Job 2:1-10

Job 2:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ó tún yá tí àwọn ọmọ Ọlọrun wá farahàn níwájú OLUWA, Satani náà wà láàrin wọn. OLUWA tún bi Satani pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?” Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Mò ń lọ sókè sódò káàkiri gbogbo ayé.” Ọlọrun tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé. Ó bẹ̀rù OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú, ó dúró ṣinṣin ninu ìwà òtítọ́ rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o dẹ mí sí i láti pa á run láìnídìí.” Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Ohun gbogbo ni eniyan lè fi sílẹ̀ láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Ìwọ fi ọwọ́ kan ara ati eegun rẹ̀ wò, bí kò bá ní sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.” OLUWA bá ní, “Ó wà ní ìkáwọ́ rẹ, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹ̀mí rẹ̀.” Satani bá lọ kúrò níwájú OLUWA, ó sì da oówo bo Jobu lára, láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé orí. Jobu ń fi àpáàdì họ ara, ó sì jókòó sinu eérú. Iyawo Jobu bá sọ fún un pé, “Orí òtítọ́ inú rẹ ni o tún wà sibẹ? Fi Ọlọrun bú, kí o kú.” Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Ò ń sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí ọ̀kan ninu àwọn aláìmòye obinrin bá ń sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ eniyan lè gba ire lọ́wọ́ Ọlọrun kí ó má gba ibi?” Ninu gbogbo nǹkan wọnyi, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀ rárá ninu ọ̀rọ̀ tí ó sọ.

Job 2:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì tún di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá síwájú OLúWA, Satani sì wá pẹ̀lú wọn láti pe níwájú OLúWA. OLúWA sì bi Satani pé, Níbo ni ìwọ ti wá? Satani sì dá OLúWA lóhùn pé, “Láti lọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.” OLúWA sì wí fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòtítọ́ tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kórìíra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run ún láìnídìí.” Satani sì dá OLúWA lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀. Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.” OLúWA sì wí fún Satani pé, “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.” Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú OLúWA, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú. Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!” Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn aṣiwèrè obìnrin ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ìre lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?” Nínú gbogbo èyí, Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa