Joṣ 7:1-26
Joṣ 7:1-26 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí pé ẹnìkan mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, láti inú ẹ̀yà Juda, mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀, inú sì bí OLUWA gidigidi sí àwọn ọmọ Israẹli. Joṣua rán àwọn ọkunrin kan láti Jẹriko lọ sí ìlú Ai, lẹ́bàá Betafeni ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe amí ilẹ̀ náà wá.” Àwọn ọkunrin náà lọ ṣe amí ìlú Ai. Wọ́n pada tọ Joṣua wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Má wulẹ̀ jẹ́ kí gbogbo àwọn eniyan lọ gbógun ti ìlú Ai, yan àwọn eniyan bí ẹgbaa (2,000) tabi ẹgbẹẹdogun (3,000) kí wọ́n lọ gbógun ti ìlú náà. Má wulẹ̀ lọ dààmú gbogbo àwọn eniyan lásán, nítorí pé àwọn ará Ai kò pọ̀ rárá.” Nítorí náà, nǹkan bí ẹgbẹẹdogun (3,000) ninu àwọn ọmọ Israẹli lọ gbógun tì wọ́n. Ṣugbọn wọ́n sá níwájú àwọn ará Ai. Àwọn ọmọ ogun Ai pa tó mẹrindinlogoji (36) ninu wọn, wọ́n sì lé gbogbo wọn kúrò ní ẹnubodè wọn títí dé Ṣebarimu. Wọ́n ń pa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Ọkàn àwọn ọmọ Israẹli bá dààmú, àyà wọn sì já. Joṣua fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ hàn, òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli dojúbolẹ̀ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì ku eruku sórí. Joṣua bá gbadura, ó ní, “Yéè! OLUWA Ọlọrun! Kí ló dé tí o fi kó àwọn eniyan wọnyi gòkè odò Jọdani láti fà wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wọ́n run? Ìbá tẹ́ wa lọ́rùn kí á wà ní òdìkejì odò Jọdani, kí á sì máa gbé ibẹ̀. OLUWA, kí ni mo tún lè sọ, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn? Àwọn ará Kenaani, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóo gbọ́, wọn yóo yí wa po, wọn yóo sì pa wá run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, OLUWA! Kí lo wá fẹ́ ṣe, nítorí orúkọ ńlá rẹ?” Nígbà náà ni OLUWA wí fun Joṣua pé, “Dìde. Kí ló dé tí o fi dojúbolẹ̀? Israẹli ti ṣẹ̀, wọ́n ti rú òfin mi. Wọ́n ti mú ninu àwọn ohun tí a yà sọ́tọ̀, wọ́n ti jalè, wọ́n ti purọ́, wọn sì ti fi ohun tí wọ́n jí pamọ́ sábẹ́ àwọn ohun ìní wọn. Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìparun. N kò ní wà pẹlu yín mọ́, àfi bí ẹ bá run àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ tí ó wà láàrin yín. Ẹ dìde, ẹ ya àwọn eniyan náà sí mímọ́; kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ti sọ pé àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ wà láàrin ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ẹ kò sì ní lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá yín títí tí ẹ óo fi kó àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ kúrò láàrin yín.’ Nítorí náà, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, a óo mú gbogbo yín wá siwaju OLUWA ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ẹ̀yà tí OLUWA bá mú yóo wá ní agbo-ilé agbo-ilé. Agbo-ilé tí OLUWA bá mú yóo wá ní ìdílé-ìdílé. Àwọn ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé tí OLUWA bá mú yóo wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú pẹlu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, iná ni a óo dá sun àtòun, ati gbogbo nǹkan tí ó ní, nítorí pé ó ti ṣẹ̀ sí majẹmu OLUWA. