Joṣ 22:1-5
Joṣ 22:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Joṣua pè awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ṣe gbogbo eyiti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin, ẹnyin si gbọ́ ohùn mi ni gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun nyin: Ẹnyin kò fi awọn arakunrin nyin silẹ lati ọjọ́ pipọ̀ wọnyi wá titi o fi di oni, ṣugbọn ẹnyin ṣe afiyesi ìlo ofin OLUWA Ọlọrun nyin. Njẹ nisisiyi OLUWA Ọlọrun nyin ti fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: njẹ nisisiyi ẹ pada, ki ẹ si lọ sinu agọ́ nyin, ati si ilẹ-iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA ti fun nyin ni ìha keji Jordani. Kìki ki ẹ kiyesara gidigidi lati pa aṣẹ ati ofin mọ́, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin, lati fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma rìn ni gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati lati faramọ́ ọ, ati lati sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo.
Joṣ 22:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, Joṣua pe àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ohun tí Mose, iranṣẹ OLUWA pa láṣẹ fun yín ni ẹ ti ṣe; ẹ sì ti ṣe gbogbo ohun tí èmi náà pa láṣẹ fun yín. Ẹ kò kọ àwọn arakunrin yín sílẹ̀ láti ọjọ́ yìí wá títí di òní, ṣugbọn ẹ fara balẹ̀, ẹ sì ti ń pa gbogbo àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín mọ́. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn; nítorí náà, ẹ pada lọ sí ilẹ̀ yín, níbi tí ohun ìní yín wà, àní ilẹ̀ tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín ní òdìkejì odò Jọdani. Ẹ máa ranti lemọ́lemọ́ láti máa pa gbogbo òfin tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín mọ́, pé kí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, ẹ máa pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ súnmọ́ ọn, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn.”
Joṣ 22:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Joṣua sì pe àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe gbogbo èyí tí Mose ìránṣẹ́ OLúWA pàṣẹ, ẹ sì ti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ. Ẹ kò fi àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ láti ìgbà yí títí di òní, ṣùgbọ́n ẹ ti kíyèsára láti pa òfin OLúWA Ọlọ́run yín mọ́. Nísinsin yìí tí OLúWA Ọlọ́run yín ti fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, ẹ padà sí ilẹ̀ yín níbi tí Mose ìránṣẹ́ OLúWA fi fún yin ní òdìkejì Jordani. Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mose ìránṣẹ́ OLúWA fi fún yin mọ́. Láti fẹ́ràn OLúWA Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, láti dìímú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín.”