Joṣ 22:10-32

Joṣ 22:10-32 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbati nwọn si dé eti Jordani, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan lẹba Jordani, pẹpẹ ti o tobi lati wò. Awọn ọmọ Israeli si gbọ́ pe, Kiyesi i, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan dojukọ ilẹ Kenaani, lẹba Jordani ni ìha keji awọn ọmọ Israeli. Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli kó ara wọn jọ ni Ṣilo, lati gòke lọ ibá wọn jagun. Awọn ọmọ Israeli si rán Finehasi ọmọ Eleasari alufa si awọn ọmọ Reubeni, ati si awọn ọmọ Gadi, ati si àbọ ẹ̀ya Manasse ni ilẹ Gileadi; Ati awọn olori mẹwa pẹlu rẹ̀, olori ile baba kọkan fun gbogbo ẹ̀ya Israeli; olukuluku si ni olori ile baba wọn ninu ẹgbẹgbẹrun Israeli. Nwọn si dé ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ati ọdọ àbọ ẹ̀ya Manasse, ni ilẹ Gileadi, nwọn si bá wọn sọ̀rọ pe, Bayi ni gbogbo ijọ OLUWA wi, Ẹ̀ṣẹ kili eyiti ẹnyin da si Ọlọrun Israeli, lati pada li oni kuro lẹhin OLUWA, li eyiti ẹnyin mọ pẹpẹ kan fun ara nyin, ki ẹnyin ki o le ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni? Ẹ̀ṣẹ ti Peori kò to fun wa kọ́, ti a kò ti iwẹ̀mọ́ ninu rẹ̀ titi di oni, bi o tilẹ ṣe pe ajakalẹ-àrun wà ninu ijọ OLUWA, Ti ẹnyin fi pada kuro lẹhin OLUWA li oni? Yio si ṣe, bi ẹnyin ti ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni, li ọla, on o binu si gbogbo ijọ Israeli. Njẹ bi o ba ṣepe ilẹ iní nyin kò ba mọ́, ẹ rekọja si ilẹ iní OLUWA, nibiti agọ́ OLUWA ngbé, ki ẹ si gbà ilẹ-iní lãrin wa: ṣugbọn ẹnyin má ṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ si wa, ni mimọ pẹpẹ miran fun ara nyin lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa. Ṣe bẹ̃ni Akani ọmọ Sera da ẹ̀ṣẹ niti ohun ìyasọtọ, ti ibinu si dé sori gbogbo ijọ Israeli? ọkunrin na kò nikan ṣegbé ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀. Nigbana ni awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse dahùn, nwọn si wi fun awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli pe, OLUWA, Ọlọrun awọn ọlọrun, OLUWA Ọlọrun awọn ọlọrun, On mọ̀, Israeli pẹlu yio si mọ̀; bi o ba ṣepe ni ìṣọtẹ ni, tabi bi ni irekọja si OLUWA, (má ṣe gbà wa li oni,) Ni awa fi mọ pẹpẹ fun ara wa, lati yipada kuro lẹhin OLUWA; tabi bi o ba ṣe pe lati ru ẹbọ sisun, tabi ẹbọ ohunjijẹ, tabi ẹbọ alafia lori rẹ̀, ki OLUWA tikala rẹ̀ ki o bère rẹ̀. Bi o ba ṣepe awa kò kuku ṣe e nitori aniyàn, ati nitori nkan yi pe, Lẹhinọla awọn ọmọ nyin le wi fun awọn ọmọ wa pe, Kili o kàn nyin niti OLUWA, Ọlọrun Israeli? Nitoriti Ọlọrun ti fi Jordani pàla li agbedemeji awa ati ẹnyin, ẹnyin ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi; ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA: bẹ̃li awọn ọmọ nyin yio mu ki awọn ọmọ wa ki o dẹkun ati ma bẹ̀ru OLUWA. Nitorina li a ṣe wipe, Ẹ jẹ ki a mura nisisiyi lati mọ pẹpẹ kan, ki iṣe fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan: Ṣugbọn ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin, ati awọn iran wa lẹhin wa, ki awa ki o le ma fi ẹbọ sisun wa, ati ẹbọ wa, pẹlu ẹbọ alafia wa jọsìn fun OLUWA niwaju rẹ̀; ki awọn ọmọ nyin ki o má ba wi fun awọn ọmọ wa lẹhinọla pe, Ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA. Nitorina