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli.” Joṣua gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli wá ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú ẹ̀yà Juda. Ó kó ẹ̀yà Juda wá ní agbo-ilé kọ̀ọ̀kan, wọn sì mú agbo-ilé Sera. Ó kó agbo-ilé Sera wá, wọ́n sì fa àwọn ọkunrin ibẹ̀ kalẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú Sabidi. Wọ́n sì fa àwọn ọkunrin ìdílé Sabidi kalẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, ti ẹ̀yà Juda. Joṣua wí fún Akani pé, “Ọmọ mi, fi ògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí o sì yìn ín. Jẹ́wọ́ ohun tí o ṣe, má fi pamọ́ fún mi.” Akani dá Joṣua lóhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ohun tí mo sì ṣe nìyí: Nígbà tí mo wo ààrin àwọn ìkógun, mo rí ẹ̀wù àwọ̀lékè dáradára kan láti Ṣinari, ati igba ìwọ̀n Ṣekeli fadaka, ati ọ̀pá wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọta Ṣekeli, wọ́n wọ̀ mí lójú, mo bá kó wọn, mo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ ninu àgọ́ mi. Fadaka ni mo fi tẹ́lẹ̀.” Joṣua bá ranṣẹ, wọ́n sáré lọ wo inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n bá àwọn nǹkan náà ní ibi tí ó bò wọ́n mọ́, ó fi fadaka tẹ́lẹ̀. Wọ́n hú wọn jáde ninu àgọ́ rẹ̀, wọ́n kó wọn wá siwaju Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì tẹ́ wọn kalẹ̀ níwájú OLUWA. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá mú Akani, ọmọ Sera, ati fadaka, ati ẹ̀wù àwọ̀lékè, ati ọ̀pá wúrà, ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, àwọn akọ mààlúù rẹ̀ ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àwọn aguntan rẹ̀ ati àgọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní, wọ́n kó wọn lọ sí àfonífojì Akori. Joṣua bá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa sinu gbogbo ìyọnu yìí? OLUWA sì ti kó ìyọnu bá ìwọ náà lónìí.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá sọ wọ́n ní òkúta pa, wọ́n sì dáná sun wọ́n. Wọ́n kó òkítì òkúta jọ sórí rẹ̀. Òkítì òkúta náà sì wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. OLUWA bá yí ibinu rẹ̀ pada. Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì Akori.
Joṣ 7:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀yà Juda, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú OLúWA ru sí àwọn ará Israẹli. Joṣua rán àwọn ọkùnrin láti Jeriko lọ sí Ai, tí ó súnmọ́ Beti-Afeni ní ìlà-oòrùn Beteli, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Ai wò. Nígbà tí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua, wọ́n wí pé, “Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ni láti gòkè lọ bá Ai jà. Rán ẹgbẹ̀rún méjì tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin láti gbà á, kí ó má ṣe dá gbogbo àwọn ènìyàn ní agara, nítorí ìba ọkùnrin díẹ̀ ní ó wà níbẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ní àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin lọ; ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ai lé wọn sá, Àwọn ènìyàn Ai sì pa àwọn bí mẹ́rìn-dínlógójì nínú wọn. Wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli láti ibodè ìlú títí dé Ṣebarimu, wọ́n sì pa àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀. Àyà àwọn ènìyàn náà sì já, ọkàn wọn sì pami. Joṣua sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA títí di àṣálẹ́. Àwọn àgbà Israẹli sì ṣe bákan náà, wọ́n ku eruku sí orí wọn. Joṣua sì wí pé, “Háà, OLúWA Olódùmarè, nítorí kín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá Jordani, láti fi wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdìkejì Jordani? OLúWA, kín ni èmi yóò sọ nísinsin yìí tí Israẹli sì ti sá níwájú ọ̀tá a rẹ̀? Àwọn Kenaani àti àwọn ènìyàn ìlú tí ó kù náà yóò gbọ́ èyí, wọn yóò sì yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò ní ayé. Kí ni ìwọ ó ha ṣe fún orúkọ ńlá à rẹ?” OLúWA sì sọ fún Joṣua pé, “Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojúbolẹ̀? Israẹli ti ṣẹ̀; Wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, Wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn. Ìdí nì èyí tí àwọn ará Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀tá a wọn nítorí pé àwọn gan an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pa ohun ìyàsọ́tọ̀ run kúrò ní àárín yín. “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni OLúWA, Ọlọ́run Israẹli wí: Ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárín yín, Israẹli. