Joṣ 10:12-13
Joṣ 10:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Joṣua wi fun OLUWA li ọjọ́ ti OLUWA fi awọn Amori fun awọn ọmọ Israeli, o si wi li oju Israeli pe, Iwọ, Õrùn, duro jẹ lori Gibeoni; ati Iwọ, Oṣupa, li afonifoji Aijaloni. Õrùn si duro jẹ, oṣupa si duro, titi awọn enia fi gbẹsan lara awọn ọtá wọn. A kò ha kọ eyi nã sinu iwé Jaṣeri? Bẹ̃li õrùn duro li agbedemeji ọrun, kò si yára lati wọ̀ nìwọn ọjọ́ kan tọ̀tọ.
Joṣ 10:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ tí OLUWA fi àwọn ará Amori lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, Joṣua bá OLUWA sọ̀rọ̀ lójú gbogbo Israẹli, ó ní, “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní Gibeoni. Ìwọ òṣùpá, sì dúró jẹ́ẹ́ ní àfonífojì Aijaloni.” Oòrùn bá dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró jẹ́ẹ́, títí tí àwọn ọmọ Israẹli fi gbẹ̀san tán lára àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n kọ ọ́ sinu ìwé Jaṣari pé, oòrùn dúró ní agbede meji ojú ọ̀run, kò sì tètè wọ̀ fún bí odidi ọjọ́ kan.
Joṣ 10:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ tí OLúWA fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún OLúWA níwájú àwọn ará Israẹli: “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí Àfonífojì Aijaloni.” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn náà sì dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró, títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jaṣari. Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan.