Joh 6:32-35
Joh 6:32-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì iṣe Mose li o fi onjẹ nì fun nyin lati ọrun wá; ṣugbọn Baba mi li o fi onjẹ otitọ nì fun nyin lati ọrun wá. Nitoripe onjẹ Ọlọrun li ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi ìye fun araiye. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Oluwa, mã fun wa li onjẹ yi titi lai. Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai.
Joh 6:32-35 Yoruba Bible (YCE)
Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe Mose ni ó fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá. Baba mi ni ó ń fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá; nítorí oúnjẹ Ọlọrun ni ẹni tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó ń fi ìyè fún aráyé.” Wọ́n bá sọ fún un pé, “Alàgbà, máa fún wa ní oúnjẹ yìí nígbà gbogbo.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ń fún eniyan ní ìyè, ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi kò ní pa á, ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ laelae.
Joh 6:32-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kì í ṣe Mose ni ó fi oúnjẹ fún yín láti ọ̀run wá; ṣùgbọ́n Baba mi ni ó fi oúnjẹ òtítọ́ náà fún yín láti ọ̀run wá. Nítorí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni èyí tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó sì fi ìyè fún aráyé.” Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí títí láé.” Jesu wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé.