Job 16:1-5
Job 16:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe, Emi ti gbọ́ iru ohun pipọ bẹ̃ ri; ayọnilẹnu onitunu enia ni gbogbo nyin. Ọ̀rọ asan lè ni opin? tabi kili o gbó ọ laiya ti iwọ fi dahùn. Emi pẹlu le isọ bi ẹnyin, bi ọkàn nyin ba wà ni ipò ọkàn mi, emi le iko ọ̀rọ pọ̀ si nyin li ọrùn, emi a si mì ori mi si nyin. Emi iba fi ọ̀rọ ẹnu mi gbà nyin ni iyanju, ati ṣiṣi ète mi iba si tu ibinujẹ nyin.
Job 16:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Jobu bá dáhùn pé, “Èmi náà ti gbọ́ irú nǹkan wọnyi rí, ọlọ́rọ̀ ìtùnú kòbákùngbé ni gbogbo yín. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ yìí tilẹ̀ lópin? Àbí, kí ní ń fa gbogbo àríyànjiyàn yìí? Bí ẹ bá wà ní ipò mi, èmi náà lè sọ̀rọ̀ bí ẹ tí ń sọ̀rọ̀ yìí, kí n da ọ̀rọ̀ bò yín, kí n sì máa mi orí si yín. Mo lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fun yín lókun, kí ọ̀rọ̀ ìtùnú mi sì mú kí ara tù yín.
Job 16:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé: “Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín. Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin? Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn? Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin; bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi, èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn, èmi a sì mi orí mi sí i yín. Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.