Joṣ 1:1-5
Joṣ 1:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe lẹhin ikú Mose iranṣẹ OLUWA, li OLUWA sọ fun Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, wipe, Mose iranṣẹ mi kú; njẹ iwọ, dide, gòke Jordani yi, iwọ, ati gbogbo enia yi, si ilẹ ti mo fi fun wọn, ani fun awọn ọmọ Israeli. Ibi gbogbo ti atẹlẹsẹ̀ nyin ba tẹ̀, ẹnyin ni mo fi fun, gẹgẹ bi mo ti sọ fun Mose. Lati aginjù, ati Lebanoni yi, ani titi dé odò nla nì, odò Euferate, gbogbo ilẹ awọn Hitti, ati titi dé okun nla ni ìwọ-õrùn, eyi ni yio ṣe opin ilẹ nyin. Ki yio sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo: gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o si wà pẹlu rẹ: Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃li emi ki yio kọ̀ ọ.
Joṣ 1:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ikú Mose, iranṣẹ OLUWA, OLUWA sọ fún Joṣua, ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ Mose pé, “Mose iranṣẹ mi ti kú, nítorí náà, ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ẹ múra kí ẹ la odò Jọdani kọjá, kí ẹ sì wọ ilẹ̀ tí n óo fun yín. Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀ ni mo ti fun yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Mose. Láti inú aṣálẹ̀ ati òkè Lẹbanoni yìí lọ, títí dé odò ńlá náà, odò Yufurate, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Hiti, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn, ni yóo jẹ́ ilẹ̀ yín. Kò ní sí ẹni tí yóo lè borí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí mo ti wà pẹlu Mose ni n óo wà pẹlu rẹ. N kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lae.
Joṣ 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ OLúWA, OLúWA sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose: “Mose ìránṣẹ́ mi ti kú. Nísinsin yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹ múra láti kọjá odò Jordani lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Israẹli. Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Mose. Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti aginjù Lebanoni, àti láti odò ńlá, ti Eufurate—gbogbo orílẹ̀-èdè Hiti títí ó fi dé Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn. Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.