Job 1:1-22

Job 1:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌKUNRIN kan wà ni ilẹ Usi, orukọ ẹniti ijẹ Jobu; ọkunrin na si ṣe olõtọ, o duro ṣinṣin, ẹniti o si bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu. A si bi ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta fun u. Ohunọ̀sin rẹ̀ si jẹ ẹdẹgbarin agutan, ati ẹgbẹdogun ibakasiẹ, ati ẹdẹgbẹta ajaga ọdámalu, ati ẹdẹgbẹta abokẹtẹkẹtẹ, o si pọ̀; bẹ̃li ọkunrin yi si pọ̀ jù gbogbo awọn ọmọ ara ila-õrun lọ. Awọn ọmọ rẹ̀ a si ma lọ ijẹun àse ninu ile ara wọn, olukuluku li ọjọ rẹ̀; nwọn a si ma ranṣẹ pe arabinrin wọn mẹtẹta lati jẹun ati lati mu pẹlu wọn. O si ṣe, nigbati ọjọ àse wọn pé yika, ni Jobu ranṣẹ lọ iyà wọn si mimọ, o si dide ni kùtukutu owurọ, o si rú ẹbọ sisun niwọn iye gbogbo wọn; nitoriti Jobu wipe: bọya awọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, nwọn kò si ṣọpẹ́ fun Ọlọrun lọkàn wọn. Bẹ̃ni Jobu imaṣe nigbagbogbo. Njẹ, o di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wá ipé niwaju Oluwa, Satani si wá pẹlu wọn. Oluwa si bi Satani wipe: nibo ni iwọ ti wá? nigbana ni Satani da Oluwa lohùn wipe: ni ilọ siwá sẹhin lori ilẹ aiye, ati ni irinkerindo ninu rẹ̀. Oluwa si sọ fun Satani pe, Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ, ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu. Nigbana ni Satani dá Oluwa lohùn wipe: Jobu ha bẹ̀ru Oluwa li asan bi? Iwọ kò ha ti sọgbà yi i ká, ati yi ile rẹ̀ ati yi ohun ti o ni ká ni iha gbogbo? Iwọ busi iṣẹ ọwọ rẹ̀, ohunọ̀sin rẹ̀ si npọsi i ni ilẹ. Njẹ nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ ohun gbogbo ti o ni; bi kì yio si bọhùn li oju rẹ. Oluwa si dá Satani lohùn wipe: kiyesi i, ohun gbogbo ti o ni mbẹ ni ikawọ rẹ, kìki on tikara rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ rẹ kàn: bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa. O si di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati obinrin njẹ, ti nwọn nmu ọti-waini ninu ile ẹgbọn wọn ọkunrin: Onṣẹ kan si tọ̀ Jobu wá wipe: awọn ọda-malu ntulẹ, awọn kẹtẹkẹtẹ si njẹ li ẹba wọn; Awọn ara Saba si kọlu wọn, nwọn si nkó wọn lọ, pẹlupẹlu nwọn ti fi idà ṣá awọn iranṣẹ pa, emi nikanṣoṣo li o sa asalà lati ròhin fun ọ. Bi o ti nsọ li ẹnu; ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: iná nla Ọlọrun ti ọrun bọ́ si ilẹ, o si jó awọn agutan ati awọn iranṣẹ ni ajorun; emi nikanṣoṣo li o salà lati rohin fun ọ. Bi o si ti nsọ li ẹnu, ẹnikan si de pẹlu ti o wipe: awọn ara Kaldea pingun si ọ̀na mẹta, nwọn si kọlu awọn ibakasiẹ, nwọn si kó wọn lọ, pẹlupẹlu nwọn si fi idà ṣá awọn iranṣẹ pa; emi nikanṣoṣo li o sa asalà lati rohin fun ọ. Bi o ti nsọ li ẹnu, ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ọmọ rẹ obinrin njẹ nwọn nmu ọti-waini ninu ile ẹgbọn wọn ọkunrin. Si kiyesi i, ẹfufu nlanla ti iha ijù fẹ wá ikọlu igun mẹrẹrin ile, o si wolù awọn ọdọmọkunrin na, nwọn si kú, emi nikanṣoṣo li o yọ lati rohin fun ọ. Nigbana ni Jobu dide, o si fa aṣọ igunwa rẹ̀ ya, o si fari rẹ̀, o wolẹ, o si gbadura. Wipe, Nihoho ni mo ti inu iya mi jade wá, nihoho ni emi o si tun pada lọ sibẹ: Oluwa fifunni Oluwa si gbà lọ, ibukun li orukọ Oluwa. Ninu gbogbo eyi Jobu kò ṣẹ̀, bẹ̃ni kò si fi were pè Ọlọrun lẹjọ.

