Joṣ 10:16-43

Joṣ 10:16-43 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn awọn ọba marun nì sá, nwọn si fara wọn pamọ́ ni ihò kan ni Makkeda. A si sọ fun Joṣua pe, A ri awọn ọba marun ni ifarapamọ́ ni ihò ni Makkeda. Joṣua si wipe, Ẹ yí okuta nla di ẹnu ihò na, ki ẹ si yàn enia sibẹ̀ lati ṣọ́ wọn: Ṣugbọn ẹnyin, ẹ má ṣe duro, ẹ lepa awọn ọtá nyin, ki ẹ si kọlù wọn lẹhin; ẹ máṣe jẹ ki nwọn ki o wọ̀ ilu wọn lọ: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi wọn lé nyin lọwọ. O si ṣe, nigbati Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa wọn ni ipakupa tán, titi a fi run wọn, ti awọn ti o kù ninu wọn wọ̀ inu ilu olodi lọ, Gbogbo enia si pada si ibudó sọdọ Joṣua ni Makkeda li alafia: kò sí ẹni kan ti o yọ ahọn rẹ̀ si awọn ọmọ Israeli. Nigbana ni Joṣua wipe, Ẹ ṣi ẹnu ihò na, ki ẹ si mú awọn ọba mararun na jade kuro ninu ihò tọ̀ mi wá. Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mú awọn ọba mararun nì jade lati inu ihò na tọ̀ ọ wá, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni. O si ṣe, nigbati nwọn mú awọn ọba na tọ̀ Joṣua wá, ni Joṣua pè gbogbo awọn ọkunrin Israeli, o si wi fun awọn olori awọn ọmọ-ogun ti o bá a lọ pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ si fi ẹsẹ̀ nyin lé ọrùn awọn ọba wọnyi. Nwọn si sunmọ wọn, nwọn si gbé ẹsẹ̀ wọn lé wọn li ọrùn. Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ má ṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya; ẹ ṣe giri, ki ẹ si mu àiya le: nitoripe bayi li OLUWA yio ṣe si awọn ọtá nyin gbogbo ti ẹnyin mbájà. Lẹhin na ni Joṣua si kọlù wọn, o si pa wọn, o si so wọn rọ̀ lori igi marun: nwọn si sorọ̀ lori igi titi di aṣalẹ. O si ṣe li akokò ìwọ-õrùn, Joṣua paṣẹ, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ kuro lori igi, nwọn si gbé wọn sọ sinu ihò na ninu eyiti nwọn ti sapamọ́ si, nwọn si fi okuta nla di ẹnu ihò na, ti o wà titi di oni-oloni. Li ọjọ́ na ni Joṣua kó Makkeda, o si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀; o pa wọn run patapata, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, kò kù ẹnikan silẹ: o si ṣe si ọba Makkeda gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko. Joṣua si kọja lati Makkeda lọ si Libna, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si fi ijà fun Libna: OLUWA si fi i lé Israeli lọwọ pẹlu, ati ọba rẹ̀: o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù ẹnikan ninu rẹ̀; o si ṣe si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko. Joṣua si kọja lati Libna lọ si Lakiṣi, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si dótì i, o si fi ìja fun u. OLUWA si fi Lakiṣi lé Israeli lọwọ, o si kó o ni ijọ́ keji, o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Libna. Nigbana ni Horamu ọba Geseri gòke lati ràn Lakiṣi lọwọ; Joṣua si kọlù u ati awọn enia rẹ̀, tobẹ̃ ti kò fi kù ẹnikan silẹ fun u. Lati Lakiṣi Joṣua kọja lọ si Egloni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si dótì i, nwọn si fi ijà fun u; Nwọn si kó o li ọjọ́ na, nwọn si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ li o parun patapata li ọjọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Lakiṣi. Joṣua si gòke lati Egloni lọ si Hebroni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si fi ijà fun u: Nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù enikan silẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Egloni; o si pa a run patapata, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀. Joṣua si pada lọ si Debiri, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; o si fi ijà fun u: O si kó o, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀; nwọn si fi oju idà kọlù wọn; nwọn si pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ run patapata; kò si kù ẹnikan silẹ: gẹgẹ bi o ti ṣe si Hebroni, bẹ̃li o ṣe si Debiri, ati ọba rẹ̀; ati gẹgẹ bi o ti ṣe si Libna, ati ọba rẹ̀. Bẹ̃ni Joṣua kọlù gbogbo ilẹ, ilẹ òke, ati ti Gusù, ati ti pẹtẹlẹ̀, ati ti ẹsẹ̀-òke, ati awọn ọba wọn gbogbo; kò kù ẹnikan silẹ: ṣugbọn o pa ohun gbogbo ti nmí run patapata, gẹgẹ bi OLUWA, Ọlọrun Israeli, ti pa a laṣẹ. Joṣua si kọlù wọn lati Kadeṣi-barnea lọ titi dé Gasa, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ani titi dé Gibeoni. Ati gbogbo awọn ọba wọnyi ati ilẹ wọn, ni Joṣua kó ni ìgba kanna, nitoriti OLUWA, Ọlọrun Israeli, jà fun Israeli. Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.