ni awa ṣe wipe, Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi bẹ̃ fun wa, tabi fun awọn iran wa lẹhinọla, awa o si wipe, Ẹ wò apẹrẹ pẹpẹ OLUWA, ti awọn baba wa mọ, ki iṣe fun ẹbọ sisun, bẹ̃ni ki iṣe fun ẹbọ; ṣugbọn o jasi ẹrí li agbedemeji awa ati ẹnyin. Ki Ọlọrun má jẹ ki awa ki o ṣọ̀tẹ si OLUWA, ki awa si pada li oni kuro lẹhin OLUWA, lati mọ pẹpẹ fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ ohunjije, tabi fun ẹbọ kan, lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa ti mbẹ niwaju agọ́ rẹ̀. Nigbati Finehasi alufa, ati awọn olori ijọ, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli ti o wà pẹlu rẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ ti awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati awọn ọmọ Manasse sọ, o dùnmọ́ wọn. Finehasi ọmọ Eleasari alufa si wi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Manasse pe, Li oni li awa mọ̀ pe OLUWA wà lãrin wa, nitoriti ẹnyin kò dẹ̀ṣẹ yi si OLUWA: nisisiyi ẹnyin yọ awọn ọmọ Israeli kuro lọwọ OLUWA. Finehasi ọmọ Eleasari alufa, ati awọn olori, si pada lati ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati lati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ni ilẹ Gileadi, si ilẹ Kenaani, sọdọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si mú ìhin pada tọ̀ wọn wá.

Joṣ 22:10-32 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí wọ́n dé agbègbè odò Jọdani, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase tẹ́ pẹpẹ kan lẹ́bàá Jọdani, pẹpẹ náà tóbi pupọ. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti tẹ́ pẹpẹ kan sí ìhà ibi tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, ní agbègbè odò Jọdani, ní àtiwọ ilẹ̀ Kenaani, Nigba tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ èyí, gbogbo wọ́n bá péjọ sí Ṣilo láti lọ bá wọn jagun. Àwọn ọmọ Israẹli ranṣẹ sí ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ Gileadi, àwọn tí wọ́n rán ni Finehasi, ọmọ Eleasari, alufaa, ati àwọn olórí mẹ́wàá; wọ́n yan olórí kọ̀ọ̀kan láti inú ìdílé Israẹli kọ̀ọ̀kan, olukuluku wọn sì jẹ́ baálé ninu ìdílé wọn. Wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ Gileadi, wọ́n sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọ eniyan Ọlọrun ní kí á bèèrè lọ́wọ́ yín pé, irú ìwà ọ̀dàlẹ̀ wo ni ẹ hù sí OLUWA Ọlọrun Israẹli yìí? Ẹ ti yára pada lẹ́yìn OLUWA, ẹ kò sì tẹ̀lé e mọ́, nítorí pé ẹ ti ṣe oríkunkun sí OLUWA nípa títẹ́ pẹpẹ fún ara yín. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá ní Peori, tí a kò tíì wẹ ara wa mọ́ kúrò ninu rẹ̀ kò tíì tó? Ṣebí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ náà ni àjàkálẹ̀ àrùn fi bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin ìjọ eniyan OLUWA? Kí ni ìbáà ṣẹlẹ̀, tí ẹ fi níláti yára yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ sì ni bí ẹ bá ṣe oríkunkun sí OLUWA lónìí, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni yóo bínú sí lọ́la. Bí ó bá jẹ́ pé ilẹ̀ yín kò mọ́ tó láti máa sin OLUWA níbẹ̀ ni, ẹ rékọjá sinu ilẹ̀ OLUWA, níbi tí àgọ́ rẹ̀ wà, ẹ wá gba ilẹ̀ láàrin wa. Ẹ ṣá má ti ṣe oríkunkun sí OLUWA, tabi kí ẹ sọ gbogbo wa di olóríkunkun nípa títẹ́ pẹpẹ mìíràn, yàtọ̀ sí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa. Ṣebí ìwà ọ̀dàlẹ̀ báyìí náà ni Akani ọmọ Sera hù nígbà tí ó kọ̀, tí kò tẹ̀lé àṣẹ tí OLUWA pa nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ OLUWA, ṣebí gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli ni OLUWA bínú sí? Àbí òun nìkan ni ó ṣègbé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?” Ni àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase bá dá àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli lóhùn pé, “Ọlọrun Alágbára, Ọlọrun ni OLUWA! Ọlọrun Alágbára, Ọlọrun ni OLUWA, ó mọ ìdí tí a fi ṣe ohun tí a ṣe, a sì fẹ́ kí ẹ̀yin ọmọ Israẹli náà mọ̀ pẹlu. Tí ó bá jẹ́ pé oríkunkun ati ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni a fẹ́ hù sí OLUWA ni a fi ṣe ohun tí a ṣe, ẹ má ṣàánú wa. Bí ó bá jẹ́ pé a tẹ́ pẹpẹ tí yóo mú wa kọ OLUWA sílẹ̀, tabi pé a tẹ́ pẹpẹ fún ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ alaafia, kí OLUWA gbẹ̀san lára wa. Ká má rí i! Ohun tí ó mú wa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ẹ̀rù ń bà wá pé, nígbà tí ó bá di ọjọ́ iwájú, àwọn ọmọ yín lè wí fún àwọn ọmọ wa pé, ‘Ọ̀rọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli kò kàn yín. Nítorí OLUWA ti fi odò Jọdani ṣe ààlà láàrin àwa pẹlu yín, ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’ Àwọn ọmọ yín sì lè mú kí àwọn ọmọ wa má sin OLUWA mọ́. Nítorí náà, ni a ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á tẹ́ pẹpẹ kan,’ kì í ṣe fún ẹbọ sísun tabi ẹbọ mìíràn, ṣugbọn yóo wà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, láàrin àwa pẹlu yín, ati àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn wa, pé àwa náà yóo máa sin OLUWA, a óo sì máa rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú rẹ̀. Kí àwọn ọmọ yín má baà wí fún àwọn ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú pé, ‘Ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’ Èyí ni a fi ronú pé, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀ sí wa, tabi sí àwọn ọmọ ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú, a óo lè wí pé, ẹ wo irú pẹpẹ OLUWA tí àwọn baba ńlá wá tẹ́, kì í ṣe pé wọ́n rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀, tabi ẹbọ mìíràn. Ẹ̀rí ni wọ́n fi ṣe láàrin àwa pẹlu yín. A kò jẹ́ ṣe oríkunkun sí OLUWA tabi kí á kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kí a má sì sìn ín mọ́ kí á wá tẹ́ pẹpẹ mìíràn fún ẹbọ sísun tabi ẹbọ alaafia tabi ẹbọ mìíràn, yàtọ̀ sí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa tí ó wà níwájú àgọ́ rẹ̀.” Nígbà tí Finehasi alufaa, ati àwọn olórí ìjọ eniyan, ati àwọn olórí ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu wọn, gbọ́ ohun tí àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase wí, ọ̀rọ̀ náà dùn mọ́ wọn ninu. Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa dá wọn lóhùn, ó ní, “Lónìí a mọ̀ pé OLUWA ń bẹ ní ààrin wa, nítorí pé ẹ kò hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí OLUWA, ẹ sì ti gba eniyan Israẹli lọ́wọ́ ìjìyà OLUWA.” Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa, ati àwọn olórí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ní ilẹ̀ Gileadi; wọ́n pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì jíṣẹ́ fún wọn.

Joṣ 22:10-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí wọ́n wá dé Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jordani. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi àti ìlàjì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ kan dojúkọ ilẹ̀ Kenaani ní Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ìhà kejì àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo àjọ Israẹli péjọ ní Ṣilo láti lọ bá wọn jagun. Àwọn ọmọ Israẹli rán Finehasi ọmọ Eleasari àlùfáà, sí ilẹ̀ Gileadi, sí Reubeni, sí Gadi àti sí ìdajì ẹ̀yà Manase. Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan tiwọn jẹ́ olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí wọ́n lọ sí Gileadi—sí Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase—wọ́n sì sọ fún wọn pé, “Gbogbo àjọ ènìyàn OLúWA wí pe: ‘A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Israẹli nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìṣọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí OLúWA? Ẹ̀ṣẹ̀ Peori kò ha tó fún wa bí? Títí di òní yìí àwa kò tí ì wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-ààrùn ti jà láàrín ènìyàn OLúWA! Ṣé ẹ tún wá ń padà kúrò lẹ́yìn OLúWA ni báyìí? “ ‘Tí ẹ̀yin bá ṣọ̀tẹ̀ sí OLúWA ní òní, ní ọ̀la ní òun o bínú sí gbogbo ìpéjọpọ̀ Israẹli. Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní OLúWA, ní ibi tí àgọ́ OLúWA dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí OLúWA tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ OLúWA Ọlọ́run wa. Nígbà tí Akani ọmọ Sera ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Israẹli nítorí rẹ̀ bí? Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀.’ ” Nígbà náà ni Reubeni, Gadi àti ẹ̀yà Manase sọ nínú ìdáhùn wọn fún àwọn olórí Israẹli pé. OLúWA Ọlọ́run àwọn ọlọ́run! OLúWA Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Òun mọ̀, jẹ́ kí Israẹli pẹ̀lú kí ó mọ̀! Bí èyí bá wà ní ìṣọ̀tẹ̀ tàbí àìgbọ́ràn sí OLúWA, ẹ má ṣe gbà wa ní òní yìí. Bí àwa bá ti mọ pẹpẹ wa láti yí padà kúrò ní ọ̀dọ̀ OLúWA àti láti rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ jíjẹ, tàbí ẹbọ àlàáfíà ní orí rẹ, kí OLúWA fún ara rẹ̀ gba ẹ̀san. “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Àwa ṣe èyí ní ìbẹ̀rù pé ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ yín yóò wí fún wa pé, ‘Kí ni ẹ̀yin ní ṣe pẹ̀lú OLúWA, Ọlọ́run Israẹli? OLúWA ti fi Jordani ṣe ààlà láàrín àwa àti ẹ̀yin—àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi! Ẹ kò ni ní ìpín nínú OLúWA.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ yín lè mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun láti máa bẹ̀rù OLúWA. “Nítorí èyí ni àwa ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí àwa múra láti mọ pẹpẹ kan, Ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ẹbọ sísun, tàbí fún àwọn ìrúbọ.’ Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàrín àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún OLúWA ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti OLúWA.’ “Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé: Ẹ wo àpẹẹrẹ pẹpẹ OLúWA, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ẹbọ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrín àwa àti ẹ̀yin.’ “Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí àwa kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí OLúWA, kí àwa sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ ní òní nípa mímọ pẹpẹ ẹbọ sísun, ọrẹ oúnjẹ jíjẹ àti ẹbọ lẹ́yìn pẹpẹ OLúWA Ọlọ́run wa tí ó dúró níwájú àgọ́ rẹ̀.” Nígbà tí Finehasi àlùfáà àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn, àwọn olórí ìdílé Israẹli gbọ́ ohun tí Reubeni, Gadi àti Manase ti sọ, ó dùn mọ́ wọn. Finehasi ọmọ Eleasari, àlùfáà wí fún Reubeni, Gadi àti Manase pé, “Ní òní ni àwa mọ̀ pé OLúWA wà pẹ̀lú wa, nítorí tí ẹ̀yin kò hùwà àìṣòótọ́ sí OLúWA ní orí ọ̀rọ̀ yí nísinsin yìí, ẹ̀yin ti yọ àwọn ará Israẹli kúrò ní ọwọ́ OLúWA”. Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari àlùfáà àti àwọn olórí padà sí Kenaani láti ibi ìpàdé wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Reubeni àti ẹ̀yà Gadi ní Gileadi, wọ́n sì mú ìròyìn tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ.