Job 9:15-35

Job 9:15-35 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bi o tilẹ ṣepe mo ṣe olododo, emi kò gbọdọ̀ da a lohùn, ṣugbọn emi o gbadura ẹ̀bẹ mi sọdọ onidajọ mi. Bi emi ba si kepè e, ti on si da mi lohùn, emi kì yio si gbagbọ pe, on ti feti si ohùn mi. Nitoripe o fi ẹ̀fufu nla ṣẹ mi tutu, o sọ ọgbẹ mi di pipọ lainidi. On kì yio jẹ ki emi ki o fà ẹmi mi, ṣugbọn o fi ohun kikorò kún u fun mi. Bi mo ba sọ ti agbara, wò o! alagbara ni, tabi niti idajọ, tani yio da akoko fun mi lati rò? Bi mo tilẹ da ara mi lare, ẹnu ara mi ni yio dá mi lẹbi; bi mo wipe, olododo li emi, yio si fi mi hàn ni ẹni-òdi. Olõtọ ni mo ṣe, sibẹ emi kò kiyesi ẹmi mi, ìwa mi li emi iba ma gàn. Ohun kanna ni, nitorina ni emi ṣe sọ ọ: on a pa ẹni-otitọ ati enia buburu pẹlu. Bi jamba ba pa ni lojijì, yio rẹrin idanwo alaiṣẹ̀. A fi aiye le ọwọ enia buburu; o si bò awọn onidajọ rẹ̀ li oju; bi kò ba ri bẹ̃, njẹ tani? Njẹ nisisiyi ọjọ mi yara jù onṣẹ lọ, nwọn fò lọ, nwọn kò ri ire. Nwọn kọja lọ bi ọkọ-ẽsú ti nsure lọ; bi idì ti o nyara si ohun ọdẹ. Bi emi ba wipe, emi o gbagbe aro ibinujẹ mi, emi o fi ọkàn lelẹ̀, emi o si rẹ̀ ara mi lẹkun. Ẹ̀ru ibinujẹ mi gbogbo bà mi, emi mọ̀ pe iwọ kì yio mu mi bi alaiṣẹ̀. Bi o ba ṣepe enia buburu li emi, njẹ kili emi nṣe lãlã lasan si! Bi mo tilẹ fi omi òjo didì wẹ̀ ara mi, ti mo fi omi-aró wẹ̀ ọwọ mi mọ́, Sibẹ iwọ o gbe mi bọ̀ inu ihò ọ̀gọdọ, aṣọ ara mi yio sọ mi di ẹni-irira. Nitori on kì iṣe enia bi emi, ti emi o fi da a lohùn ti awa o fi pade ni idajọ. Bẹ̃ni kò si alatunṣe kan lagbedemeji wa, ti iba fi ọwọ rẹ̀ le awa mejeji lara. Ki on sa mu ọ̀pa rẹ̀ kuro lara mi, ki ìbẹru rẹ̀ ki o má si ṣe daiya fò mi. Nigbana ni emi iba sọ̀rọ, emi kì ba si bẹ̀ru rẹ̀; ṣugbọn kò ri bẹ̃ fun mi.

Job 9:15-35 Yoruba Bible (YCE)

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn. Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú, lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí. Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́, tí ó sì dá mi lóhùn, sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi. Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀, ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí; kò ní jẹ́ kí n mí, ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi. Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni, agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ! Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́, ta ló lè pè é lẹ́jọ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ ọ̀rọ̀ ẹnu mi yóo di ẹ̀bi rù mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́ṣẹ̀, sibẹsibẹ yóo fihàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí. N kò lẹ́bi, sibẹ n kò ka ara mi kún, ayé sú mi. Kò sí ìyàtọ̀ lójú rẹ̀, nítorí náà ni mo fi wí pé, ati ẹlẹ́bi ati aláìlẹ́bi ni ó ti parun. Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀, tí ó já sí ikú òjijì, a máa fi aláìṣẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà ninu ìdààmú wọn. A ti fi ayé lé àwọn ẹni ibi lọ́wọ́, ó ti di àwọn adájọ́ rẹ̀ lójú. Bí kì í bá ṣe òun Ọlọrun, ta ló tún tó bẹ́ẹ̀? “Ọjọ́ ayé mi ń sáré lọ tete, kò sí ẹyọ ọjọ́ kan tí ó dára ninu wọn. Wọ́n sáré kọjá lọ bíi koríko ojú omi, bí ẹyẹ idì tí ń fò fẹ̀ẹ̀ lọ bá ohun tí ó fẹ́ pa. Bí mo bá sọ pé kí n gbàgbé ìráhùn mi, kí n sì tújúká; kí n má ronú mọ́; ẹ̀rù ìrora mi á bẹ̀rẹ̀ sí bà mí, nítorí mo mọ̀ pé o kò ní gbà pé n kò dẹ́ṣẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá mi lẹ́bi, kí ni mo tún ń ṣe wahala lásán fún? Ọṣẹ yòówù tí mo lè fi wẹ̀, kódà kí n fi omi yìnyín fọ ọwọ́, sibẹ o óo tì mí sinu kòtò ìdọ̀tí. Kódà n óo di ohun ìríra sí aṣọ ara mi. Ọlọrun kì í ṣe eniyan bíì mi, tí mo fi lè fún un lésì, tí a fi lè jọ rojọ́ ní ilé ẹjọ́. Kò sí ẹnìkẹta láàrin àwa mejeeji, tí ó lè dá wa lẹ́kun. Kí ó sọ pàṣán rẹ̀ sílẹ̀, kí ó má nà mí mọ́! Kí ìbẹ̀rù rẹ̀ má sì pá mi láyà mọ́! Kí n baà le sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù, nítorí mo mọ inú ara mi.

Job 9:15-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn; ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú. Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi. Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá, ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí. Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi. Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó! Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò? Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi; bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi. “Olóòótọ́ ni mo ṣe, síbẹ̀ èmi kò kíyèsi ara mi, ayé mi ní èmi ìbá máa gàn. Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ: ‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’ Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì, yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀. Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú; ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú; bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni? “Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ, wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀. Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ; bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ. Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi, èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’ Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí, èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi, ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí? Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ dídì wẹ ara mi, tí mo fi omi aró wẹ ọwọ́ mi mọ́, síbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra. “Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi, tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára. Kí ẹnìkan sá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi, kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì ṣe dáyà fò mí Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀; ṣùgbọ́n bí ó tí dúró tì mí, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.