Joh 8:53-59
Joh 8:53-59 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ ha pọ̀ju Abrahamu baba wa lọ, ẹniti o kú? awọn woli si kú: tani iwọ nfi ara rẹ pè? Jesu dahùn wipe, Bi mo ba nyìn ara mi li ogo, ogo mi kò jẹ nkan: Baba mi ni ẹniti nyìn mi li ogo, ẹniti ẹnyin wipe, Ọlọrun nyin ni iṣe: Ẹ kò si mọ̀ ọ; ṣugbọn emi mọ̀ ọ: bi mo ba si wipe, emi kò mọ̀ ọ, emi ó di eke gẹgẹ bi ẹnyin: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, mo si pa ọ̀rọ rẹ̀ mọ́. Abrahamu baba nyin yọ̀ lati ri ọjọ mi: o si ri i, o si yọ̀. Nitorina awọn Ju wi fun u pe, Ọdún rẹ kò ti ito adọta, iwọ si ti ri Abrahamu? Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ki Abrahamu to wà, emi ti wà. Nitorina nwọn gbé okuta lati sọ lù ú: ṣugbọn Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, o si jade kuro ni tẹmpili.
Joh 8:53-59 Yoruba Bible (YCE)
Abrahamu baba wa, tí ó ti kú ńkọ́? Ṣé ìwọ jù ú lọ ni? Ati àwọn wolii tí wọ́n ti kú? Ta ni o tilẹ̀ ń fi ara rẹ pè?” Jesu dáhùn pé, “Bí mo bá bu ọlá fún ara mi, òfo ni ọlá mi. Baba mi ni ó bu ọlá fún mi, òun ni ẹ̀yin ń pè ní Ọlọrun yín. Ẹ kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́n. Bí mo bá sọ pé èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóo di òpùrọ́ bíi yín. Ṣugbọn mo mọ̀ ọ́n, mo sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Inú Abrahamu baba yín dùn láti rí àkókò wíwá mi, ó rí i, ó sì yọ̀.” Àwọn Juu sọ fún un pé, “Ìwọ yìí ti rí Abrahamu, nígbà tí o kò ì tíì tó ẹni aadọta ọdún?” Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kí wọ́n tó bí Abrahamu ni èmi ti wà.” Wọ́n bá ṣa òkúta, wọ́n fẹ́ sọ ọ́ lù ú, ṣugbọn ó fi ara pamọ́, ó bá kúrò ninu Tẹmpili.
Joh 8:53-59 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú: ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?” Jesu dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan; Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe: Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Abrahamu baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi: ó sì rí i, ó sì yọ̀.” Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé, “Ọdún rẹ kò ì tó àádọ́ta, ìwọ sì ti rí Abrahamu?” Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Abrahamu tó wà, èmi ti wa.” Nítorí náà wọ́n gbé òkúta láti sọ lù ú: ṣùgbọ́n Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, ó sì jáde kúrò ní tẹmpili.