Job 19:1-12
Job 19:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe, Yio ti pẹ to ti ẹnyin o fi ma bà mi ninu jẹ, ti ẹnyin o fi ma fi ọ̀rọ kun mi ni ìjanja? Igba mẹwa li ẹnyin ti ngàn mi, oju kò tì nyin ti ẹ fi jẹ mi niya. Ki a fi sí bẹ̃ pe, mo ṣìna nitõtọ, ìṣina mi wà lara emi tikarami. Bi o tilẹ ṣepe ẹnyin o ṣogo si mi lori nitõtọ, ti ẹ o si ma fi ẹ̀gan mi gun mi loju. Ki ẹ mọ̀ nisisiyi pe: Ọlọrun li o bì mi ṣubu, o si nà àwọn rẹ̀ yi mi ka. Kiyesi i, emi nkigbe pe, Ọwọ́ alagbara! ṣugbọn a kò gbọ́ ti emi; mo kigbe soke, bẹ̃ni kò si idajọ. O sọ̀gba di ọ̀na mi ti emi kò le kọja, o si mu òkunkun ṣú si ipa ọ̀na mi: O ti bọ́ ogo mi, o si ṣi ade kuro li ori mi. O ti bà mi jẹ ni iha gbogbo, ẹmi si pin; ireti mi li a o si fatu bi igi: O si tinabọ ibinu rẹ̀ si mi, o si kà mi si bi ọkan ninu awọn ọta rẹ̀. Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ si dàpọ si mi, nwọn si tẹgun si mi, nwọn si dó yi agọ mi ka.
Job 19:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Jobu bá dáhùn, ó ní, “Ẹ óo ti ni mí lára pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ọ̀rọ̀ yín bà mí ninu jẹ́? Ẹ kẹ́gàn mi ní àìníye ìgbà ojú kò tilẹ̀ tì yín láti ṣẹ̀ mí? Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé lótìítọ́ ni mo ṣẹ̀, ṣebí ara mi ni àṣìṣe mi wà? Bí ẹ bá rò pé ẹ sàn jù mí lọ, tí ẹ sì rò pé ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ni ìdààmú mi, ẹ mọ̀ dájú pé Ọlọrun ni ó dá mi lẹ́bi, tí ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká. Mò ń kérora pé wọ́n dá mi lóró, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn; mo pariwo, pariwo, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dìde láti ṣe ẹ̀tọ́. Ọlọrun ti dí ọ̀nà mọ́ mi, kí n má baà kọjá, ó mú ọ̀nà mi ṣókùnkùn. Ó bọ́ ògo mi kúrò, ó sì gba adé orí mi. Ó ba ayé mi jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà, ó sì ti parí fún mi, ó fa ìrètí mi tu bí ẹni fa igi tu. Ibinu rẹ̀ ń jó mi bí iná, ó kà mí kún ọ̀tá rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ, wọ́n dó tì mí, wọ́n sì pa àgọ́ tiwọn yí àgọ́ mi ká.
Job 19:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ni Jobu dáhùn, ó sì wí pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí, tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ yìí? Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí; ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà. Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́, ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi. Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́, tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú, Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká. “Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi; mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́. Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi. Ó ti bọ́ ògo mi, ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi. Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo, ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi. Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi, ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi, wọ́n sì mọ odi yí mi ká, wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.