Job 2:7-10
Job 2:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa, o si sọ Jobu li õwo kikankikan lati atẹlẹsẹ rẹ̀ lọ de atari rẹ̀. O si mu apadì o fi nhá ara rẹ̀, o si joko ninu ẽru. Nigbana ni aya rẹ̀ wi fun u pe, iwọ di ìwa otitọ rẹ mu sibẹ! bu Ọlọrun, ki o si kú. Ṣugbọn on da a lohùn pe, iwọ sọ̀rọ bi ọkan ninu awọn obinrin alaimoye ti isọ̀rọ; kinla! awa o ha gba ire lọwọ Ọlọrun, ki a má si gba ibi! Ninu gbogbo eyi Jobu kò fi ète rẹ̀ ṣẹ̀.
Job 2:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Satani bá lọ kúrò níwájú OLUWA, ó sì da oówo bo Jobu lára, láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé orí. Jobu ń fi àpáàdì họ ara, ó sì jókòó sinu eérú. Iyawo Jobu bá sọ fún un pé, “Orí òtítọ́ inú rẹ ni o tún wà sibẹ? Fi Ọlọrun bú, kí o kú.” Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Ò ń sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí ọ̀kan ninu àwọn aláìmòye obinrin bá ń sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ eniyan lè gba ire lọ́wọ́ Ọlọrun kí ó má gba ibi?” Ninu gbogbo nǹkan wọnyi, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀ rárá ninu ọ̀rọ̀ tí ó sọ.
Job 2:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú OLúWA, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú. Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!” Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn aṣiwèrè obìnrin ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ìre lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?” Nínú gbogbo èyí, Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.