Joṣ 10:1-5
Joṣ 10:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn; Nwọn bẹ̀ru pipọ̀, nitoriti Gibeoni ṣe ilu nla, bi ọkan ninu awọn ilu ọba, ati nitoriti o tobi jù Ai lọ, ati gbogbo ọkunrin inu rẹ̀ jẹ́ alagbara. Nitorina Adoni-sedeki ọba Jerusalemu ranṣẹ si Hohamu ọba Hebroni, ati si Piramu ọba Jarmutu, ati si Jafia ọba Lakiṣi, ati si Debiri ọba Egloni, wipe, Ẹ gòke tọ̀ mi wá, ki ẹ si ràn mi lọwọ, ki awa ki o le kọlù Gibeoni: nitoriti o bá Joṣua ati awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ. Awọn ọba Amori mararun, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni, kó ara wọn jọ, nwọn si gòke, awọn ati gbogbo ogun wọn, nwọn si dótì Gibeoni, nwọn si fi ìja fun u.
Joṣ 10:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Adonisedeki, ọba Jerusalẹmu, gbọ́ bí Joṣua ṣe gba ìlú Ai, ati pé ó pa ìlú Ai ati ọba rẹ̀ run, bí ó ti ṣe sí ìlú Jẹriko ati ọba rẹ̀; ati pé àwọn ará Gibeoni ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia, wọ́n sì ń gbé ààrin wọn, ẹ̀rù bà á gidigidi, nítorí pé ìlú ńlá ni ìlú Gibeoni bí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọba aládé. Gibeoni tóbi ju ìlú Ai lọ, akọni sì ni gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀. Nítorí náà, Adonisedeki ọba Jerusalẹmu ranṣẹ sí Hohamu ọba Heburoni, Piramu ọba Jarimutu, Jafia ọba Lakiṣi ati Debiri ọba Egiloni, pé, “Ẹ wá ràn mí lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí á kọlu Gibeoni, nítorí pé ó ti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia.” Nígbà náà ni àwọn ọba Amori maraarun, ọba Jerusalẹmu, ti Heburoni, ti Jarimutu, ti Lakiṣi, ati ti Egiloni parapọ̀, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ. Wọ́n lọ dó ti Gibeoni, wọ́n sì ń bá a jagun.
Joṣ 10:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní báyìí tí Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu gbọ́ pé Joṣua ti gba Ai, tí ó sì ti pa wọ́n pátápátá; tí ó sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gibeoni ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Israẹli, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn. Ìbẹ̀rù sì mú òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ torí pé Gibeoni jẹ́ ìlú tí ó ṣe pàtàkì, bí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ọba; ó tóbi ju Ai lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ ní ó jẹ́ jagunjagun. Nítorí náà Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu bẹ Hohamu ọba Hebroni, Piramu ọba Jarmatu, Jafia ọba Lakiṣi àti Debiri ọba Egloni. Wí pe, “Ẹ gòkè wá, kí ẹ sì ràn mi lọ́wọ́ láti kọlu Gibeoni, nítorí tí ó ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Joṣua àti àwọn ará Israẹli.” Àwọn ọba Amori márààrún, ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni, kó ara wọn jọ, wọ́n sì gòkè, àwọn àti gbogbo ogun wọn, wọ́n sì dojúkọ Gibeoni, wọ́n sì kọlù ú.