sẹhin, titi o fi run gbogbo awọn ara ilu Ai tútu. Kìki ohun-ọ̀sin ati ikogun ilu na ni Israeli kó fun ara wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA ti o palaṣẹ fun Joṣua. Joṣua si kun Ai, o sọ ọ di òkiti lailai, ani ahoro titi di oni-oloni. Ọba Ai li o si so rọ̀ lori igi titi di aṣalẹ: bi õrùn si ti wọ̀, Joṣua paṣẹ ki a sọ okú rẹ̀ kuro lori igi kalẹ, ki a si wọ́ ọ jù si atiwọ̀ ibode ilu na, ki a si kó òkiti nla okuta lé e lori, ti mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.

Joṣ 8:1-29 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ kí o lọ sí ìlú Ai. Wò ó! Mo ti fi ọba Ai, ati àwọn eniyan rẹ̀, ìlú rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Bí o ti ṣe sí Jẹriko ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe sí Ai ati ọba rẹ̀. Ṣugbọn ẹ dá ìkógun ati àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó wà níbẹ̀ sí, kí ẹ sì kó o gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín; ẹ ba ní ibùba lẹ́yìn odi ìlú náà.” Joṣua bá múra, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí ìlú Ai. Joṣua yan ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) akikanju ọmọ ogun, ó rán wọn jáde ní alẹ́. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ fara pamọ́ lẹ́yìn ìlú náà, ẹ má jìnnà sí i pupọ, ṣugbọn ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀. Èmi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu mi nìkan ni a óo wọ ìlú náà. Nígbà tí wọ́n bá jáde sí wa láti bá wa jà bí i ti àkọ́kọ́, a óo sá fún wọn. Wọn yóo máa lé wa lọ títí tí a óo fi tàn wọ́n jáde kúrò ninu ìlú, nítorí wọn yóo ṣe bí à ń sálọ fún wọn bíi ti àkọ́kọ́ ni; nítorí náà ni a óo ṣe sá fún wọn. Ẹ̀yin ẹ dìde níbi tí ẹ farapamọ́ sí, kí ẹ sì gba ìlú náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yóo fi lé yín lọ́wọ́. Gbàrà tí ẹ bá ti gba ìlú náà tán, ẹ ti iná bọ̀ ọ́, kí ẹ sì ṣe bí àṣẹ OLUWA. Ó jẹ́ àṣẹ tí mo pa fun yín.” Joṣua bá rán wọn ṣiwaju, wọ́n sì lọ sí ibi tí wọn yóo fara pamọ́ sí ní ìwọ̀ oòrùn Ai, láàrin Ai ati Bẹtẹli. Ṣugbọn Joṣua wà pẹlu àwọn eniyan ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn eniyan náà jọ. Òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli ṣáájú wọn, wọ́n lọ sí Ai. Gbogbo àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá a lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìlú Ai, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí apá ìhà àríwá ìlú náà, odò kan ni ó wà láàrin wọn ati ìlú Ai. Joṣua ṣa nǹkan bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọmọ ogun, ó fi wọ́n pamọ́ sí ààrin Bẹtẹli ati Ai ní apá ìwọ̀ oòrùn Ai. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi àwọn ọmọ ogun wọn sí ipò, àwọn tí wọn yóo gbógun ti ìlú gan-an wà ní apá ìhà àríwá ìlú, àwọn tí wọn yóo wà lẹ́yìn wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ṣugbọn Joṣua alára wà ní àfonífojì ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Nígbà tí ọba Ai ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ rí i, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ìlú náà bá yára, wọ́n jáde lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá ọ̀nà Araba láti kó ogun pàdé àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé àwọn kan ti farapamọ́ sẹ́yìn ìlú. Joṣua ati gbogbo ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá ṣe bí ẹni pé àwọn ará Ai ti ṣẹgun àwọn, wọ́n sì sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ. Àwọn ará Ai bá pe gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ìlú jọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ Israẹli lọ. Bí wọ́n ti ń lé Joṣua lọ ni wọ́n ń jìnnà sí ìlú. Kò sì sí ẹyọ ọkunrin kan tí ó kù ní Ai ati Bẹtẹli tí kò jáde láti lépa àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n fi ìlẹ̀kùn ẹnubodè sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n ń lé àwọn ọmọ Israẹli lọ. OLUWA sọ fun Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ sí ọ̀kánkán Ai, nítorí n óo fi lé ọ lọ́wọ́.” Joṣua bá na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀kánkán ìlú náà. Gbogbo àwọn tí wọn farapamọ́ bá yára dìde ní ibi tí wọ́n wà. Bí Joṣua ti na ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sáré wọ inú ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára sọ iná sí i. Nígbà tí àwọn ará Ai bojú wẹ̀yìn, tí wọ́n rí i tí èéfín yọ ní ìlú wọn, wọn kò ní agbára mọ́ láti sá síhìn-ín tabi sọ́hùn-ún, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ yíjú pada sí wọn. Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn tí wọn farapamọ́ ti gba ìlú náà, tí èéfín sì ti yọ sókè, wọ́n yipada, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ará Ai. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ninu ìlú náà jáde sí wọn, àwọn ará Ai sì wà ní agbede meji àwọn ọmọ Israẹli, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ keji. Àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n ní ìpakúpa títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan. Ṣugbọn wọ́n mú ọba Ai láàyè, wọ́n sì mú un tọ Joṣua wá. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti fi idà pa gbogbo àwọn ará Ai tán ninu aṣálẹ̀, ní ibi tí wọ́n ti ń lé wọn lọ, wọ́n pada sí ìlú Ai, wọ́n sì fi idà pa gbogbo wọn patapata. Gbogbo àwọn ará Ai tí wọ́n pa ní ọjọ́ náà, ati ọkunrin, ati obinrin, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaafa (12,000). Nítorí pé ọwọ́ tí Joṣua fi na ọ̀kọ̀ sókè, kò gbé e sílẹ̀ títí tí wọ́n fi pa gbogbo àwọn ará Ai tán. Àfi ẹran ọ̀sìn ati dúkìá ìlú náà ni àwọn ọmọ Israẹli kó ní ìkógun gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua. Joṣua dáná sun ìlú Ai, ó sì sọ ọ́ di òkítì àlàpà títí di òní olónìí. Ó so ọba Ai kọ́ sórí igi kan títí di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọn já òkú rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì wọ́ ọ sí ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, wọ́n kó òkúta jọ lé e lórí, òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.

Joṣ 8:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù, kí àyà kí ó má ṣe fò ọ́. Kó gbogbo àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ, kí ẹ gòkè lọ gbógun ti Ai. Nítorí mo ti fi ọba Ai, àwọn ènìyàn rẹ̀, ìlú u rẹ̀ àti ilẹ̀ ẹ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ìwọ yóò sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, ohun ìkógun wọn àti ohun ọ̀sìn wọn ni kí ẹ̀yin mú fún ara yín. Rán ènìyàn kí wọ́n ba sí ẹ̀yìn ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun jáde lọ láti dojúkọ Ai. Ó sì yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru. Pẹ̀lú àwọn àṣẹ wọ̀nyí: “Ẹ fi etí sílẹ̀ dáradára. Ẹ ba sí ẹ̀yìn ìlú náà. Ẹ má ṣe jìnnà sí i púpọ̀. Kí gbogbo yín wà ní ìmúrasílẹ̀. Èmi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi yóò súnmọ́ ìlú náà; Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà bá jáde sí wa, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìṣáájú, àwa yóò sì sá kúrò níwájú u wọn. Wọn yóò sì lépa wa títí àwa ó fi tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà, nítorí tí wọn yóò wí pé, wọ́n ń sálọ kúrò ní ọ̀dọ̀ wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ṣe ní ìṣáájú. Nítorí náà bí a bá sá kúrò fún wọn, ẹ̀yin yóò dìde kúrò ní ibùba, ẹ ó sì gba ìlú náà. OLúWA Ọlọ́run yín yóò sì fi lé e yín lọ́wọ́. Nígbà tí ẹ bá ti gba ìlú náà, kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́. Kí ẹ ṣe ohun tí OLúWA pàṣẹ. Mo ti fi àṣẹ fún un yín ná.” Nígbà náà ni Joṣua rán wọn lọ. Wọ́n sì lọ sí ibùba, wọ́n sì sùn ní àárín Beteli àti Ai, ní ìwọ̀-oòrùn Ai. Ṣùgbọ́n Joṣua wá dúró pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní òru ọjọ́ náà. