Joh 6:43-71

Joh 6:43-71 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitorina Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe kùn lãrin ara nyin. Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. A sá ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, A o si kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun wá. Nitorina ẹnikẹni ti o ba ti gbọ́, ti a si ti ọdọ Baba kọ́, on li o ntọ̀ mi wá. Koṣepe ẹnikan ti ri Baba bikoṣe ẹniti o ti ọdọ Ọlọrun wá, on li o ti ri Baba. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, o ni ìye ainipẹkun. Emi li onjẹ ìye. Awọn baba nyin jẹ manna li aginjù, nwọn si kú. Eyi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ki enia le mã jẹ ninu rẹ̀ ki o má si kú. Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye. Nitorina li awọn Ju ṣe mba ara wọn jiyàn, wipe, ọkunrin yi yio ti ṣe le fi ara rẹ̀ fun wa lati jẹ? Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe ẹnyin ba jẹ ara Ọmo-enia, ki ẹnyin si mu ẹ̀jẹ rẹ̀, ẹnyin kò ni ìye ninu nyin. Ẹnikẹni ti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ni ìye ti kò nipẹkun; Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. Nitori ara mi li ohun jijẹ nitõtọ, ati ẹ̀jẹ mi li ohun mimu nitõtọ. Ẹniti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ngbé inu mi, emi si ngbé inu rẹ̀. Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi. Eyi si li onjẹ na ti o sọkalẹ lati ọrun wá: ki iṣe bi awọn baba nyin ti jẹ manna, ti nwọn si kú: ẹniti o ba jẹ onjẹ yi yio yè lailai. Nkan wọnyi li o sọ ninu sinagogu, bi o ti nkọni ni Kapernaumu. Nitorina nigbati ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọ̀rọ ti o le li eyi; tani le gbọ́ ọ? Nigbati Jesu si mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nkùn si ọ̀rọ na, o wi fun wọn pe, Eyi jẹ ikọsẹ̀ fun nyin bi? Njẹ, bi ẹnyin ba si ri ti Ọmọ-enia ngòke lọ sibi ti o gbé ti wà ri nkọ́? Ẹmí ni isọni di ãye; ara kò ni ère kan; ọ̀rọ wọnni ti mo sọ fun nyin, ẹmi ni, ìye si ni. Ṣugbọn awọn kan wà ninu nyin ti kò gbagbọ́. Nitori Jesu mọ̀ lati ìbẹrẹ wá ẹniti nwọn iṣe ti ko gbagbọ́, ati ẹniti yio fi on hàn. O si wipe, Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, kò si ẹniti o le tọ̀ mi wá, bikoṣepe a fifun u lati ọdọ Baba mi wá. Nitori eyi ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pada sẹhin, nwọn kò si bá a rìn mọ́. Nitorina Jesu wi fun awọn mejila pe, Ẹnyin pẹlu nfẹ lọ bi? Nigbana ni Simoni Peteru da a lohùn wipe, Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? Iwọ li o ni ọ̀rọ ìye ainipẹkun. Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye. Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin mejila kọ́ ni mo yàn, ọkan ninu nyin kò ha si yà Èṣu? O nsọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni: nitoripe on li ẹniti yio fi i hàn, ọkan ninu awọn mejila.

Joh 6:43-71 Yoruba Bible (YCE)

Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrin ara yín mọ́. Kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi àfi bí Baba tí ó rán mi níṣẹ́ bá fà á wá, èmi óo wá jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. Ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé, ‘Gbogbo wọn ni Ọlọrun yóo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.’ Gbogbo ẹni tí ó bá gba ọ̀rọ̀ Baba, tí ó kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, á wá sọ́dọ̀ mi. Kò sí ẹni tí ó rí Baba rí àfi ẹni tí ó ti wà pẹlu Baba ni ó ti rí Baba. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní ìyè ainipẹkun. Èmi pàápàá ni oúnjẹ tí ó ń fún eniyan ní ìyè. Àwọn baba wa jẹ mana ní aṣálẹ̀, sibẹ wọ́n kú. Ṣugbọn oúnjẹ tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ ni èyí tí ó jẹ́ pé bí ẹnìkan bá jẹ ninu rẹ̀, olúwarẹ̀ kò ní kú. Èmi ni oúnjẹ tí ó wà láàyè tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ninu oúnjẹ yìí, olúwarẹ̀ yóo wà láàyè laelae. Oúnjẹ tí èmi yóo fi fún un ni ẹran ara mi tí yóo fi ìyè fún gbogbo ayé.” Gbolohun yìí dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láàrin àwọn Juu. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe lè fún wa ní ẹran-ara rẹ̀ jẹ?” Jesu wá wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ̀yin kò bá jẹ ẹran ara ọmọ eniyan, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò lè ní ìyè ninu yín. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ní ìyè ainipẹkun, èmi yóo sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. Ẹran-ara mi ni oúnjẹ gidi, ẹ̀jẹ̀ mi sì ni ohun mímu iyebíye. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, olúwarẹ̀ ń gbé inú mi, èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wà láàyè nítorí ti Baba. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran ara mi, yóo yè nítorí tèmi. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀, kì í ṣe irú èyí tí àwọn baba yín jẹ, tí wọ́n sì kú sibẹsibẹ. Ẹni tí ó bá jẹ oúnjẹ yìí yóo wà láàyè laelae.” Jesu sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn ní Kapanaumu. Ọpọlọpọ tí ó gbọ́ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé, “Ọ̀rọ̀ yìí le, kò sí ẹni tí ó lè gba irú rẹ̀!” Nígbà tí Jesu rí i pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn nítorí rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí ni ó mú kí ọkàn yín dààmú? Tí ẹ bá wá rí Ọmọ-Eniyan tí ń gòkè lọ sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀ ńkọ́? Ẹ̀mí ní ń sọ eniyan di alààyè, ẹran-ara kò ṣe anfaani kankan. Ọ̀rọ̀ tí mo ti ba yín sọ jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀mí ati ti ìyè. Ṣugbọn àwọn tí kò gbàgbọ́ wà ninu yín.” Jesu sọ èyí nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ó ti mọ àwọn tí kò gbàgbọ́ ati ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Ó ní, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, àfi bí Baba mi bá ṣí ọ̀nà fún un láti wá.” Nítorí èyí, ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ̀, wọn kò tún bá a rìn mọ́. Jesu bá bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila pé, “Ẹ̀yin náà fẹ́ lọ bí?” Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Oluwa, ọ̀dọ̀ ta ni à bá lọ? Ìwọ ni o ní ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun. Ní tiwa, a ti gbàgbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọrun.” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ̀yin mejila ni mo yàn. Ṣugbọn ẹni ibi ni ọ̀kan ninu yín.” Ó wí èyí nípa Judasi Iskariotu ọmọ Simoni, nítorí òun ni ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ni Judasi Iskariotu yìí.

Joh 6:43-71 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrín yín! Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, bí kò ṣe pé Baba tí ó rán mi fà á: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. A sá à ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé, ‘A ó sì kọ́ gbogbo wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,’ nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́, tí a sì ti ọ̀dọ̀ Baba kọ́, òun ni ó ń tọ̀ mí wá. Kì í ṣe pé ẹnìkan ti rí Baba bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, òun ni ó ti rí Baba. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun. Èmi ni oúnjẹ ìyè. Àwọn baba yín jẹ manna ní aginjù, wọ́n sì kú. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú. Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.” Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, “Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun; Èmi o sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. Nítorí ara mi ni ohun jíjẹ nítòótọ́, àti ẹ̀jẹ̀ mi ni ohun mímu nítòótọ́. Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi. Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá: kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ manna, tí wọ́n sì kú: ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.” Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ nínú Sinagọgu, bí ó ti ń kọ́ni ní Kapernaumu. Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Ọ̀rọ̀ tí ó le ni èyí; ta ní lè gbọ́ ọ?” Nígbà tí Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí? Ǹjẹ́, bí ẹ̀yin bá sì rí i tí ọmọ ènìyàn ń gòkè lọ sí ibi tí ó gbé ti wà rí ńkọ́? Ẹ̀mí ní ń sọ ni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àwọn kan wà nínú yín tí kò gbàgbọ́.” Nítorí Jesu mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹni tí wọ́n jẹ́ tí kò gbàgbọ́, àti ẹni tí yóò fi òun hàn. Ó sì wí pé, “Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ mí wá, bí kò ṣe pé a fi fún un láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá.” Nítorí èyí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ padà sẹ́yìn, wọn kò sì bá a rìn mọ́. Nítorí náà Jesu wí fún àwọn méjìlá pé, “Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ lọ bí?” Nígbà náà ni Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa ó lọ? Ìwọ ni ó ni ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun. Àwa sì ti gbàgbọ́, a sì mọ̀ pé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin méjìlá kọ́ ni mo yàn, ọ̀kan nínú yín kò ha sì ya èṣù?” (Ó ń sọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni ọ̀kan nínú àwọn méjìlá: nítorí pé òun ni ẹni tí yóò fi í hàn.)