Joṣ 7:1-15

Joṣ 7:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

ṢUGBỌN awọn ọmọ Israeli dẹ́ṣẹ kan niti ohun ìyasọtọ: nitoriti Akani, ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀ya Juda, mú ninu ohun ìyasọtọ: ibinu OLUWA si rú si awọn ọmọ Israeli. Joṣua si rán enia lati Jeriko lọ si Ai, ti mbẹ lẹba Beti-afeni, ni ìla-õrùn Beti-eli, o si wi fun wọn pe, Ẹ gòke lọ ki ẹ si ṣamí ilẹ na. Awọn enia na gòke lọ nwọn si ṣamí Ai. Nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, nwọn si wi fun u pe, Má ṣe jẹ ki gbogbo enia ki o gòke lọ; ṣugbọn jẹ ki ìwọn ẹgba tabi ẹgbẹdogun enia ki o gòke lọ ki nwọn si kọlù Ai; má ṣe jẹ ki gbogbo enia lọ ṣiṣẹ́ nibẹ̀; nitori diẹ ni nwọn. Bẹ̃ni ìwọn ẹgbẹdogun enia gòke lọ sibẹ̀: nwọn si sá niwaju awọn enia Ai. Awọn enia Ai pa enia mẹrindilogoji ninu wọn: nwọn si lepa wọn lati ẹnubode titi dé Ṣebarimu, nwọn si pa wọn bi nwọn ti nsọkalẹ: àiya awọn enia na já, o si di omi. Joṣua si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si dojubolẹ niwaju apoti OLUWA titi di aṣalẹ, on ati awọn àgba Israeli; nwọn si bù ekuru si ori wọn. Joṣua si wipe, Yẽ, Oluwa ỌLỌRUN, nitori kini iwọ fi mú awọn enia yi kọja Jordani, lati fi wa lé ọwọ́ awọn Amori, lati pa wa run? awa iba mọ̀ ki a joko ni ìha keji ọhún Jordani! A, Oluwa, kili emi o wi, nigbati Israeli pa ẹhin wọn dà niwaju awọn ọtá wọn! Nitoriti awọn ara Kenaani ati gbogbo awọn ara ilẹ na yio gbọ́, nwọn o si yi wa ká, nwọn o si ke orukọ wa kuro li aiye: kini iwọ o ha ṣe fun orukọ nla rẹ? OLUWA si wi fun Joṣua pe, Dide; ẽṣe ti iwọ fi doju rẹ bolẹ bayi? Israeli ti dẹ̀ṣẹ, nwọn si ti bà majẹmu mi jẹ́ ti mo palaṣẹ fun wọn: ani nwọn ti mú ninu ohun ìyasọtọ nì; nwọn si jale, nwọn si ṣe agabagebe pẹlu, ani nwọn si fi i sinu ẹrù wọn. Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin. Dide, yà awọn enia na simimọ́, ki o si wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ fun ọla: nitori bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wipe; Ohun ìyasọtọ kan mbẹ ninu rẹ, iwọ Israeli: iwọ ki yio le duro niwaju awọn ọtá rẹ, titi ẹnyin o fi mú ohun ìyasọtọ na kuro ninu nyin. Nitorina li owurọ̀ a o mú nyin wá gẹgẹ bi ẹ̀ya nyin: yio si ṣe, ẹ̀ya ti OLUWA ba mú yio wá gẹgẹ ni idile idile: ati idile ti OLUWA ba mú yio wá li agbagbole; ati agbole ti OLUWA ba mú yio wá li ọkunrin kọkan. Yio si ṣe, ẹniti a ba mú pẹlu ohun ìyasọtọ na, a o fi iná sun u, on ati ohun gbogbo ti o ní: nitoriti o rú ofin OLUWA, ati nitoriti o si hù ìwakiwa ni Israeli.

