Job 32:6-9
Job 32:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, dahùn o si wipe, Ọmọde li emi, àgba si li ẹnyin; njẹ nitorina ni mo duro, mo si mbẹ̀ru lati fi ìmọ mi hàn nyin. Emi wipe, ọjọ-jọjọ ni iba sọ̀rọ, ati ọ̀pọlọpọ ọdun ni iba ma kọ́ni li ọgbọ́n. Ṣugbọn ẹmi kan ni o wà ninu enia, ati imisi Olodumare ni isi ma fun wọn li oye. Enia nlanla kì iṣe ọlọgbọ́n, bẹ̃ni awọn àgba li oye idajọ kò ye.
Job 32:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní, “Àgbàlagbà ni yín, ọmọde sì ni mí, nítorí náà ni ojú fi ń tì mí, tí ẹ̀rù sì ń bà mí láti sọ èrò ọkàn mi. Mo ní kí ẹ̀yin àgbà sọ̀rọ̀, kí ọ̀rọ̀ yín sì fa ọgbọ́n yọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí yín. Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu eniyan, tíí ṣe èémí Olodumare, ni ó ń fún eniyan ní ìmọ̀. Kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ni wọ́n gbọ́n, tabi pé arúgbó nìkan ni ó mọ òye ohun tó tọ́, tó yẹ.
Job 32:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, dáhùn ó sì wí pé: “Ọmọdé ni èmi, àgbà sì ní ẹ̀yin; ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró, mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin. Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n. Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye. Ènìyàn ńláńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n, Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.