Job 12:1-6
Job 12:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
JOBU si dahùn o si wipe, Kò si ani-ani nibẹ̀, ṣugbọn ẹnyin li awọn enia na, ọgbọ́n yio si kú pẹlu nyin. Ṣugbọn emi ni iyè ninu gẹgẹ bi ẹnyin: emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin: ani, tani kò mọ̀ nkan bi iru wọnyi? Emi dabi ẹniti a nfi ṣe ẹlẹya lọdọ aladugbo rẹ̀, ti o kepe Ọlọrun, ti o si da a lohùn: a nfi olõtọ ẹni-iduro-ṣinṣin rẹrin ẹlẹyà. Ẹgan ni ẹni-òtoṣi, ti ẹsẹ rẹ̀ mura tan lati yọ́ ninu ìro ẹniti ara rọ̀. Agọ awọn igara ngberú, awọn ti o si nmu Ọlọrun binu wà lailewu, awọn ẹniti o si gbá oriṣa mu li ọwọ wọn.
Job 12:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Jobu dáhùn pé: “Láìsí àní àní, ẹ̀yin ni agbẹnusọ gbogbo eniyan, bí ẹ bá jáde láyé, ọgbọ́n kan kò tún ní sí láyé mọ́. Bí ẹ ti ní ìmọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà ní, ẹ kò sàn jù mí lọ. Ta ni kò mọ irú nǹkan, tí ẹ̀ ń sọ yìí? Mo wá di ẹlẹ́yà lójú àwọn ọ̀rẹ́ mi, èmi tí mò ń ké pe Ọlọrun, tí ó sì ń dá mi lóhùn; èmi tí mo jẹ́ olódodo ati aláìlẹ́bi, mo wá di ẹlẹ́yà. Lójú ẹni tí ara tù, ìṣòro kì í báni láìnídìí. Lójú rẹ̀, ẹni tí ó bá ṣìṣe ni ìṣòro wà fún. Àwọn olè ń gbé ilé wọn ní alaafia, àwọn tí wọn ń mú Ọlọrun bínú wà ní àìléwu, àwọn tí ó jẹ́ pé agbára wọn ni Ọlọrun wọn.
Job 12:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé: “Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà, ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín! Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: èmi kò kéré sí i yín: àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí? “Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn: à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà. Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà, gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀. Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù; àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu, àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.