Joṣ 23:4-16

Joṣ 23:4-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

Wò o, emi ti pín awọn orilẹ-ède wọnyi ti o kù fun nyin, ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya nyin, lati Jordani lọ, pẹlu gbogbo awọn orilẹ-ède ti mo ti ke kuro, ani titi dé okun nla ni ìha ìwọ-õrùn. OLUWA Ọlọrun nyin, on ni yio tì wọn jade kuro niwaju nyin, yio si lé wọn kuro li oju nyin; ẹnyin o si ní ilẹ wọn, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin. Nitorina ẹ mura gidigidi lati tọju ati lati ṣe ohun gbogbo ti a kọ sinu iwé ofin Mose, ki ẹnyin ki o má ṣe yipada kuro ninu rẹ̀ si ọwọ́ ọtún tabi si ọwọ́ òsi; Ki ẹnyin ki o má ṣe wá sãrin awọn orilẹ-ède wọnyi, awọn wọnyi ti o kù pẹlu nyin; ki ẹnyin má ṣe da orukọ oriṣa wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe fi wọn bura, ẹ má ṣe sìn wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe tẹriba fun wọn: Ṣugbọn ki ẹnyin faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe titi di oni. Nitoriti OLUWA ti lé awọn orilẹ-ède nla ati alagbara kuro niwaju nyin; ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, kò sí ọkunrin kan ti o ti iduro niwaju nyin titi di oni. Ọkunrin kan ninu nyin yio lé ẹgbẹrun: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti njà fun nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun nyin. Nitorina ẹ kiyesara nyin gidigidi, ki ẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin. Ṣugbọn bi ẹ ba daṣà ati pada, ti ẹ si faramọ́ iyokù awọn orile-ède wọnyi, ani awọn wọnyi ti o kù lãrin nyin, ti ẹ si bá wọn gbeyawo, ti ẹ si nwọle tọ̀ wọn, ti awọn si nwọle tọ̀ nyin: Ki ẹnyin ki o mọ̀ dajudaju pe OLUWA Ọlọrun nyin ki yio lé awọn orilẹ-ède wọnyi jade mọ́ kuro niwaju nyin; ṣugbọn nwọn o jẹ́ okùn-didẹ ati ẹgẹ́ fun nyin, ati paṣán ni ìha nyin, ati ẹgún li oju nyin, titi ẹ o fi ṣegbé kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin. Ẹnyin kiyesi i, li oni emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: ényin si mọ̀ li àiya nyin gbogbo, ati li ọkàn nyin gbogbo pe, kò sí ohun kan ti o tase ninu ohun rere gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ niti nyin; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ fun nyin, kò si sí ohun ti o tase ninu rẹ̀. Yio si ṣe, gẹgẹ bi ohun rere gbogbo ti ṣẹ fun nyin, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin; bẹ̃ni OLUWA yio mú ibi gbogbo bá nyin, titi yio fi pa nyin run kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin. Nigbati ẹnyin ba re majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin kọja, ti o palaṣẹ fun nyin, ti ẹ ba si lọ, ti ẹ ba nsìn oriṣa ti ẹnyin ba tẹ̀ ori nyin bà fun wọn; nigbana ni ibinu OLUWA yio rú si nyin, ẹnyin o si ṣegbé kánkan kuro ni ilẹ daradara ti o ti fi fun nyin.

