Joh 9:35-41
Joh 9:35-41 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu gbọ́ pe, nwọn ti tì i sode; nigbati o si ri i, o wipe, Iwọ gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́ bi? On si dahùn wipe, Tani, Oluwa, ki emi ki o le gbà a gbọ́? Jesu wi fun u pe, Iwọ ti ri i, on na si ni ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi. O si wipe, Oluwa, mo gbagbọ́, o si wolẹ fun u. Jesu si wipe, Nitori idajọ ni mo ṣe wá si aiye yi, ki awọn ti kò riran, le riran; ati ki awọn ti o riran le di afọju. Ninu awọn Farisi ti o wà lọdọ rẹ̀ gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si wi fun u pe, Awa pẹlu fọju bi? Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin fọju, ẹnyin kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi ẹnyin wipe, Awa riran; nitorina ẹ̀ṣẹ nyin wà sibẹ̀.
Joh 9:35-41 Yoruba Bible (YCE)
Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ti ọkunrin náà jáde kúrò ninu ilé ìpàdé. Nígbà tí ó rí i, ó bí i pé, “Ìwọ gba Ọmọ-Eniyan gbọ́ bí?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Alàgbà, ta ni ẹni náà, kí n lè gbà á gbọ́?” Jesu wí fún un pé, “Èmi tí ò ń wò yìí, tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni ẹni náà.” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́, Oluwa!” Ó bá dọ̀bálẹ̀ fún un. Jesu bá ní, “Kí n lè ṣe ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran, kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.” Farisi wà láàrin àwọn eniyan tí ó wà pẹlu rẹ̀, tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n bi í pé, “Àbí àwa náà fọ́jú?” Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ fọ́jú, ẹ kò bá tí ní ẹ̀bi. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ sọ pé, ‘Àwa ríran’ ẹ̀bi yín wà sibẹ.”
Joh 9:35-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu gbọ́ pé, wọ́n ti tì í sóde; nígbà tí ó sì rí i, ó wí pe, “Ìwọ gba Ọmọ Ọlọ́run, gbọ́ bí?” Òun sì dáhùn wí pé, “Ta ni, Olúwa, kí èmi lè gbà á gbọ́?” Jesu wí fún un pé, “Ìwọ ti rí i, Òun náà sì ni ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.” Ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́,” ó sì wólẹ̀ fún un. Jesu sì wí pé, “Nítorí ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran; àti kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.” Nínú àwọn Farisi tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú fọ́jú bí?” Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fọ́jú, ẹ̀yin kì bá tí lẹ́sẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa ríran,’ nítorí náà ẹ̀ṣẹ̀ yín wà síbẹ̀.