Joh 6:56-58
Joh 6:56-58 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ngbé inu mi, emi si ngbé inu rẹ̀. Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi. Eyi si li onjẹ na ti o sọkalẹ lati ọrun wá: ki iṣe bi awọn baba nyin ti jẹ manna, ti nwọn si kú: ẹniti o ba jẹ onjẹ yi yio yè lailai.
Joh 6:56-58 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, olúwarẹ̀ ń gbé inú mi, èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wà láàyè nítorí ti Baba. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran ara mi, yóo yè nítorí tèmi. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀, kì í ṣe irú èyí tí àwọn baba yín jẹ, tí wọ́n sì kú sibẹsibẹ. Ẹni tí ó bá jẹ oúnjẹ yìí yóo wà láàyè laelae.”
Joh 6:56-58 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi. Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá: kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ manna, tí wọ́n sì kú: ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.”