Job 38:1-18

Job 38:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe, Tani eyi ti nfi ọ̀rọ aini igbiro ṣú ìmọ li òkunkun. Di ẹgbẹ ara rẹ li amure bi ọkunrin nisisiyi, nitoripe emi o bère lọwọ rẹ ki o si da mi lohùn. Nibo ni iwọ wà nigbati mo fi ipilẹ aiye sọlẹ? wi bi iwọ ba moye! Tali o fi ìwọn rẹ̀ lelẹ, bi iwọ ba mọ̀, tabi tani o ta okun wiwọn sori rẹ̀. Lori ibo ni a gbe kan ipilẹ rẹ̀ mọ́, tabi tali o fi okuta igun rẹ̀ le ilẹ? Nigbati awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nhó iho ayọ̀? Tabi tali o fi ilẹkun sé omi okun mọ́, nigbati o ya jade bi ẹnipe o ti inu tu jade wá? Nigbati mo fi awọsanma ṣe aṣọ rẹ̀, ati òkunkun ṣiṣu ṣe ọ̀ja igbanu rẹ̀? Ti mo ti paṣẹ ipinnu mi fun u, ti mo si ṣe bèbe ati ilẹkun. Ti mo si wipe, Nihinyi ni iwọ o dé, ki o má si rekọja, nihinyi si ni igberaga riru omi rẹ yio gbe duro mọ. Iwọ paṣẹ fun owurọ lati igba ọjọ rẹ̀ wá, iwọ si mu ila-õrun mọ̀ ipo rẹ̀? Ki o le idi opin ilẹ aiye mu, ki a le gbọ̀n awọn enia buburu kuro ninu rẹ̀. Ki o yipada bi amọ fun edidi amọ, ki gbogbo rẹ̀ ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ẹnipe ninu aṣọ igunwa. A si fa imọlẹ wọn sẹhin kuro lọdọ enia buburu, apa giga li o si ṣẹ́. Iwọ ha wọ inu isun okun lọ ri bi? iwọ si rin lori isalẹ ibú nla? A ha ṣilẹkun ikú silẹ fun ọ ri bi, iwọ si ri ilẹkun ojiji ikú? Iwọ̀ moye ibú aiye bi? sọ bi iwọ ba mọ̀ gbogbo rẹ̀?

Job 38:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà náà ni OLUWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì líle. Ó bi í pé, “Ta ni ẹni tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìmọ̀ràn, tí ń sọ̀rọ̀ tí kò ní ìmọ̀? Nisinsinyii, múra gírí bí ọkunrin, mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ, o óo sì dá mi lóhùn. Níbo lo wà, nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Bí o bá mọ ìgbà náà, sọ fún mi. Ta ló ṣe ìdíwọ̀n rẹ̀– ṣebí o mọ̀ ọ́n, dá mi lóhùn! Àbí ta ló ta okùn ìwọ̀n sórí rẹ̀? Orí kí ni a gbé ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé, àbí ta ló fi òkúta igun rẹ̀ sọlẹ̀; tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ ń jùmọ̀ kọrin, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun sì búsáyọ̀? Ta ló tìlẹ̀kùn mọ́ òkun, nígbà tí ó ń ru jáde, tí mo fi awọsanma ṣe ẹ̀wù rẹ̀, tí òkùnkùn biribiri sì jẹ́ ọ̀já ìgbànú rẹ̀, tí mo sì pa ààlà fún un, tí mo sé ìlẹ̀kùn mọ́ ọn, tí mo wí pé, ‘Dúró níhìn-ín, o kò gbọdọ̀ kọjá ibẹ̀, ibí ni ìgbì líle rẹ ti gbọdọ̀ dáwọ́ dúró?’ Jobu, láti ọjọ́ tí o ti dé ayé, ǹjẹ́ o ti pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mọ́ rí, tabi pé kí àfẹ̀mọ́jú mọ́ àkókò rẹ̀, kí ìmọ́lẹ̀ lè tàn sí gbogbo ayé, kí ó sì lè gbọn àwọn ẹni ibi dànù, kúrò ní ibi ìsápamọ́sí wọn? A ti yí ayé pada bí amọ̀ tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀, ati bí aṣọ tí a pa láró. A mú ìmọ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹni ibi, a sì ká wọn lápá kò. “Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí, tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí? Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí, tabi o ti rí ìlẹ̀kùn òkùnkùn biribiri rí? Ṣé o mọ̀ bí ayé ti tóbi tó? Dá mi lóhùn, bí o bá mọ àwọn nǹkan wọnyi.

Job 38:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ní OLúWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé: “Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi? Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dá mi lóhùn. “Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye. Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ? Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀, Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀? “Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi Òkun mọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá, Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀, Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un, tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn, Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ? “Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbà ọjọ́ rẹ̀ wá, ìwọ sì mú ìlà-oòrùn mọ ipò rẹ̀, Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lè gbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀? Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdì amọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà. A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga ni a sì ṣẹ́. “Ìwọ ha wọ inú ìsun Òkun lọ rí bí? Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá? A ha ṣílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí, ìwọ sì rí ìlẹ̀kùn òjìji òkú? Ìwọ mòye ìbú ayé bí? Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí.