Job 12:7-10
Job 12:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nisisiyi, bi awọn ẹranko lere, nwọn o kọ́ ọ li ẹkọ́, ati ẹiyẹ oju ọrun, nwọn o si sọ fun ọ. Tabi, ba ilẹ aiye sọ̀rọ, yio si kọ́ ọ, awọn ẹja inu okun yio si sọ fun ọ. Tani kò mọ̀ ninu gbogbo wọnyi pe, ọwọ Oluwa li o ṣe nkan yi? Lọwọ ẹniti ẹmi ohun alãye gbogbo gbé wà, ati ẹmi gbogbo araiye.
Job 12:7-10 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣugbọn, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹranko, wọn óo sì kọ́ ọ, bi àwọn ẹyẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ; tabi kí o bi àwọn koríko, wọn yóo sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú òkun yóo sì ṣe àlàyé fún ọ. Ta ni kò mọ̀ ninu gbogbo wọn pé OLUWA ló ṣe èyí? Ọwọ́ rẹ̀ ni ìyè gbogbo ẹ̀dá wà, ati ẹ̀mí gbogbo eniyan.
Job 12:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ. Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú Òkun yóò sì sọ fún ọ. Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí pé, ọwọ́ OLúWA ni ó ṣe nǹkan yìí? Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà, Àti ẹ̀mí gbogbo aráyé.