Jon 4:1-10

Jon 4:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)

ṢUGBỌN o bà Jona ninu jẹ́ gidigidi, o si binu pupọ̀. O si gbadura si Oluwa, o si wipe, Emi bẹ ọ, Oluwa, ọ̀rọ mi kọ yi nigbati mo wà ni ilẹ mi? nitorina ni mo ṣe salọ si Tarṣiṣi ni iṣaju: nitori emi mọ̀ pe, Ọlọrun olore-ọfẹ ni iwọ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ, o si ronupiwada ibi na. Njẹ nitorina, Oluwa, emi bẹ ọ, gbà ẹmi mi kuro lọwọ mi nitori o sàn fun mi lati kú jù ati wà lãyè. Nigbana ni Oluwa wipe, Iwọ ha ṣe rere lati binu? Jona si jade kuro ni ilu na, o si joko niha ila-õrun ilu na, o si pa agọ kan nibẹ fun ara rẹ̀, o si joko ni iboji labẹ rẹ̀, titi yio fi ri ohun ti yio ṣe ilu na. Oluwa Ọlọrun si pese itakùn kan, o si ṣe e ki o goke wá sori Jona; ki o le ṣiji bò o lori; lati gbà a kuro ninu ibinujẹ rẹ̀. Jona si yọ ayọ̀ nla nitori itakùn na. Ṣugbọn Ọlọrun pese kokorò kan nigbati ilẹ mọ́ ni ijọ keji, o si jẹ itakùn na, o si rọ. O si ṣe, nigbati õrun là, Ọlọrun si pese ẹfufu gbigbona ti ila-õrùn; õrùn si pa Jona lori, tobẹ̃ ti o rẹ̀ ẹ, o si fẹ́ ninu ara rẹ̀ lati kú, o si wipe, O sàn fun mi lati kú jù ati wà lãyè lọ. Ọlọrun si wi fun Jona pe, O ha tọ́ fun ọ lati binu nitori itakùn na? on si wipe, O tọ́ fun mi lati binu titi de ikú. Nigbana ni Oluwa wipe, Iwọ kẹdùn itakùn na nitori eyiti iwọ kò ṣiṣẹ, bẹ̃li iwọ kò mu u dagbà; ti o hù jade li oru kan ti o si kú li oru kan.

Jon 4:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn bí Ọlọrun ti ṣe yìí kò dùn mọ́ Jona ninu rárá, inú bí i. Ó bá gbadura sí OLUWA, ó ní: “OLUWA, ṣebí ohun tí mo sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ nìyí, nígbà tí mo wà ní orílẹ̀-èdè mi? Nítorí náà ni mo ṣe sa gbogbo ipá mi láti sálọ sí Taṣiṣi; nítorí mo mọ̀ pé Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ ati aláàánú ni ọ́, o ní sùúrù, o kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ò sì máa yí ibi tí o bá ti pinnu láti ṣe pada. Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gba ẹ̀mí mi, nítorí pé, ó sàn fún mi láti kú ju pé kí n wà láàyè lọ.” OLUWA bá dá Jona lóhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí o bínú?” Jona bá jáde kúrò láàrin ìlú náà, ó sì lọ jókòó sí ìhà ìlà oòrùn ìlú náà. Ó pa àtíbàbà kan sibẹ, ó jókòó ní ìbòòji lábẹ́ rẹ̀, ó ń retí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà. OLUWA bá rán ìtàkùn kan, ó fà á bo ibẹ̀, o sì ṣíji bo orí ibi tí Jona wà kí ó lè fún un ní ìtura ninu ìnira rẹ̀. Inú Jona dùn gidigidi nítorí ìtàkùn yìí. Ṣugbọn Ọlọrun rán kòkòrò kan ní àárọ̀ ọjọ́ keji, ó jẹ ìtàkùn náà, ó sì rọ. Nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn fẹ́, oòrùn sì pa Jona tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́rẹ̀ dákú. Ó sọ fún Ọlọrun pé kí ó gba ẹ̀mí òun. Ó ní, “Ó sàn kí n kú ju pé kí n wà láàyè lọ.” Ọlọrun bá bi Jona pé, “Ǹjẹ́ o lẹ́tọ̀ọ́ láti bínú nítorí ìtàkùn yìí?” Jona dáhùn, ó ní: “Ó tọ́ kí n bínú títí dé ojú ikú.” Nígbà náà ni OLUWA dá a lóhùn pé, “ìwọ ń káàánú ìtàkùn lásánlàsàn, tí o kò ṣiṣẹ́ fún, tí kì í sìí ṣe ìwọ ni o mú un dàgbà, àní ìtàkùn tí ó hù ní òru ọjọ́ kan, tí ó sì gbẹ ní ọjọ́ keji.

Jon 4:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n ó ba Jona nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀. Ó sì gbàdúrà sí OLúWA, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, OLúWA, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyí nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítorí èyí ni mo ṣé sálọ sí Tarṣiṣi ní ìṣáájú: nítorí èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà. Ǹjẹ́ báyìí, OLúWA, èmi bẹ̀ ọ, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.” Nígbà náà ni OLúWA wí pé, “Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí?” Jona sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà. Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni òjìji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà. OLúWA Ọlọ́run sì pèsè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jona; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jona sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ. Ó sì ṣe, nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jona lórí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.” Ọlọ́run sì wí fún Jona pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?” Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, o tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.” Nígbà náà ni OLúWA wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fun, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan.