Jon 1:1-17

Jon 1:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jona ọmọ Amittai wá, wipe, Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kigbe si i; nitori ìwa buburu wọn goke wá iwaju mi. Ṣugbọn Jona dide lati sá lọ si Tarṣiṣi kuro niwaju Oluwa, o si sọkalẹ lọ si Joppa; o si ri ọkọ̀ kan ti nlọ si Tarṣiṣi: bẹ̃li o sanwo ọkọ, o si sọkalẹ sinu rẹ̀, lati ba wọn lọ si Tarṣiṣi lati sá kuro niwaju Oluwa. Ṣugbọn Oluwa rán ẹfufu nla jade si oju okun, ijì lile si wà ninu okun, tobẹ̃ ti ọkọ̀ na dabi ẹnipe yio fọ. Nigbana ni awọn atukọ̀ bẹ̀ru, olukuluku si kigbe si ọlọrun rẹ̀, nwọn ko ẹrù ti o wà ninu ọkọ dà sinu okun, lati mu u fẹrẹ. Ṣugbọn Jona sọkalẹ lọ si ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀; o si dubulẹ sùn wọra. Bẹ̃li olori-ọkọ̀ tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ rò, iwọ olõrun? dide, kepe Ọlọrun rẹ, boya Ọlọrun yio ro tiwa, ki awa ki o má bà ṣegbé. Olukuluku wọn si wi fun ẹgbẹ rẹ̀ pe, Wá, ẹ si jẹ ka ṣẹ keké, ki awa ki o le mọ̀ itori tani buburu yi ṣe wá sori wa. Bẹ̃ni nwọn ṣẹ keké, keké si mu Jona. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Sọ fun wa, awa bẹ̀ ọ, nitori ti tani buburu yi ṣe wá sori wa? kini iṣẹ rẹ? nibo ni iwọ si ti wá? orukọ ilu rẹ? orilẹ-ède wo ni iwọ si iṣe? On si wi fun wọn pe, Heberu li emi; mo si bẹ̀ru Oluwa, Ọlọrun ọrun, ti o dá okun ati iyangbẹ ilẹ. Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru gidigidi, nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe eyi? nitori awọn ọkunrin na mọ̀ pe o sá kuro niwaju Oluwa, nitori on ti sọ fun wọn. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kini ki a ṣe si ọ, ki okun le dakẹ fun wa? nitori okun ru, o si jà ẹfufu lile. On si wi fun wọn pe, Ẹ gbe mi, ki ẹ si sọ mi sinu okun; bẹ̃li okun yio si dakẹ fun nyin: nitori emi mọ̀ pe nitori mi ni ẹfufu lile yi ṣe de bá nyin. Ṣugbọn awọn ọkunrin na wà kikan lati mu ọkọ̀ wá si ilẹ; ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: nitori ti okun ru, o si jà ẹfufu lile si wọn. Nitorina nwọn kigbe si Oluwa nwọn si wi pe, Awa bẹ̀ ọ, Oluwa awa bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki awa ṣegbe nitori ẹmi ọkunrin yi, má si ka ẹjẹ alaiṣẹ si wa li ọrùn: nitori iwọ, Oluwa, ti ṣe bi o ti wù ọ. Bẹ̃ni nwọn gbe Jona, ti nwọn si sọ ọ sinu okun: okun si dẹkun riru rẹ̀. Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru Oluwa gidigidi, nwọn si rubọ si Oluwa, nwọn si jẹ́ ẹ̀jẹ́. Ṣugbọn Oluwa ti pese ẹja nla kan lati gbe Jona mì. Jona si wà ninu ẹja na li ọsan mẹta ati oru mẹta.

