Joel 2:28-32
Joel 2:28-32 Yoruba Bible (YCE)
“Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá yá, n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo eniyan, àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, àwọn àgbààgbà yín yóo máa lá àlá, àwọn ọdọmọkunrin yín yóo sì máa ríran. Bákan náà, nígbà tí àkókò bá tó, n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín. “Ìtàjẹ̀sílẹ̀ yóo pọ̀, n óo sì fi iná, ati òpó èéfín sí ojú ọ̀run, ati sórí ilẹ̀ ayé; yóo jẹ́ ìkìlọ̀ fun yín. Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo pọ́n rẹ̀bẹ̀tẹ̀ bí ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ OLUWA tí ó lẹ́rù tó dé. Ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bá ké pe orúkọ OLUWA ni a óo gbàlà. Àwọn kan yóo sá àsálà ní òkè Sioni, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, àwọn tí OLUWA pè yóo sì wà lára àwọn tí wọn yóo sá àsálà.
Joel 2:28-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Yio si ṣe, nikẹhìn emi o tú ẹmi mi jade si ara enia gbogbo; ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma ṣotẹlẹ, awọn arugbo nyin yio ma lá alá, awọn ọdọmọkunrin nyin yio ma riran: Ati pẹlu si ara awọn ọmọ-ọdọ ọkunrin, ati si ara awọn ọmọ-ọdọ obinrin, li emi o tú ẹmi mi jade li ọjọ wọnni. Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn li ọrun ati li aiye, ẹjẹ̀ ati iná, ati ọwọ̀n ẹ̃fin. A ó sọ õrùn di òkunkun, ati oṣùpá di ẹjẹ̀, ki ọjọ nla ati ẹ̀ru Oluwa to de. Yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ke pè orukọ Oluwa li a o gbàla: nitori li oke Sioni ati ni Jerusalemu ni igbàla yio gbe wà, bi Oluwa ti wi, ati ninu awọn iyokù ti Oluwa yio pè.
Joel 2:28-32 Yoruba Bible (YCE)
“Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá yá, n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo eniyan, àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, àwọn àgbààgbà yín yóo máa lá àlá, àwọn ọdọmọkunrin yín yóo sì máa ríran. Bákan náà, nígbà tí àkókò bá tó, n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín. “Ìtàjẹ̀sílẹ̀ yóo pọ̀, n óo sì fi iná, ati òpó èéfín sí ojú ọ̀run, ati sórí ilẹ̀ ayé; yóo jẹ́ ìkìlọ̀ fun yín. Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo pọ́n rẹ̀bẹ̀tẹ̀ bí ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ OLUWA tí ó lẹ́rù tó dé. Ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bá ké pe orúkọ OLUWA ni a óo gbàlà. Àwọn kan yóo sá àsálà ní òkè Sioni, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, àwọn tí OLUWA pè yóo sì wà lára àwọn tí wọn yóo sá àsálà.
Joel 2:28-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́, èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo; àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran. Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin, àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin, ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì. Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun àti ní ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín. A á sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù OLúWA tó dé. Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ OLúWA ní a ó gbàlà: nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí OLúWA ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí OLúWA yóò pè.