Job 1:8-9
Job 1:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa si sọ fun Satani pe, Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ, ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu. Nigbana ni Satani dá Oluwa lohùn wipe: Jobu ha bẹ̀ru Oluwa li asan bi?
Job 1:8-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí ẹni tí ó jẹ́ olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé, ati pé ó bẹ̀rù èmi OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú?” Satani dáhùn pé, “Ṣé lásán ni Jobu bẹ̀rù ìwọ Ọlọrun ni?
Job 1:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.” Nígbà náà ni Satani dá OLúWA lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?”