Jon 1:9-16
Jon 1:9-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
On si wi fun wọn pe, Heberu li emi; mo si bẹ̀ru Oluwa, Ọlọrun ọrun, ti o dá okun ati iyangbẹ ilẹ. Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru gidigidi, nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe eyi? nitori awọn ọkunrin na mọ̀ pe o sá kuro niwaju Oluwa, nitori on ti sọ fun wọn. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kini ki a ṣe si ọ, ki okun le dakẹ fun wa? nitori okun ru, o si jà ẹfufu lile. On si wi fun wọn pe, Ẹ gbe mi, ki ẹ si sọ mi sinu okun; bẹ̃li okun yio si dakẹ fun nyin: nitori emi mọ̀ pe nitori mi ni ẹfufu lile yi ṣe de bá nyin. Ṣugbọn awọn ọkunrin na wà kikan lati mu ọkọ̀ wá si ilẹ; ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: nitori ti okun ru, o si jà ẹfufu lile si wọn. Nitorina nwọn kigbe si Oluwa nwọn si wi pe, Awa bẹ̀ ọ, Oluwa awa bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki awa ṣegbe nitori ẹmi ọkunrin yi, má si ka ẹjẹ alaiṣẹ si wa li ọrùn: nitori iwọ, Oluwa, ti ṣe bi o ti wù ọ. Bẹ̃ni nwọn gbe Jona, ti nwọn si sọ ọ sinu okun: okun si dẹkun riru rẹ̀. Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru Oluwa gidigidi, nwọn si rubọ si Oluwa, nwọn si jẹ́ ẹ̀jẹ́.
Jon 1:9-16 Yoruba Bible (YCE)
Ó bá dá wọn lóhùn pé: “Heberu ni mí, ẹ̀rù OLUWA ni ó bà mí, àní Ọlọrun ọ̀run, tí ó dá òkun ati ilẹ̀ gbígbẹ.” Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gidigidi, wọ́n sọ fún un pé, “Kí ni o dánwò yìí?” Nítorí wọ́n mọ̀ pé Jona ń sá kúrò níwájú OLUWA ni, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wọn. Wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni kí á ṣe sí ọ, kí ìjì omi òkun lè dáwọ́ dúró? Nítorí ìjì náà sá túbọ̀ ń le sí i ni.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi jù sinu òkun, ìjì náà yóo sì dáwọ́ dúró, nítorí mo mọ̀ pé nítorí mi ni òkun fi ń ru.” Sibẹsibẹ, àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gbìyànjú láti tu ọkọ̀ wọn pada sórí ilẹ̀, ṣugbọn kò ṣeéṣe, nítorí pé, afẹ́fẹ́ líle dojú kọ wọ́n, ìjì náà sì ń pọ̀ sí i. Wọ́n bá gbadura sí OLUWA, wọ́n ní, “A bẹ̀ ọ́, OLUWA, má jẹ́ kí á ṣègbé nítorí ti ọkunrin yìí, má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ yìí sí wa lọ́rùn; nítorí bí o ti fẹ́ ni ò ń ṣe.” Wọ́n bá gbé Jona jù sinu òkun, òkun sì dákẹ́rọ́rọ́. Ẹ̀rù OLUWA ba àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ lọpọlọpọ, wọ́n rúbọ, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA.
Jon 1:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òun sì dá wọn lóhùn pé, “Heberu ni èmi, mo sì bẹ̀rù OLúWA, Ọlọ́run ọ̀run ẹni tí ó dá Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀.” Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù gidigidi, wọn sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣe èyí?” (Nítorí àwọn ọkùnrin náà mọ̀ pé ó ń sá kúrò ní iwájú OLúWA ni, nítorí òun ti sọ fun wọn bẹ́ẹ̀.) Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Kí ni kí àwa ó ṣe sí ọ kí Òkun lè dákẹ́ fún wa?” Nítorí Òkun ru, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle. Òun sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mi sínú Òkun, bẹ́ẹ̀ ni okun yóò sì dákẹ́ fún un yin. Nítorí èmi mọ̀ pé, nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín.” Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú gidigidi láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀: ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí Òkun túbọ̀ ru sí i, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn. Nítorí náà wọ́n kígbe sí OLúWA, wọ́n sì wí pé, “OLúWA àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí. Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, OLúWA, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Jona, tí wọ́n sì sọ ọ́ sínú Òkun, Òkun sì dẹ́kun ríru rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù OLúWA gidigidi, wọn si rú ẹbọ sí OLúWA, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.