Job 2:4-6
Job 2:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Satani si dá Oluwa lohùn wipe, awọ fun awọ; ani ohun gbogbo ti enia ni, on ni yio fi rà ẹmi rẹ̀. Ṣugbọn nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ egungun rẹ̀ ati ara rẹ̀, bi kì yio si bọhùn li oju rẹ. Oluwa si wi fun Satani pe, Wõ, o mbẹ ni ikawọ rẹ, ṣugbọn dá ẹmi rẹ̀ si.
Job 2:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Ohun gbogbo ni eniyan lè fi sílẹ̀ láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Ìwọ fi ọwọ́ kan ara ati eegun rẹ̀ wò, bí kò bá ní sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.” OLUWA bá ní, “Ó wà ní ìkáwọ́ rẹ, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹ̀mí rẹ̀.”
Job 2:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Satani sì dá OLúWA lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀. Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.” OLúWA sì wí fún Satani pé, “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.”