Joṣ 10:16-43 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọba maraarun sá, wọ́n sì fi ara pamọ́ sinu ihò tí ó wà ní Makeda. Àwọn kan wá sọ fún Joṣua pé wọ́n ti rí àwọn ọba maraarun ní ibi tí wọ́n fi ara pamọ́ sí ní Makeda. Joṣua dá wọn lóhùn pé, “Ẹ yí òkúta ńláńlá dí ẹnu ihò náà kí ẹ sì fi àwọn eniyan sibẹ, láti máa ṣọ́ wọn. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ dúró níbẹ̀, ẹ máa lé àwọn ọ̀tá yín lọ, kí ẹ máa pa wọ́n láti ẹ̀yìn. Ẹ má jẹ́ kí wọ́n pada wọnú ìlú wọn, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ti fi wọ́n le yín lọ́wọ́.” Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ti pa wọ́n ní ìpakúpa tán, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ pa gbogbo wọn run, tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù sì ti sá wọ àwọn ìlú olódi wọn lọ tán, gbogbo àwọn eniyan pada sọ́dọ̀ Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Makeda láìsí ewu. Kò sì sí ẹni tí ó sọ ìsọkúsọ sí àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn náà, Joṣua ní, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì kó àwọn ọba maraarun náà wá fún mi.” Wọ́n bá kó wọn jáde, láti inú ihò: ọba Jerusalẹmu, ọba Heburoni, ọba Jarimutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egiloni. Nígbà tí wọ́n kó àwọn ọba náà dé ọ̀dọ̀ Joṣua, ó pe gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli jọ, ó sọ fún àwọn ọ̀gágun tí wọ́n bá a lọ sí ojú ogun pé, “Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín tẹ ọrùn àwọn ọba wọnyi.” Wọ́n bá súnmọ́ Joṣua, wọ́n sì tẹ àwọn ọba náà lọ́rùn mọ́lẹ̀. Joṣua bá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà yín já. Ẹ múra, kí ẹ sì ṣe ọkàn gírí, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀ ń bá jà.” Lẹ́yìn náà, Joṣua fi idà pa wọ́n, ó so wọ́n kọ́ orí igi marun-un, wọ́n sì wà lórí àwọn igi náà títí di ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọ́n já òkú wọn lulẹ̀ kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu ihò tí wọ́n sápamọ́ sí, wọ́n sì yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà. Ó wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Joṣua gba ìlú Makeda, ó sì fi idà pa àwọn eniyan inú rẹ̀ ati ọba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni ó parun, kò dá ẹnikẹ́ni sí. Bí ó ti ṣe sí ọba Jẹriko náà ló ṣe sí ọba Makeda. Joṣua gbéra ní Makeda, ó kọjá lọ sí Libina pẹlu gbogbo Israẹli láti gbógun ti Libina. OLUWA sì fi ìlú Libina ati ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n fi idà pa wọ́n, wọn kò ṣẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu wọn. Bí ó ti ṣe ọba Jẹriko, náà ló ṣe sí ọba ìlú náà. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra láti Libina lọ sí Lakiṣi. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì bá a jagun. OLUWA fi ìlú Lakiṣi lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì gbà á ní ọjọ́ keji. Wọ́n fi idà pa gbogbo wọn patapata bí wọ́n ti ṣe pa àwọn ará Libina. Horamu ọba Geseri wá láti ran àwọn ará ìlú Lakiṣi lọ́wọ́, Joṣua gbógun tì í, ó sì pa òun ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ láìku ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo. Joṣua kúrò ní Lakiṣi, ó lọ sí Egiloni pẹlu gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dó ti Egiloni, wọ́n sì bá a jagun. Wọ́n gba ìlú náà ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ patapata gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí àwọn ará Lakiṣi. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Egiloni lọ sí Heburoni, wọ́n sì gbógun tì í. Wọ́n gba ìlú Heburoni, wọ́n sì fi idà pa ọba ìlú náà ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ láìku ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí ìlú Egiloni tí wọn parun láìku ẹnìkan. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada sí Debiri, wọ́n sì gbógun tì í. Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n mú ọba ibẹ̀. Wọ́n gba àwọn ìlú kéékèèké agbègbè rẹ̀ pẹlu. Wọ́n fi idà pa ọba wọn ati gbogbo àwọn ará ìlú náà. Gbogbo wọn ni wọ́n pa láìku ẹnìkan. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Heburoni, ati Libina ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe sí Debiri ati ọba rẹ̀. Joṣua ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ náà, ati àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Nẹgẹbu ní apá gúsù, ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ati gbogbo àwọn ọba wọn. Kò dá ẹnikẹ́ni sí, gbogbo wọn patapata ni ó parun gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli pa fún un. Joṣua ṣẹgun gbogbo wọn láti Kadeṣi Banea títí dé Gasa ati gbogbo agbègbè Goṣeni títí dé Gibeoni. Joṣua mú gbogbo àwọn ọba wọnyi, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nítorí pé OLUWA Ọlọrun jà fún Israẹli. Lẹ́yìn náà, Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pada sí àgọ́ wọn, ní Giligali.