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Joṣua kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, òun àti àwọn olórí Israẹli, wọ́n wọ́de ogun lọ sí Ai. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì súnmọ́ tòsí ìlú náà, wọ́n sì dé iwájú u rẹ̀. Wọ́n sì pàgọ́ ní ìhà àríwá Ai. Àfonífojì sì wà ní agbede-méjì wọn àti ìlú náà. Joṣua sì ti fi bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọmọ-ogun pamọ́ sí àárín Beteli àti Ai, sí ìwọ̀-oòrùn ìlú náà. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ-ogun sí ipò wọn, gbogbo àwọn tí ó wà ní ibùdó lọ sí àríwá ìlú náà àti àwọn tí ó sápamọ́ sí ìwọ̀-oòrùn rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà Joṣua lọ sí àfonífojì. Nígbà tí ọba Ai rí èyí, òun àti gbogbo ọkùnrin ìlú náà yára jáde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti pàdé ogun Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aginjù. Ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àwọn kan wà ní ibùba ní ẹ̀yìn ìlú náà. Joṣua àti gbogbo àwọn Israẹli sì ṣe bí ẹni tí a lé padà níwájú wọn, wọ́n sì sá gba ọ̀nà aginjù. A sì pe gbogbo àwọn ọkùnrin Ai jọ láti lépa wọn, wọ́n sì lépa Joṣua títí wọ́n fi tàn wọ́n jáde nínú ìlú náà. Kò sì ku ọkùnrin kan ní Ai tàbí Beteli tí kò tẹ̀lé Israẹli. Wọ́n sì fi ìlẹ̀kùn ibodè ìlú náà sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli. Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ sí Ai, nítorí tí èmi yóò fi ìlú náà lé ọ ní ọwọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua sì na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí Ai. Bí ó ti ṣe èyí tán, àwọn ọkùnrin tí ó ba sì dìde kánkán kúrò ní ipò wọn, wọ́n sáré síwájú. Wọn wọ ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára ti iná bọ̀ ọ́. Àwọn ọkùnrin Ai bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, ààyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Israẹli tí wọ́n tí ń sálọ sí aginjù ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn. Nígbà tí Joṣua àti gbogbo àwọn ará Israẹli rí i pé àwọn tí ó bá ti gba ìlú náà, tí èéfín ìlú náà sì ń gòkè, wọ́n yí padà wọ́n sì kọlu àwọn ọkùnrin Ai. Àwọn ọmọ-ogun tí ó ba náà sì yípadà sí wọn láti inú ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wà ní agbede-méjì àwọn ará Israẹli ní ìhà méjèèjì. Israẹli sì pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì jẹ́ kí ọ̀kan kí ó yè tàbí kí ó sálọ nínú wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n mú ọba Ai láààyè, wọ́n sì mu un tọ Joṣua wá. Nígbà tí Israẹli parí pípa gbogbo àwọn ìlú Ai ní pápá àti ní aginjù ní ibi tí wọ́n ti lépa wọn lọ, tí gbogbo wọ́n sì ti ojú idà ṣubú, tí a fi pa gbogbo wọn tan, gbogbo àwọn Israẹli sì padà sí Ai, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú. Ẹgbẹ̀rún méjìlá ọkùnrin àti obìnrin ni ó kú ní ọjọ́ náà—gbogbo wọn jẹ́ àwọn ènìyàn Ai. Nítorí tí Joṣua kò fa ọwọ́ rẹ̀ tí ó di ọ̀kọ̀ mú sí ẹ̀yìn, títí ó fi pa gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú Ai run. Ṣùgbọ́n Israẹli kó ẹran ọ̀sìn àti ìkógun ti ìlú yìí fún ara wọn, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Joṣua. Joṣua sì jó Ai, ó sì sọ ọ́ di ààtàn, àní ahoro di òní yìí. Ó sì gbé ọba Ai kọ́ orí igi, ó sì fi kalẹ̀ síbẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí oòrùn sì ti wọ̀ ni Joṣua pàṣẹ fún wọn láti sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní orí igi, kí wọn sì wọ́ ọ jù sí àtiwọ ẹnu ibodè ìlú náà. Wọ́n sì kó òkìtì òkúta ńlá lé e ní orí, èyí tí ó wà títí di òní yìí.