Job 40:6-9
Job 40:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe: Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́. Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo? Iwọ ni apá bi Ọlọrun, tabi iwọ le ifi ohùn san ãrá bi on?
Job 40:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní, “Múra gírí bí ọkunrin, mo ní ìbéèrè láti bi ọ́, o óo sì dá mi lóhùn. Ṣé o fẹ́ sọ pé mò ń ṣe àìdára ni? O fẹ́ dá mi lẹ́bi kí á lè dá ọ láre? Ṣé o lágbára bí èmi Ọlọrun, àbí o lè sán wàá bí ààrá, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀?
Job 40:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ní OLúWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé: “Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin, èmi ó bi ọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn. “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán? Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?