Joh 8:1-12

Joh 8:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Ni olukuluku wọn bá lọ sí ilé wọn; ṣugbọn Jesu lọ sí Òkè Olifi. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó tún lọ sí Tẹmpili. Gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá jókòó, ó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn amòfin ati àwọn Farisi mú obinrin kan wá, tí wọ́n ká mọ́ ibi tí ó ti ń ṣe àgbèrè. Wọ́n ní kí ó dúró láàrin wọn; wọ́n wá sọ fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, a ká obinrin yìí mọ́ ibi tí ó ti ń ṣe àgbèrè, a ká a mọ́ ọn gan-an ni! Ninu Òfin wa Mose pàṣẹ pé kí á sọ irú àwọn bẹ́ẹ̀ ní òkúta pa. Kí ni ìwọ wí?” Wọ́n sọ èyí láti fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu ni kí wọ́n lè fi ẹ̀sùn kàn án. Jesu bá bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀. Bí wọ́n ti dúró tí wọ́n tún ń bi í, ó gbé ojú sókè ní ìjókòó tí ó wà, ó wí fún wọn pé, “Ẹni tí kò bá ní ẹ̀ṣẹ̀ ninu yín ni kí ó kọ́ sọ ọ́ ní òkúta.” Ó bá tún bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, àwọn àgbààgbà ni wọ́n kọ́ lọ. Gbogbo wọ́n bá túká pátá láìku ẹnìkan. Ó wá ku obinrin yìí nìkan níbi tí ó dúró sí. Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó bi obinrin náà pé, “Obinrin, àwọn dà? Ẹnìkan ninu wọn kò dá ọ lẹ́bi?” Ó ní, “Alàgbà, ẹnìkankan kò dá mi lẹ́bi.” Jesu wí fún un pé, “Èmi náà kò dá ọ lẹ́bi. Máa lọ; láti ìsinsìnyìí lọ, má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”] Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

Joh 8:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Jesu sì lọ sí orí òkè olifi. Ó sì tún padà wá sí tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú nínú ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrín. Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà, Ǹjẹ́ nínú òfin, Mose pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?” Èyí ni wọ́n wí, láti dán án wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn. Ṣùgbọ́n Jesu bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.” Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, (tí ẹ̀rí ọkàn wọn sì dá wọn lẹ́bi) wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jesu nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàrín, níbi tí ó wà. Jesu sì dìde, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn (olùfisùn rẹ) dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?” Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.” Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi: máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.” Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”