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò. “ ‘Ní òwúrọ̀, kí ẹ mú ará yín wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí OLúWA bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí OLúWA bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí OLúWA bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan. Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, a ó fi iná pa á run, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú OLúWA jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Israẹli!’ ” Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Joṣua mú Israẹli wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Juda. Àwọn agbo ilé e Juda wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sera. Ó sì mú agbo ilé Sera wá síwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Sabdi. Joṣua sì mú ìdílé Simri wá síwájú ní ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, a sì mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ti ẹ̀yà Juda. Nígbà náà ní Joṣua sọ fún Akani pé, “Ọmọ mi fi ògo fún OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, kí o sì fi ìyìn fún un. Sọ fún mi ohun tí ìwọ ti ṣe, má ṣe fi pamọ́ fún mi.” Akani sì dáhùn pé, “Òtítọ́ ni! Mo ti ṣẹ̀ sí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Nǹkan tí mo ṣe nìyìí: Nígbà tí mo rí ẹ̀wù Babeli kan tí ó dára nínú ìkógun, àti igba ṣékélì fàdákà àti odindi wúrà olóṣùnwọ́n àádọ́ta ṣékélì, mo ṣe ojúkòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ mi àti fàdákà ní abẹ́ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ran àwọn òjíṣẹ́, wọ́n sì sáré wọ inú àgọ́ náà, ó sì wà níbẹ̀, a sì fi pamọ́ nínú àgọ́ ọ rẹ̀, àti fàdákà ní abẹ́ ẹ rẹ̀. Wọ́n sì mú àwọn nǹkan náà jáde láti inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n mú wọn wá fún Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fi wọ́n lélẹ̀ níwájú OLúWA. Nígbà náà ni Joṣua pẹ̀lú gbogbo Israẹli, mú Akani ọmọ Sera, fàdákà, ẹ̀wù àti wúrà tí a dà, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ni, wọ́n sì kó wọn lọ sí ibi Àfonífojì Akori. Joṣua sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ mú wàhálà yìí wá sí orí wa? OLúWA yóò mú ìpọ́njú wá sí orí ìwọ náà lónìí.” Nígbà náà ni gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sọ àwọn tókù ní òkúta pa tán, wọ́n sì jó wọn níná. Wọ́n sì kó òkìtì òkúta ńlá lé Akani lórí títí di òní yìí. Nígbà náà ní OLúWA sì yí ìbínú gbígbóná rẹ̀ padà. Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Àfonífojì Akori láti ìgbà náà.
Joṣ 7:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN awọn ọmọ Israeli dẹ́ṣẹ kan niti ohun ìyasọtọ: nitoriti Akani, ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀ya Juda, mú ninu ohun ìyasọtọ: ibinu OLUWA si rú si awọn ọmọ Israeli. Joṣua si rán enia lati Jeriko lọ si Ai, ti mbẹ lẹba Beti-afeni, ni ìla-õrùn Beti-eli, o si wi fun wọn pe, Ẹ gòke lọ ki ẹ si ṣamí ilẹ na. Awọn enia na gòke lọ nwọn si ṣamí Ai. Nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, nwọn si wi fun u pe, Má ṣe jẹ ki gbogbo enia ki o gòke lọ; ṣugbọn jẹ ki ìwọn ẹgba tabi ẹgbẹdogun enia ki o gòke lọ ki nwọn si kọlù Ai; má ṣe jẹ ki gbogbo enia lọ ṣiṣẹ́ nibẹ̀; nitori diẹ ni nwọn. Bẹ̃ni ìwọn ẹgbẹdogun enia gòke lọ sibẹ̀: nwọn si sá niwaju awọn enia Ai. Awọn enia Ai pa enia mẹrindilogoji