Job 8:1-7
Job 8:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe, Iwọ o ti ma sọ nkan wọnyi pẹ to? ti ọ̀rọ ẹnu rẹ yio si ma dabi ẹfufu nla? Ọlọrun a ha ma yi idajọ po bi, tabi Olodumare a ma fi otitọ ṣẹ̀ bi? Nigbati awọn ọmọ rẹ ṣẹ̀ si i, o si gbá wọn kuro nitori irekọja wọn. Bi iwọ ba si kepe Ọlọrun ni igba akokò, ti iwọ bá si gbadura ẹ̀bẹ si Olodumare. Iwọ iba mọ́, ki o si duro ṣinṣin: njẹ nitõtọ nisisiyi on o tají fun ọ, on a si sọ ibujoko ododo rẹ di pipọ. Ipilẹṣẹ rẹ iba tilẹ kere ri, bẹ̃ni igbẹhin rẹ iba pọ̀ si i gidigidi.
Job 8:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Bilidadi ará Ṣuha dáhùn pé, “O óo ti sọ irú ọ̀rọ̀ wọnyi pẹ́ tó, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ yóo sì dàbí afẹ́fẹ́ líle? Ṣé Ọlọrun a máa yí ìdájọ́ po? Ṣé Olodumare a máa yí òdodo pada? Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ dẹ́ṣẹ̀ ni, ó ti jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣugbọn bí o bá wá Ọlọrun, tí o sì sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Olodumare; tí o bá jẹ́ ẹni mímọ́ ati olóòótọ́, dájúdájú OLUWA yóo dìde, yóo ràn ọ́ lọ́wọ́, yóo sì fi ibùgbé rere san ẹ̀san fún ọ. Díẹ̀ ni ọrọ̀ tí o ní tẹ́lẹ̀ yóo jẹ́ lára ohun tí Ọlọrun yóo fún ọ ní ọjọ́ iwájú.
Job 8:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, sì dáhùn wí pé: “Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó? Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá? Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí? Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre? Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i, ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn. Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò, tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè. Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin: ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ, òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀. Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í, bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.