Joṣ 7:20-21
Joṣ 7:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Akani si da Joṣua lohùn, o si wipe, Nitõtọ ni mo ṣẹ̀ si OLUWA, Ọlọrun Israeli, bayi bayi ni mo ṣe: Nigbati mo ri ẹ̀wu Babeli kan daradara ninu ikogun, ati igba ṣekeli fadakà, ati dindi wurà kan oloṣuwọn ãdọta ṣekeli, mo ṣojukokoro wọn, mo si mú wọn; sawò o, a fi wọn pamọ́ ni ilẹ lãrin agọ́ mi, ati fadakà na labẹ rẹ̀.
Joṣ 7:20-21 Yoruba Bible (YCE)
Akani dá Joṣua lóhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ohun tí mo sì ṣe nìyí: Nígbà tí mo wo ààrin àwọn ìkógun, mo rí ẹ̀wù àwọ̀lékè dáradára kan láti Ṣinari, ati igba ìwọ̀n Ṣekeli fadaka, ati ọ̀pá wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọta Ṣekeli, wọ́n wọ̀ mí lójú, mo bá kó wọn, mo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ ninu àgọ́ mi. Fadaka ni mo fi tẹ́lẹ̀.”
Joṣ 7:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Akani sì dáhùn pé, “Òtítọ́ ni! Mo ti ṣẹ̀ sí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Nǹkan tí mo ṣe nìyìí: Nígbà tí mo rí ẹ̀wù Babeli kan tí ó dára nínú ìkógun, àti igba ṣékélì fàdákà àti odindi wúrà olóṣùnwọ́n àádọ́ta ṣékélì, mo ṣe ojúkòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ mi àti fàdákà ní abẹ́ rẹ̀.”