Joh 8:22-34

Joh 8:22-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitorina awọn Ju wipe, On o ha pa ara rẹ̀ bi? nitoriti o wipe, Ibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì ó le wá. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti isalẹ wá; emi ti oke wá: ẹnyin jẹ ti aiye yi; emi kì iṣe ti aiye yi. Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: nitori bikoṣepé ẹ ba gbagbọ́ pe, emi ni, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin. Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? Jesu si wi fun wọn pe, Ani eyinì ti mo ti wi fun nyin li àtetekọṣe. Mo ni ohun pupọ̀ lati sọ, ati lati ṣe idajọ nipa nyin: ṣugbọn olõtọ li ẹniti o ran mi, ohun ti emi si ti gbọ lati ọdọ rẹ̀ wá, nwọnyi li emi nsọ fun araiye. Kò yé wọn pe, ti Baba li o nsọ fun wọn. Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Nigbati ẹ ba gbé Ọmọ-enia soke, nigbana li ẹ o mọ̀ pe, emi ni, ati pe emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi nsọ nkan wọnyi. Ẹniti o rán mi si mbẹ pẹlu mi: kò jọwọ emi nikan si; nitoriti emi nṣe ohun ti o wù u nigbagbogbo. Bi o ti nsọ nkan wọnyi, ọ̀pọ enia gbà a gbọ́. Nitorina Jesu wi fun awọn Ju ti o gbà a gbọ́ pe, Bi ẹnyin ba duro ninu ọ̀rọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ. Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira. Nwọn da a lohùn wipe, Irú-ọmọ Abrahamu li awa iṣe, awa kò si ṣe ẹrú fun ẹnikẹni ri lai: iwọ ha ṣe wipe, Ẹ o di omnira? Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ.

Joh 8:22-34 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Kò ṣá ní pa ara rẹ̀, nítorí ó wí pé, ‘Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.’ ” Ó wá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin, ní tiyín, ìsàlẹ̀ ni ẹ ti wá, ṣugbọn ní tèmi, òkè ọ̀run ni mo ti wá. Ti ayé yìí ni yín, èmi kì í ṣe ti ayé yìí. Nítorí náà, mo wí fun yín pé ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Nítorí bí ẹ kò bá gbàgbọ́ pé, ‘Èmi ni,’ ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Wọ́n bi í pé, “Ta ni ọ́?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ti sọ ẹni tí mo jẹ́ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀. Mo ní ohun pupọ láti sọ nípa yín ati láti fi ṣe ìdájọ́ yín. Olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi níṣẹ́; ohun tí mo gbọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mò ń sọ fún aráyé.” Wọn kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Baba ni ó ń sọ fún wọn. Jesu tún wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ-Eniyan sókè, nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni, ati pé èmi kò dá ohunkohun ṣe fúnra mi, ṣugbọn bí Baba ti kọ́ mi ni mò ń sọ̀rọ̀ yìí. Ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ wà pẹlu mi, kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan, nítorí mò ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ báyìí, ọpọlọpọ eniyan gbà á gbọ́. Jesu bá wí fún àwọn Juu tí ó gbà á gbọ́ pé, “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín nítòótọ́; ẹ óo mọ òtítọ́, òtítọ́ yóo sì sọ yín di òmìnira.” Wọ́n sọ fún un pé, “Ìran Abrahamu ni wá, a kò fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ẹnikẹ́ni. Kí ni ìtumọ̀ gbolohun tí o wí pé, ‘Ẹ̀yin yóo di òmìnira’?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.

Joh 8:22-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí. Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?” Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe. Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín: ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.” Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn. Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí. Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́. Nítorí náà Jesu wí fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi nítòótọ́. Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.