Joṣ 23:4-16 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ wò ó! Gbogbo ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí a kò tíì ṣẹgun, ati gbogbo àwọn tí a ti ṣẹgun ni mo ti pín fun yín gẹ́gẹ́ bí ogún yín, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn, OLUWA Ọlọrun yín yóo máa tì wọ́n sẹ́yìn fun yín, yóo máa lé wọn kúrò níwájú yín, ẹ óo sì gba ilẹ̀ wọn bí OLUWA Ọlọrun yín ti ṣèlérí fun yín. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sinu ìwé òfin Mose. Ẹ kò gbọdọ̀ yẹ ẹsẹ̀ kúrò ninu wọn sí ọ̀tún tabi sí òsì, kí ẹ má baà darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ́kù láàrin yín, kí ẹ má baà máa bọ àwọn oriṣa wọn, tabi kí ẹ máa fi orúkọ wọn búra, tabi kí ẹ máa sìn wọ́n, tabi kí ẹ máa foríbalẹ̀ fún wọn. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ súnmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe títí di òní. Nítorí pé, OLUWA ti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi tí wọ́n sì ní agbára kúrò níwájú yín, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè ṣẹgun yín títí di òní. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ninu yín ni ó ń bá ẹgbẹrun eniyan jà, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ sì fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín. Nítorí pé, bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ṣẹ́kù láàrin yín, tí ẹ̀ ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn, tí àwọn náà sì ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ yín, ẹ mọ̀ dájú pé, OLUWA Ọlọrun yín kò ní lé àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jáde kúrò fun yín mọ́; ṣugbọn wọn óo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fun yín, OLUWA yóo sì fi wọ́n ṣe pàṣán tí yóo máa fi nà yín. Wọn óo dàbí ẹ̀gún, wọn óo máa gún yín lójú, títí tí ẹ óo fi parun patapata lórí ilẹ̀ dáradára tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. “Nisinsinyii, ó tó àkókò fún mi láti kú, gbogbo yín ni ẹ sì mọ̀ dájúdájú ninu ọkàn yín pé, ninu gbogbo àwọn ohun rere tí OLUWA Ọlọrun yín ṣèlérí fun yín, kò sí èyí tí kò mú ṣẹ. Gbogbo wọn patapata ni wọ́n ṣẹ, ẹyọ kan kò yẹ̀ ninu wọn. Ṣugbọn bí OLUWA Ọlọrun yín ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa àwọn nǹkan dáradára tí ó pinnu láti ṣe fun yín, bákan náà ni yóo mú kí gbogbo àwọn nǹkan burúkú tí ó ti ṣèlérí wá sórí yín, títí tí yóo fi run yín patapata lórí ilẹ̀ dáradára tí ó fun yín, tí ẹ kò bá pa majẹmu tí ó pa láṣẹ fun yín mọ́. Tí ẹ bá lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, inú yóo bí OLUWA si yín, ẹ óo sì parun kíákíá lórí ilẹ̀ dáradára tí ó ti fun yín.”

Joṣ 23:4-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ rántí bí mo ṣe pín ogún ìní fún àwọn ẹ̀yà yín ní ilẹ̀ orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó kù; àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti ṣẹ́gun ní àárín Jordani àti Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn. OLúWA Ọlọ́run yín fúnrarẹ̀ yóò lé wọn jáde kúrò ní ọ̀nà yín, yóò sì tì wọ́n jáde ní iwájú yín, ẹ̀yin yóò sì gba ilẹ̀ ìní wọn, gẹ́gẹ́ bí OLúWA Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún yín. “Ẹ jẹ́ alágbára gidigidi, kí ẹ sì ṣọ́ra láti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun tí a kọ sí inú Ìwé Ofin Mose, láìyí padà sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Ẹ má ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ́kù láàrín yín; ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra. Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn. Ṣùgbọ́n ẹ di OLúWA Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí. “OLúWA ti lé àwọn orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín; títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojúkọ yín. Ọ̀kan nínú yín lé ẹgbẹ̀rún ọ̀tá, nítorí tí OLúWA Ọlọ́run yín jà fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣọ́ra gidigidi láti fẹ́ràn OLúWA Ọlọ́run yín. “Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yí padà, tí ẹ sì gba ìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́kù lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù láàrín yín, tí ẹ sì ń fọmọ fún ara yín ní ìyàwó, tí ẹ sì bá wọn ní àjọṣepọ̀, Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé OLúWA Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín. Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹ́kùn àti tàkúté fún un yín, pàṣán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí OLúWA Ọlọ́run yín ti fi fún yín. “Nísinsin yìí èmi ti fẹ́ máa lọ sí ibi tí àwọn àgbà ń rè. Ẹ mọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti àyà yín pé, kò sí ohun kan tí ó kùnà nínú àwọn ìlérí rere gbogbo tí OLúWA Ọlọ́run yín fi fún un yín. Gbogbo ìlérí tó ti ṣe kò sí ọ̀kan tí ó kùnà. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti OLúWA Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni OLúWA yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín. Bí ẹ bá sẹ̀ sí májẹ̀mú OLúWA Ọlọ́run yín, èyí tí ó pàṣẹ fún un yín, tí ẹ bá sì lọ tí ẹ sì sin àwọn òrìṣà tí ẹ sì tẹ orí ba fún wọn, ìbínú gbígbóná OLúWA yóò wá sórí i yín, ẹ̀yin yóò sì ṣègbé kíákíá kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.”