ninu wọn: nwọn si lepa wọn lati ẹnubode titi dé Ṣebarimu, nwọn si pa wọn bi nwọn ti nsọkalẹ: àiya awọn enia na já, o si di omi. Joṣua si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si dojubolẹ niwaju apoti OLUWA titi di aṣalẹ, on ati awọn àgba Israeli; nwọn si bù ekuru si ori wọn. Joṣua si wipe, Yẽ, Oluwa ỌLỌRUN, nitori kini iwọ fi mú awọn enia yi kọja Jordani, lati fi wa lé ọwọ́ awọn Amori, lati pa wa run? awa iba mọ̀ ki a joko ni ìha keji ọhún Jordani! A, Oluwa, kili emi o wi, nigbati Israeli pa ẹhin wọn dà niwaju awọn ọtá wọn! Nitoriti awọn ara Kenaani ati gbogbo awọn ara ilẹ na yio gbọ́, nwọn o si yi wa ká, nwọn o si ke orukọ wa kuro li aiye: kini iwọ o ha ṣe fun orukọ nla rẹ? OLUWA si wi fun Joṣua pe, Dide; ẽṣe ti iwọ fi doju rẹ bolẹ bayi? Israeli ti dẹ̀ṣẹ, nwọn si ti bà majẹmu mi jẹ́ ti mo palaṣẹ fun wọn: ani nwọn ti mú ninu ohun ìyasọtọ nì; nwọn si jale, nwọn si ṣe agabagebe pẹlu, ani nwọn si fi i sinu ẹrù wọn. Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin. Dide, yà awọn enia na simimọ́, ki o si wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ fun ọla: nitori bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wipe; Ohun ìyasọtọ kan mbẹ ninu rẹ, iwọ Israeli: iwọ ki yio le duro niwaju awọn ọtá rẹ, titi ẹnyin o fi mú ohun ìyasọtọ na kuro ninu nyin. Nitorina li owurọ̀ a o mú nyin wá gẹgẹ bi ẹ̀ya nyin: yio si ṣe, ẹ̀ya ti OLUWA ba mú yio wá gẹgẹ ni idile idile: ati idile ti OLUWA ba mú yio wá li agbagbole; ati agbole ti OLUWA ba mú yio wá li ọkunrin kọkan. Yio si ṣe, ẹniti a ba mú pẹlu ohun ìyasọtọ na, a o fi iná sun u, on ati ohun gbogbo ti o ní: nitoriti o rú ofin OLUWA, ati nitoriti o si hù ìwakiwa ni Israeli. Bẹ̃ni Joṣua dide ni kùtukutu owurọ̀, o si mú Israeli wá gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; a si mú ẹ̀ya Juda: O si mú idile Juda wá; a si mu idile Sera: o si mú idile Sera wá li ọkunrin kọkan; a si mú Sabdi: O si mú ara ile rẹ̀ li ọkunrin kọkan; a si mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ninu, ẹ̀ya Judah. Joṣua si wi fun Akani pe, Ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ, fi ogo fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, ki o si jẹwọ fun u; ki o si sọ fun mi nisisiyi, ohun ti iwọ se; má ṣe pa a mọ́ fun mi. Akani si da Joṣua lohùn, o si wipe, Nitõtọ ni mo ṣẹ̀ si OLUWA, Ọlọrun Israeli, bayi bayi ni mo ṣe: Nigbati mo ri ẹ̀wu Babeli kan daradara ninu ikogun, ati igba ṣekeli fadakà, ati dindi wurà kan oloṣuwọn ãdọta ṣekeli, mo ṣojukokoro wọn, mo si mú wọn; sawò o, a fi wọn pamọ́ ni ilẹ lãrin agọ́ mi, ati fadakà na labẹ rẹ̀. Joṣua si rán onṣẹ, nwọn si sare wọ̀ inu agọ́ na; si kiyesi i, a fi i pamọ́ ninu agọ́ rẹ̀, ati fadakà labẹ rẹ̀. Nwọn si mú wọn jade lãrin agọ́ na, nwọn si mú wọn wá sọdọ Joṣua, ati sọdọ gbogbo awọn ọmọ Israeli, nwọn si fi wọn lelẹ niwaju OLUWA. Joṣua, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si mú Akani ọmọ Sera, ati fadakà na, ati ẹ̀wu na, ati dindi wurà na, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ati akọ-mãlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, ati agutan rẹ̀, ati agọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; nwọn si mú wọn lọ si ibi afonifoji Akoru. Joṣua si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yọ wa lẹnu? OLUWA yio yọ iwọ na lẹnu li oni yi. Gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta pa; nwọn si dánasun wọn, nwọn sọ wọn li okuta. Nwọn si kó òkiti okuta nla kan lé e lori titi di oni-oloni; OLUWA si yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀. Nitorina li a ṣe npè orukọ ibẹ̀ li Afonifoji Akoru, titi di oni-oloni.