Job 1:1-22 Yoruba Bible (YCE)

Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jobu; ó ń gbé ilẹ̀ Usi, ó jẹ́ olódodo ati olóòótọ́ eniyan, ó bẹ̀rù Ọlọrun, ó sì kórìíra ìwà burúkú. Ó bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta. Ó ní ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan, ẹgbẹẹdogun (3,000) ràkúnmí, ẹẹdẹgbẹta (500) àjàgà mààlúù, ẹẹdẹgbẹta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ọpọlọpọ iranṣẹ; òun ni ó lọ́lá jùlọ ninu gbogbo àwọn ará ìlà oòrùn. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa lọ jẹ àsè ninu ilé ara wọn. Olukuluku wọn ní ọjọ́ àsè tirẹ̀, wọn a sì máa pe àwọn arabinrin wọn wá sí ilé láti bá wọn jẹ àsè. Nígbà tí wọ́n bá se àsè náà kárí tán, Jobu yóo ranṣẹ sí wọn láti rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún wọn. Ní àárọ̀ kutukutu, yóo dìde yóo rú ẹbọ sísun fún olukuluku wọn, yóo wí pé, “Bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti bú Ọlọrun ninu ọkàn wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni Jobu máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà. Ní ọjọ́ kan, àwọn ọmọ Ọlọrun wá láti fi ara wọn hàn níwájú OLUWA. Satani náà wà láàrin wọn. OLUWA bi Satani pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?” Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Mò ń lọ sókè sódò káàkiri gbogbo ayé.” OLUWA tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí ẹni tí ó jẹ́ olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé, ati pé ó bẹ̀rù èmi OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú?” Satani dáhùn pé, “Ṣé lásán ni Jobu bẹ̀rù ìwọ Ọlọrun ni? Ṣebí nígbà gbogbo ni ò ń dáàbò bo òun ati àwọn ará ilé rẹ̀, ati gbogbo ohun tí ó ní. Ò ń bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, o sì sọ ohun ìní rẹ̀ di pupọ. Ǹjẹ́, ìwọ mú gbogbo nǹkan wọnyi kúrò wò, o óo rí i pé yóo sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.” OLUWA dá Satani lóhùn pé, “Ó dára, ohun gbogbo tí ó ní wà ní ìkáwọ́ rẹ. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan òun fúnra rẹ̀.” Satani bá kúrò níwájú OLUWA. Ní ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Jobu ń jẹ àsè ninu ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkunrin, tí ó jẹ́ àgbà patapata, iranṣẹ kan wá sọ́dọ̀ Jobu, ó ròyìn fún un pé, “Àwọn akọ mààlúù ń fi àjàgà wọn kọlẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹko nítòsí wọn; àwọn ará Sabea rí wọn, wọ́n sì kó gbogbo wọn, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Iná Ọlọrun wá láti ọ̀run, ó jó àwọn aguntan ati gbogbo darandaran patapata, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.” Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ tí iranṣẹ mìíràn fi tún dé, ó ní, “Àwọn ẹgbẹ́ ogun Kalidea mẹta kọlù wá, wọ́n kó gbogbo ràkúnmí wa lọ, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Bí àwọn ọmọ rẹ tí ń jẹ àsè ninu ilé ẹ̀gbọ́n wọn àgbà, ìjì líle kan fẹ́ la àṣálẹ̀ kọjá, ó fẹ́ lu ilé náà, ó wó, ó sì pa gbogbo wọn, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.” Jobu bá dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn; ó fá orí rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì sin OLUWA. Ó ní, “Ìhòòhò ni wọ́n bí mi, ìhòòhò ni n óo sì pada lọ. OLUWA níí fún ni ní nǹkan, OLUWA náà ní í sì í gbà á pada, ìyìn ni fún orúkọ OLUWA.” Ninu gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀, kò sì dá Ọlọrun lẹ́bi.

Job 1:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú, A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un. Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ. Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo. Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú OLúWA, Satani sì wá pẹ̀lú wọn. OLúWA sì bi Satani wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Nígbà náà ní Satani dá OLúWA lóhùn wí pé, “Ní ìlọ-síwá-sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.” OLúWA sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.” Nígbà náà ni Satani dá OLúWA lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?” “Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ si ní ilẹ̀. Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ.” OLúWA sì dá Satani lóhùn wí pé, “Kíyèsi i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.” Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú OLúWA. Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin, oníṣẹ́ kan sì tọ Jobu wá wí pé: “Àwọn ọ̀dá màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn; Àwọn ará Sabeani sì kọlù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.” Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi nìkan ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.” Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kaldea píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọlù àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lú wọ́n sì fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!” Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n. Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńláńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ. Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà wí pé: “Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá, ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ. OLúWA fi fún ni, OLúWA sì gbà á lọ, ìbùkún ni fún orúkọ OLúWA.” Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa