Joh 6:48-58

Joh 6:48-58 Yoruba Bible (YCE)

Èmi pàápàá ni oúnjẹ tí ó ń fún eniyan ní ìyè. Àwọn baba wa jẹ mana ní aṣálẹ̀, sibẹ wọ́n kú. Ṣugbọn oúnjẹ tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ ni èyí tí ó jẹ́ pé bí ẹnìkan bá jẹ ninu rẹ̀, olúwarẹ̀ kò ní kú. Èmi ni oúnjẹ tí ó wà láàyè tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ninu oúnjẹ yìí, olúwarẹ̀ yóo wà láàyè laelae. Oúnjẹ tí èmi yóo fi fún un ni ẹran ara mi tí yóo fi ìyè fún gbogbo ayé.” Gbolohun yìí dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láàrin àwọn Juu. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe lè fún wa ní ẹran-ara rẹ̀ jẹ?” Jesu wá wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ̀yin kò bá jẹ ẹran ara ọmọ eniyan, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò lè ní ìyè ninu yín. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ní ìyè ainipẹkun, èmi yóo sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. Ẹran-ara mi ni oúnjẹ gidi, ẹ̀jẹ̀ mi sì ni ohun mímu iyebíye. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, olúwarẹ̀ ń gbé inú mi, èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wà láàyè nítorí ti Baba. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran ara mi, yóo yè nítorí tèmi. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀, kì í ṣe irú èyí tí àwọn baba yín jẹ, tí wọ́n sì kú sibẹsibẹ. Ẹni tí ó bá jẹ oúnjẹ yìí yóo wà láàyè laelae.”

Joh 6:48-58 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èmi ni oúnjẹ ìyè. Àwọn baba yín jẹ manna ní aginjù, wọ́n sì kú. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú. Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.” Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, “Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun; Èmi o sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. Nítorí ara mi ni ohun jíjẹ nítòótọ́, àti ẹ̀jẹ̀ mi ni ohun mímu nítòótọ́. Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi. Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá: kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ manna, tí wọ́n sì kú: ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.”