Joṣ 1:5-13

Joṣ 1:5-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ki yio sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo: gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o si wà pẹlu rẹ: Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃li emi ki yio kọ̀ ọ. Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn. Sá ṣe giri ki o si mu àiya le gidigidi, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi ti palaṣẹ fun ọ: má ṣe yà kuro ninu rẹ̀ si ọtún tabi si òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ. Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ̀ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ̀: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọ̀na rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ. Emi kò ha paṣẹ fun ọ bi? Ṣe giri ki o si mu àiya le; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ ba nlọ. Nigbana ni Joṣua paṣẹ fun awọn olori awọn enia wipe, Ẹ là ãrin ibudó já, ki ẹ si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Ẹ pèse onjẹ; nitoripe ni ijọ́ mẹta oni ẹnyin o gòke Jordani yi, lati lọ gbà ilẹ ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin lati ní. Ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse, ni Joṣua wipe, Ranti ọ̀rọ ti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin pe, OLUWA Ọlọrun nyin nfun nyin ni isimi, on o si fun nyin ni ilẹ yi.

Joṣ 1:5-13 Yoruba Bible (YCE)

Kò ní sí ẹni tí yóo lè borí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí mo ti wà pẹlu Mose ni n óo wà pẹlu rẹ. N kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lae. Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, nítorí ìwọ ni o óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn, pé n óo fún wọn. Ìwọ ṣá ti múra, kí o ṣe ọkàn gírí, kí o sì rí i dájú pé o pa gbogbo òfin tí Mose, iranṣẹ mi, fún ọ mọ́. Má ṣe yẹsẹ̀ kúrò ninu rẹ̀ sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé níbikíbi tí o bá lọ lè máa yọrí sí rere. Máa ka ìwé òfin yìí nígbà gbogbo, kí o sì máa ṣe àṣàrò ninu rẹ̀, tọ̀sán-tòru; rí i dájú pé o pa gbogbo ohun tí wọ́n kọ sinu rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni yóo dára fún ọ, gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé yóo sì máa yọrí sí rere. Ranti pé mo ti pàṣẹ fún ọ pé kí o múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn rẹ, nítorí pé èmi, OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ níbikíbi tí o bá ń lọ.” Lẹ́yìn náà, Joṣua pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí àwọn eniyan náà, ó ní, “Ẹ lọ káàkiri ibùdó, kí ẹ sì pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, pé kí wọn máa pèsè oúnjẹ sílẹ̀, nítorí pé láàrin ọjọ́ mẹta wọn óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn fún wọn.” Joṣua sọ fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase pé, “Ẹ ranti àṣẹ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa fun yín pé, ‘OLUWA Ọlọrun yín ń pèsè ibi ìsinmi fun yín, yóo sì fi ilẹ̀ yìí fun yín.’

Joṣ 1:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́. “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn. Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, Má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ. Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí. Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé OLúWA à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.” Báyìí ni Joṣua pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ “Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Ẹ pèsè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jordani yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí OLúWA Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.’ ” Ṣùgbọ́n Joṣua sọ fún àwọn ará a Reubeni, àwọn ará Gadi àti fún ìdajì ẹ̀yà Manase pé, “Rántí àṣẹ tí Mose ìránṣẹ́ OLúWA pa fún yín: ‘OLúWA Ọlọ́run yín á fún yin ní ìsinmi, òun yóò sì fún un yín ní ilẹ̀ yìí.’