Joh 8:12-20
Joh 8:12-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye. Nitorina awọn Farisi wi fun u pe, Iwọ njẹri ara rẹ; ẹrí rẹ kì iṣe otitọ. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Bi mo tilẹ njẹri fun ara mi, otitọ li ẹrí mi: nitoriti mo mọ̀ ibiti mo ti wá, mo si mọ̀ ibiti mo nlọ; ṣugbọn ẹnyin kò le mọ̀ ibiti mo ti wá, ati ibiti mo nlọ. Ẹnyin nṣe idajọ nipa ti ara; emi kò ṣe idajọ ẹnikẹni. Ṣugbọn bi emi ba si ṣe idajo, otitọ ni idajọ mi: nitori emi nikan kọ́, ṣugbọn emi ati Baba ti o rán mi. Ẹ si kọ ọ pẹlu ninu ofin nyin pe, otitọ li ẹrí enia meji. Emi li ẹniti njẹri ara mi, ati Baba ti o rán mi si njẹri fun mi. Nitorina nwọn wi fun u pe, Nibo ni Baba rẹ wà? Jesu dahùn pe, Ẹnyin kò mọ̀ mi, bẹli ẹ kò mọ̀ Baba mi: ibaṣepe ẹnyin mọ̀ mi, ẹnyin iba si ti mọ̀ Baba mi pẹlu. Ọ̀rọ wọnyi ni Jesu sọ nibi iṣura, bi o ti nkọ́ni ni tẹmpili: ẹnikẹni ko si mu u; nitori wakati rẹ̀ ko ti ide.
Joh 8:12-20 Yoruba Bible (YCE)
Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.” Àwọn Farisi sọ fún un pé, “Ò ń jẹ́rìí ara rẹ, ẹ̀rí rẹ kò jámọ́ nǹkankan.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá ń jẹ́rìí ara mi, sibẹ òtítọ́ ni ẹ̀rí mi, nítorí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mò ń lọ. Ṣugbọn ẹ̀yin kò mọ ibi tí mo ti wá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì mọ ibi tí mò ń lọ. Ojú ni ẹ̀ ń wò tí ẹ fi ń ṣe ìdájọ́, èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni. Bí mo bá tilẹ̀ ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni ìdájọ́ mi, nítorí kì í ṣe èmi nìkan ni mò ń ṣe ìdájọ́, èmi ati Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni. Ninu òfin yín a kọ ọ́ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí ẹni meji. Èmi fúnra mi jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi níṣẹ́ náà sì ń jẹ́rìí mi.” Wọ́n bi í pé, “Níbo ni baba rẹ wà?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀ mí, ẹ̀ bá mọ Baba mi.” Jesu wí báyìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili ninu iyàrá ìṣúra. Ẹnikẹ́ni kò mú un, nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.
Joh 8:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.” Nítorí náà àwọn Farisi wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rìí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.” Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rìí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ. Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni: nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi. A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì. Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí mi.” Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi: ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.” Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili: ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.