Joṣ 7:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí pé ẹnìkan mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, láti inú ẹ̀yà Juda, mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀, inú sì bí OLUWA gidigidi sí àwọn ọmọ Israẹli. Joṣua rán àwọn ọkunrin kan láti Jẹriko lọ sí ìlú Ai, lẹ́bàá Betafeni ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe amí ilẹ̀ náà wá.” Àwọn ọkunrin náà lọ ṣe amí ìlú Ai. Wọ́n pada tọ Joṣua wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Má wulẹ̀ jẹ́ kí gbogbo àwọn eniyan lọ gbógun ti ìlú Ai, yan àwọn eniyan bí ẹgbaa (2,000) tabi ẹgbẹẹdogun (3,000) kí wọ́n lọ gbógun ti ìlú náà. Má wulẹ̀ lọ dààmú gbogbo àwọn eniyan lásán, nítorí pé àwọn ará Ai kò pọ̀ rárá.” Nítorí náà, nǹkan bí ẹgbẹẹdogun (3,000) ninu àwọn ọmọ Israẹli lọ gbógun tì wọ́n. Ṣugbọn wọ́n sá níwájú àwọn ará Ai. Àwọn ọmọ ogun Ai pa tó mẹrindinlogoji (36) ninu wọn, wọ́n sì lé gbogbo wọn kúrò ní ẹnubodè wọn títí dé Ṣebarimu. Wọ́n ń pa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Ọkàn àwọn ọmọ Israẹli bá dààmú, àyà wọn sì já. Joṣua fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ hàn, òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli dojúbolẹ̀ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì ku eruku sórí. Joṣua bá gbadura, ó ní, “Yéè! OLUWA Ọlọrun! Kí ló dé tí o fi kó àwọn eniyan wọnyi gòkè odò Jọdani láti fà wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wọ́n run? Ìbá tẹ́ wa lọ́rùn kí á wà ní òdìkejì odò Jọdani, kí á sì máa gbé ibẹ̀. OLUWA, kí ni mo tún lè sọ, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn? Àwọn ará Kenaani, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóo gbọ́, wọn yóo yí wa po, wọn yóo sì pa wá run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, OLUWA! Kí lo wá fẹ́ ṣe, nítorí orúkọ ńlá rẹ?” Nígbà náà ni OLUWA wí fun Joṣua pé, “Dìde. Kí ló dé tí o fi dojúbolẹ̀? Israẹli ti ṣẹ̀, wọ́n ti rú òfin mi. Wọ́n ti mú ninu àwọn ohun tí a yà sọ́tọ̀, wọ́n ti jalè, wọ́n ti purọ́, wọn sì ti fi ohun tí wọ́n jí pamọ́ sábẹ́ àwọn ohun ìní wọn. Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìparun. N kò ní wà pẹlu yín mọ́, àfi bí ẹ bá run àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ tí ó wà láàrin yín. Ẹ dìde, ẹ ya àwọn eniyan náà sí mímọ́; kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ti sọ pé àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ wà láàrin ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ẹ kò sì ní lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá yín títí tí ẹ óo fi kó àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ kúrò láàrin yín.’ Nítorí náà, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, a óo mú gbogbo yín wá siwaju OLUWA ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ẹ̀yà tí OLUWA bá mú yóo wá ní agbo-ilé agbo-ilé. Agbo-ilé tí OLUWA bá mú yóo wá ní ìdílé-ìdílé. Àwọn ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé tí OLUWA bá mú yóo wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú pẹlu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, iná ni a óo dá sun àtòun, ati gbogbo nǹkan tí ó ní, nítorí pé ó ti ṣẹ̀ sí majẹmu OLUWA. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli.”

Joṣ 7:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀yà Juda, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú OLúWA ru sí àwọn ará Israẹli. Joṣua rán àwọn ọkùnrin láti Jeriko lọ sí Ai, tí ó súnmọ́ Beti-Afeni ní ìlà-oòrùn Beteli, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Ai wò. Nígbà tí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua, wọ́n wí pé, “Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ni láti gòkè lọ bá Ai jà. Rán ẹgbẹ̀rún méjì tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin láti gbà á, kí ó má ṣe dá gbogbo àwọn ènìyàn ní agara, nítorí ìba ọkùnrin díẹ̀ ní ó wà níbẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ní àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin lọ; ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ai lé wọn sá, Àwọn ènìyàn Ai sì pa àwọn bí mẹ́rìn-dínlógójì nínú wọn. Wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli láti ibodè ìlú títí dé Ṣebarimu, wọ́n sì pa àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀. Àyà àwọn ènìyàn náà sì já, ọkàn wọn sì pami. Joṣua sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA títí di àṣálẹ́. Àwọn àgbà Israẹli sì ṣe bákan náà, wọ́n ku eruku sí orí wọn. Joṣua sì wí pé, “Háà, OLúWA Olódùmarè, nítorí kín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá Jordani, láti fi wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdìkejì Jordani? OLúWA, kín ni èmi yóò sọ nísinsin yìí tí Israẹli sì ti sá níwájú ọ̀tá a rẹ̀? Àwọn Kenaani àti àwọn ènìyàn ìlú tí ó kù náà yóò gbọ́ èyí, wọn yóò sì yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò ní ayé. Kí ni ìwọ ó ha ṣe fún orúkọ ńlá à rẹ?” OLúWA sì sọ fún Joṣua pé, “Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojúbolẹ̀? Israẹli ti ṣẹ̀; Wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, Wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn. Ìdí nì èyí tí àwọn ará Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀tá a wọn nítorí pé àwọn gan an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pa ohun ìyàsọ́tọ̀ run kúrò ní àárín yín. “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni OLúWA, Ọlọ́run Israẹli wí: Ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárín yín, Israẹli. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò. “ ‘Ní òwúrọ̀, kí ẹ mú ará yín wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí OLúWA bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí OLúWA bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí OLúWA bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan. Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, a ó fi iná pa á run, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú OLúWA jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Israẹli!’ ”