Jon 1:1-17 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA bá Jona ọmọ Amitai sọ̀rọ̀, ó ní, “Dìde, lọ sí Ninefe, ìlú ńlá nì, kéde, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé mo rí gbogbo ìwà burúkú wọn!” Ṣugbọn Jona gbéra ó fẹ́ sálọ sí Taṣiṣi, kí ó lè kúrò níwájú OLUWA. Ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jọpa, ó sì rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń lọ sí Taṣiṣi níbẹ̀. Ó san owó ọkọ̀, ó bá bọ́ sinu ọkọ̀, ó fẹ́ máa bá a lọ sí Taṣiṣi kí ó sì sá kúrò níwájú OLUWA. Ṣugbọn OLUWA gbé ìjì kan dìde lójú omi òkun, afẹ́fẹ́ náà le tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ ojú omi fẹ́rẹ̀ ya. Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa rẹ̀, wọ́n ń da ẹrù wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ sinu òkun kí ọkọ̀ lè fúyẹ́. Ṣugbọn Jona ti lọ dùbúlẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀, ó sì ti sùn lọ fọnfọn. Olórí àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí ò ń sùn, olóorun? Dìde, ké pe ọlọrun rẹ, bóyá a jẹ́ ṣàánú wa, kí á má baà ṣègbé.” Wọ́n bá dámọ̀ràn láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ gègé, kí á lè mọ ẹni tí ó fà á, tí nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa.” Wọ́n ṣẹ́ gègé, gègé bá mú Jona. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nítorí ta ni nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni o ti wá? Níbo ni orílẹ̀-èdè rẹ? Inú ẹ̀yà wo ni o sì ti wá?” Ó bá dá wọn lóhùn pé: “Heberu ni mí, ẹ̀rù OLUWA ni ó bà mí, àní Ọlọrun ọ̀run, tí ó dá òkun ati ilẹ̀ gbígbẹ.” Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gidigidi, wọ́n sọ fún un pé, “Kí ni o dánwò yìí?” Nítorí wọ́n mọ̀ pé Jona ń sá kúrò níwájú OLUWA ni, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wọn. Wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni kí á ṣe sí ọ, kí ìjì omi òkun lè dáwọ́ dúró? Nítorí ìjì náà sá túbọ̀ ń le sí i ni.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi jù sinu òkun, ìjì náà yóo sì dáwọ́ dúró, nítorí mo mọ̀ pé nítorí mi ni òkun fi ń ru.” Sibẹsibẹ, àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gbìyànjú láti tu ọkọ̀ wọn pada sórí ilẹ̀, ṣugbọn kò ṣeéṣe, nítorí pé, afẹ́fẹ́ líle dojú kọ wọ́n, ìjì náà sì ń pọ̀ sí i. Wọ́n bá gbadura sí OLUWA, wọ́n ní, “A bẹ̀ ọ́, OLUWA, má jẹ́ kí á ṣègbé nítorí ti ọkunrin yìí, má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ yìí sí wa lọ́rùn; nítorí bí o ti fẹ́ ni ò ń ṣe.” Wọ́n bá gbé Jona jù sinu òkun, òkun sì dákẹ́rọ́rọ́. Ẹ̀rù OLUWA ba àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ lọpọlọpọ, wọ́n rúbọ, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA. OLUWA bá pèsè ẹja ńlá kan tí ó gbé Jona mì. Jona sì wà ninu ẹja náà fún ọjọ́ mẹta.

Jon 1:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Jona ọmọ Amittai wá, wí pé: “Dìde lọ sí ìlú ńlá Ninefe kí o sì wàásù sí i, nítorí ìwà búburú rẹ̀ gòkè wá iwájú mi.” Ṣùgbọ́n Jona dìde kúrò láti sálọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú OLúWA, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Joppa, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tarṣiṣi: lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú OLúWA. Nígbà náà ni OLúWA rán ìjì ńlá jáde sí ojú Òkun, ìjì líle sì wà nínú Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́. Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú Òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́. Ṣùgbọ́n Jona sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra. Bẹ́ẹ̀ ni olórí ọkọ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi sùn, ìwọ olóòórùn? Dìde kí o ké pe Ọlọ́run rẹ! Bóyá yóò ro tiwa, kí àwa má ba à ṣègbé.” Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ sọ fún ara wọn pé, “Wá, ẹ jẹ́ kí a sẹ́ kèké, kí àwa kí o le mọ̀ nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa.” Wọ́n ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jona. Nígbà náà ni wọn wí fún un pé, “Sọ fún wa, àwa bẹ̀ ọ́, nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni ìwọ ti wá? Kí ni orúkọ ìlú rẹ? Ẹ̀yà orílẹ̀-èdè wo sì ni ìwọ sì í ṣe?” Òun sì dá wọn lóhùn pé, “Heberu ni èmi, mo sì bẹ̀rù OLúWA, Ọlọ́run ọ̀run ẹni tí ó dá Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀.” Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù gidigidi, wọn sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣe èyí?” (Nítorí àwọn ọkùnrin náà mọ̀ pé ó ń sá kúrò ní iwájú OLúWA ni, nítorí òun ti sọ fun wọn bẹ́ẹ̀.) Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Kí ni kí àwa ó ṣe sí ọ kí Òkun lè dákẹ́ fún wa?” Nítorí Òkun ru, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle. Òun sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mi sínú Òkun, bẹ́ẹ̀ ni okun yóò sì dákẹ́ fún un yin. Nítorí èmi mọ̀ pé, nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín.” Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú gidigidi láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀: ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí Òkun túbọ̀ ru sí i, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn. Nítorí náà wọ́n kígbe sí OLúWA, wọ́n sì wí pé, “OLúWA àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí. Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, OLúWA, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Jona, tí wọ́n sì sọ ọ́ sínú Òkun, Òkun sì dẹ́kun ríru rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù OLúWA gidigidi, wọn si rú ẹbọ sí OLúWA, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́. Ṣùgbọ́n OLúWA ti pèsè ẹja ńlá kan láti gbé Jona mì. Jona sì wà nínú ẹja náà ni ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.