Joṣ 1:10-18

Joṣ 1:10-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbana ni Joṣua paṣẹ fun awọn olori awọn enia wipe, Ẹ là ãrin ibudó já, ki ẹ si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Ẹ pèse onjẹ; nitoripe ni ijọ́ mẹta oni ẹnyin o gòke Jordani yi, lati lọ gbà ilẹ ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin lati ní. Ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse, ni Joṣua wipe, Ranti ọ̀rọ ti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin pe, OLUWA Ọlọrun nyin nfun nyin ni isimi, on o si fun nyin ni ilẹ yi. Awọn obinrin nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin, ati ohunọ̀sin nyin, yio joko ni ilẹ ti Mose fi fun nyin ni ìha ihin Jordani; ṣugbọn ẹnyin o gòke lọ niwaju awọn arakunrin nyin ni ihamọra, gbogbo awọn alagbara akọni, ẹnyin o si ràn wọn lọwọ, Titi OLUWA yio fi fun awọn arakunrin nyin ni isimi, gẹgẹ bi o ti fi fun nyin, ati ti awọn pẹlu yio fi gbà ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun wọn: nigbana li ẹnyin o pada si ilẹ iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla-õrùn, ẹnyin o si ní i. Nwọn si da Joṣua lohùn, wipe, Gbogbo ohun ti iwọ palaṣẹ fun wa li awa o ṣe, ibikibi ti iwọ ba rán wa lọ, li awa o lọ. Gẹgẹ bi awa ti gbọ́ ti Mose li ohun gbogbo, bẹ̃li awa o gbọ́ tirẹ: kìki ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o wà pẹlu rẹ, gẹgẹ bi o ti wà pẹlu Mose. Ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ti o ba tapá si ofin rẹ, ti ki yio si gbọ́ ọ̀rọ rẹ li ohun gbogbo ti iwọ palaṣẹ fun u, pipa li a o pa a: kìki ki iwọ ṣe giri ki o si mu àiya le.

Joṣ 1:10-18 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, Joṣua pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí àwọn eniyan náà, ó ní, “Ẹ lọ káàkiri ibùdó, kí ẹ sì pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, pé kí wọn máa pèsè oúnjẹ sílẹ̀, nítorí pé láàrin ọjọ́ mẹta wọn óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn fún wọn.” Joṣua sọ fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase pé, “Ẹ ranti àṣẹ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa fun yín pé, ‘OLUWA Ọlọrun yín ń pèsè ibi ìsinmi fun yín, yóo sì fi ilẹ̀ yìí fun yín.’ Àwọn aya yín, àwọn ọmọ yín kéékèèké, ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín ni yóo kù lẹ́yìn lórí ilẹ̀ tí Mose fun yín ní òdìkejì odò Jọdani; ṣugbọn gbogbo àwọn akọni láàrin yín yóo rékọjá sí òdìkejì odò náà pẹlu ihamọra ogun níwájú àwọn arakunrin yín, wọn yóo máa ràn wọ́n lọ́wọ́ títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti fun yín, tí wọn yóo sì fi gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fún wọn. Nígbà náà ni ẹ óo tó pada sí orí ilẹ̀ yín, tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fun yín ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, ẹ óo sì máa gbé ibẹ̀.” Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún wa ni a óo ṣe, ibikíbi tí o bá sì rán wa ni a óo lọ. Bí a ti gbọ́ ti Mose, bẹ́ẹ̀ ni a óo máa gbọ́ tìrẹ náà. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣá ti wà pẹlu rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹlu Mose. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí àṣẹ rẹ, tí ó sì kọ̀ láti ṣe ohunkohun tí o bá sọ fún un, pípa ni a óo pa á. Ìwọ ṣá ti múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí.”

Joṣ 1:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Báyìí ni Joṣua pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ “Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Ẹ pèsè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jordani yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí OLúWA Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.’ ” Ṣùgbọ́n Joṣua sọ fún àwọn ará a Reubeni, àwọn ará Gadi àti fún ìdajì ẹ̀yà Manase pé, “Rántí àṣẹ tí Mose ìránṣẹ́ OLúWA pa fún yín: ‘OLúWA Ọlọ́run yín á fún yin ní ìsinmi, òun yóò sì fún un yín ní ilẹ̀ yìí.’ Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ẹran ọ̀sìn yín lè dúró ní ilẹ̀ tí Mose fún un yin ní ìlà-oòrùn Jordani; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn jagunjagun un yín, pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín. Ẹ̀yin yóò sì rán àwọn arákùnrin yín lọ́wọ́ títí OLúWA yóò fi fún wọn ní ìsinmi, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún un yín, àti títí tí àwọn pẹ̀lú yóò fi gba ilẹ̀ náà tí OLúWA Ọlọ́run yín fi fún wọn. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin lè padà sí ilẹ̀ ìní in yín, tí Mose ìránṣẹ́ OLúWA fi fún un yin ní agbègbè ìlà-oòrùn ti Jordani.” Nígbà náà ni wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Ohunkóhun tí ìwọ pàṣẹ fún wa ni àwa yóò ṣe, ibikíbi tí ìwọ bá rán wa ni àwa yóò lọ. Gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́rọ̀ sí Mose nínú ohun gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò máa gbọ́ tìrẹ. Kí OLúWA Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà pẹ̀lú u Mose. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí ọ̀rọ̀ rẹ, tí kò sì ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ nínú ohun gbogbo tí ìwọ yóò pàṣẹ fún wọn, pípa ni a ó pa á. Kí ìwọ sá à ṣe gírí, kí ó sì mú àyà le!”