Joṣ 10:16-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní báyìí àwọn ọba Amori márùn-ún ti sálọ, wọ́n sì fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Makkeda, Nígbà tí wọ́n sọ fún Joṣua pé, a ti rí àwọn ọba márààrún, ti ó fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Makkeda, ó sì wí pé, “Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ. Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe dúró! Ẹ lépa àwọn ọ̀tá yín, ẹ kọlù wọ́n láti ẹ̀yìn, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó dé ìlú wọn, nítorí tí OLúWA Ọlọ́run yín tí fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ-ogun àwọn ọba márààrún run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní ibùdó ogun ní Makkeda ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Israẹli. Joṣua sì wí pe, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba márààrún jáde wá fún mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúrò nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni. Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Joṣua wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn. Joṣua sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni OLúWA yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.” Nígbà náà ni Joṣua kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba márààrún náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí oòrùn wọ̀, Joṣua pàṣẹ, wọ́n sì sọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúrò ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí. Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí. Ní ọjọ́ náà Joṣua gba Makkeda. Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátápátá, kò fi ẹnìkan sílẹ̀. Ó sì ṣe sí ọba Makkeda gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jeriko. Nígbà náà ní Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Makkeda lọ sí Libina wọ́n sì kọlù ú. OLúWA sì fi ìlú náà àti ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Ìlú náà àti gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni Joṣua fi idà pa. Kò fi ẹnìkan sílẹ̀ ní ibẹ̀: Ó sì ṣe sí ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jeriko. Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo ará Israẹli, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Libina lọ sí Lakiṣi; ó sì dó tì í, ó sì kọlù ú. OLúWA sì fi Lakiṣi lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sì gbà á ní ọjọ́ kejì. Ìlú náà àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀ ní ó fi idà pa gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Libina. Ní àkókò yìí, Horamu ọba Geseri gòkè láti ran Lakiṣi lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Joṣua ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ títí ti kò fi ku ẹnìkan sílẹ̀. Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Lakiṣi lọ sí Egloni; wọ́n sì dó tì í, wọ́n sì kọlù ú. Wọ́n gbà á ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì run gbogbo ènìyàn ibẹ̀ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Lakiṣi. Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli ṣí láti Egloni lọ sí Hebroni, wọ́n sì kọlù ú. Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n sì ti idà bọ̀ ọ́, pẹ̀lú ọba rẹ̀, gbogbo ìletò wọn àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí. Gẹ́gẹ́ bí ti Egloni, wọ́n run un pátápátá àti gbogbo ènìyàn inú rẹ̀. Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ yí padà, wọ́n sì kọlu Debiri. Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátápátá. Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí. Wọ́n ṣe sí Debiri àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Libina àti ọba rẹ̀ àti sí Hebroni. Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣẹ́gun gbogbo agbègbè náà, ìlú òkè, gúúsù, ìlú ẹsẹ̀ òkè ti ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè pẹ̀lú gbogbo ọba, wọn kò dá ẹnìkankan sí. Ó pa gbogbo ohun alààyè run pátápátá, gẹ́gẹ́ bí OLúWA Ọlọ́run Israẹli, ti pàṣẹ. Joṣua sì ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi-Barnea sí Gasa àti láti gbogbo agbègbè Goṣeni lọ sí Gibeoni. Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí àti ilẹ̀ wọn ní Joṣua ṣẹ́gun ní ìwọ́de ogun ẹ̀ẹ̀kan, nítorí tí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, jà fún Israẹli. Nígbà náà ni Joṣua padà sí ibùdó ní Gilgali pẹ̀lú gbogbo Israẹli.